Juízes 5 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Juízes 5:1-31

O Cântico de Débora

1Naquele dia, Débora e Baraque, filho de Abinoão, entoaram este cântico:

2“Consagrem-se para a guerra os chefes de Israel.

Voluntariamente o povo se apresenta.

Louvem o Senhor!

3“Ouçam, ó reis! Governantes, escutem!

Cantarei ao5.3 Ou sobre o Senhor, cantarei;

comporei músicas ao5.3 Ou Com cânticos louvarei o Senhor, o Deus de Israel.

4“Ó Senhor, quando saíste de Seir,

quando marchaste desde os campos de Edom,

a terra estremeceu, os céus gotejaram,

as nuvens despejaram água!

5Os montes tremeram

perante o Senhor, o Deus do Sinai,

perante o Senhor, o Deus de Israel.

6“Nos dias de Sangar, filho de Anate,

nos dias de Jael, as estradas estavam desertas;

os que viajavam seguiam caminhos tortuosos.

7Já tinham desistido os camponeses de Israel,5.7 Ou Desapareceram os guerreiros em Israel,

já tinham desistido,

até que eu, Débora, me levantei;5.7 Ou até que você, Débora, se levantou;

levantou-se uma mãe em Israel.

8Quando escolheram novos deuses,

a guerra chegou às portas,

e não se via um só escudo ou lança

entre quarenta mil de Israel.

9Meu coração está com os comandantes de Israel,

com os voluntários dentre o povo.

Louvem o Senhor!

10“Vocês, que cavalgam em brancos jumentos,

que se assentam em ricos tapetes,

que caminham pela estrada, considerem!

11Mais alto que a voz dos que distribuem água5.11 Ou dos flecheiros

junto aos bebedouros,

recitem-se os justos feitos do Senhor,

os justos feitos em favor dos camponeses5.11 Ou guerreiros de Israel.

“Então o povo do Senhor

desceu às portas.

12‘Desperte, Débora! Desperte!

Desperte, desperte, irrompa em cânticos!

Levante-se, Baraque!

Leve presos os seus prisioneiros, ó filho de Abinoão!’

13“Então desceram os restantes e foram aos nobres;

o povo do Senhor veio a mim contra os poderosos.

14Alguns vieram de Efraim,

das raízes de Amaleque;

Benjamim estava com o povo que seguiu você.

De Maquir desceram comandantes;

de Zebulom, os que levam a vara de oficial.

15Os líderes de Issacar estavam com Débora;

sim, Issacar também estava com Baraque,

apressando-se após ele até o vale.

Nas divisões de Rúben

houve muita inquietação.

16Por que vocês permaneceram entre as fogueiras5.16 Ou os alforjes

a ouvir o balido dos rebanhos?

Nas divisões de Rúben

houve muita indecisão.

17Gileade permaneceu do outro lado do Jordão.

E Dã, por que se deteve junto aos navios?

Aser permaneceu no litoral

e em suas enseadas ficou.

18O povo de Zebulom arriscou a vida,

como o fez Naftali nas altas regiões do campo.

19“Vieram reis e lutaram.

Os reis de Canaã lutaram em Taanaque,

junto às águas de Megido,

mas não levaram prata alguma, despojo algum.

20Desde o céu lutaram as estrelas,

desde as suas órbitas lutaram contra Sísera.

21O rio Quisom os levou,

o antigo rio, o rio Quisom.

Avante, minh’alma! Seja forte!

22Os cascos dos cavalos faziam tremer o chão;

galopavam, galopavam os seus poderosos cavalos.

23‘Amaldiçoem Meroz’, disse o anjo do Senhor.

‘Amaldiçoem o seu povo,

pois não vieram ajudar o Senhor,

ajudar o Senhor contra os poderosos.’

24“Que Jael seja a mais bendita das mulheres,

Jael, mulher de Héber, o queneu!

Seja ela bendita entre as mulheres

que habitam em tendas!

25Ele pediu água, e ela lhe deu leite;

numa tigela digna de príncipes trouxe-lhe coalhada.

26Ela estendeu a mão e apanhou a estaca da tenda;

e com a mão direita o martelo do trabalhador.

Golpeou Sísera, esmigalhou sua cabeça,

esmagou e traspassou suas têmporas.

27Aos seus pés ele se curvou,

caiu e ali ficou prostrado.

Aos seus pés ele se curvou e caiu;

onde caiu, ali ficou. Morto!

28“Pela janela olhava a mãe de Sísera;

atrás da grade ela exclamava:

‘Por que o seu carro se demora tanto?

Por que custa a chegar o ruído de seus carros?’

29As mais sábias de suas damas respondiam,

e ela continuava falando consigo mesma:

30‘Estarão achando e repartindo os despojos?

Uma ou duas moças para cada homem,

roupas coloridas como despojo para Sísera,

roupas coloridas e bordadas, tecidos bordados

para o meu pescoço, tudo isso como despojo?’

31“Assim pereçam todos os teus inimigos, ó Senhor!

Mas os que te amam sejam como o sol

quando se levanta na sua força”.

E a terra teve paz durante quarenta anos.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 5:1-31

Orin Debora

1Nígbà náà ni Debora àti Baraki ọmọ Abinoamu kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:

2“Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli,

nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa,

ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!

3“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé!

Èmi yóò kọrin sí Olúwa,

Èmi yóò kọrin ìyìn sí Olúwa: Ọlọ́run Israẹli.

4Olúwa nígbà tí o jáde kúrò ní Seiri,

nígbà tí ìwọ ń yan jáde wá láti pápá Edomu,

ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run sì kán sílẹ̀,

àní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú kàn omi sílẹ̀.

5Àwọn òkè ńlá wárìrì ní iwájú Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Sinai ní iwájú Olúwa

Ọlọ́run Israẹli.

6“Ní ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati,

Ní ọjọ́ Jaeli, àwọn ọ̀nà òpópó dá;

àwọn arìnrìn-àjò sì ń gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀.

7Àwọn olórí tán ní Israẹli,

wọ́n tán, títí èmi Debora fi dìde

bí ìyá ní Israẹli.

8Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun,

nígbà náà ni ogun wà ní ibodè

a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan

láàrín ẹgbàá ogun ní Israẹli bí.

9Àyà mi fà sí àwọn aláṣẹ Israẹli

àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láàrín àwọn ènìyàn

Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa!

10“Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun,

ẹ̀yin tí ń jókòó lórí ẹní dáradára,

àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà,

Ní ọ̀nà jíjìn sí 11ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi.

Níbẹ̀ ni wọ́n gbé ń sọ ti iṣẹ́ òdodo Olúwa,

àní iṣẹ́ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Israẹli.

“Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Olúwa

sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibodè.

12‘Jí, jí, Debora!

Jí, jí, kọ orin dìde!

Dìde ìwọ Baraki!

Kó àwọn ìgbèkùn rẹ ní ìgbèkùn ìwọ ọmọ Abinoamu.’

13“Nígbà náà ni àwọn tókù sọ̀kalẹ̀ àwọn ọlọ́lá lọ;

àwọn ènìyàn Olúwa tọ̀ mí wá pẹ̀lú àwọn alágbára.

14Àwọn kan jáde wá láti Efraimu, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Amaleki;

Benjamini wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ.

Láti Makiri ni àwọn aláṣẹ ti sọ̀kalẹ̀ wá,

láti Sebuluni ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.

15Àwọn ọmọ-aládé Isakari wá pẹ̀lú Debora;

bí Isakari ti ṣe olóòtítọ́ sí Baraki,

wọ́n fi ẹsẹ̀ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà.

Ní ipadò Reubeni

ni ìgbèrò púpọ̀ wà.

16Èéṣe tí ìwọ fi dúró pẹ́ láàrín agbo àgùntàn

láti máa gbọ́ fèrè olùṣọ́-àgùntàn?

Ní ipadò Reubeni

ni ìgbèrò púpọ̀ wà.

17Gileadi dúró ní òkè odò Jordani.

Èéṣe tí Dani fi dúró nínú ọkọ̀ ojú omi?

Aṣeri jókòó ní etí bèbè Òkun,

ó sì ń gbé èbúté rẹ̀.

18Àwọn ènìyàn Sebuluni fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú;

bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Naftali ní ibi gíga pápá.

19“Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;

àwọn ọba Kenaani jà

ní Taanaki ní etí odo Megido,

ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.

20Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá

láti inú ipa ọ̀nà wọn ni wọ́n bá Sisera jà.

21Odò Kiṣoni gbá wọn lọ,

odò ìgbàanì, odò Kiṣoni.

Máa yan lọ, ìwọ ọkàn mi, nínú agbára!

22Nígbà náà ni pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin ki ilẹ̀,

nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.

23‘Ẹ fi Merosi bú’ ni angẹli Olúwa wí.

‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ìbú kíkorò,

nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ Olúwa,

láti dojúkọ àwọn alágbára.’

24“Ìbùkún ni fún Jaeli,

aya Heberi ará Keni ju àwọn obìnrin lọ,

ìbùkún ni fún un ju àwọn obìnrin tí ń gbé nínú àgọ́.

25Ó béèrè omi, ó fún un ní wàrà;

ó mú òrí-àmọ́ tọ̀ ọ́ wá nínú àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́lá.

26Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,

ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà,

òòlù náà ni ó sì fi lu Sisera, ó gbá a mọ́ ọn ní orí,

ó sì gun, ó sì kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ ṣinṣin.

27Ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀

ó ṣubú; ó dùbúlẹ̀,

ó wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ṣubú níbi tí ó gbé ń wólẹ̀;

níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú sí.

28“Ìyá Sisera yọjú láti ojú fèrèsé,

ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,

‘Èéṣe tí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?

Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ fi dúró lẹ́yìn?’

29Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;

àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,

30‘Wọn kò ha ń wa kiri, wọn kò ha ti pín ìkógun bi:

ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,

fún Sisera ìkógun aṣọ aláràbarà,

ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,

àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,

gbogbo èyí tí a kó ní ogun?’

315.31: If 1.16.“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!

Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn,

nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”

Ilẹ̀ náà sì sinmi ní ogójì ọdún.