Apocalipse 18 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Apocalipse 18:1-24

A Queda da Babilônia

1Depois disso vi outro anjo que descia dos céus. Tinha grande autoridade, e a terra foi iluminada por seu esplendor. 2E ele bradou com voz poderosa:

“Caiu! Caiu a grande Babilônia!

Ela se tornou habitação de demônios

e antro de todo espírito imundo18.2 Ou maligno,

antro de toda ave impura e detestável,

3pois todas as nações beberam

do vinho da fúria da sua prostituição.

Os reis da terra se prostituíram com ela;

à custa do seu luxo excessivo

os negociantes da terra se enriqueceram”.

4Então ouvi outra voz dos céus que dizia:

“Saiam dela, vocês, povo meu,

para que vocês não participem dos seus pecados,

para que as pragas que vão cair sobre ela não os atinjam!

5Pois os pecados da Babilônia acumularam-se até o céu,

e Deus se lembrou dos seus crimes.

6Retribuam-lhe na mesma moeda;

paguem-lhe em dobro pelo que fez;

misturem para ela uma porção dupla no seu próprio cálice.

7Façam-lhe sofrer tanto tormento e tanta aflição

como a glória e o luxo a que ela se entregou.

Em seu coração ela se vangloriava:

‘Estou sentada como rainha;

não sou viúva

e jamais terei tristeza’.

8Por isso num só dia as suas pragas a alcançarão:

morte, tristeza e fome;

e o fogo a consumirá,

pois poderoso é o Senhor Deus que a julga.

9“Quando os reis da terra, que se prostituíram com ela e participaram do seu luxo, virem a fumaça do seu incêndio, chorarão e se lamentarão por ela. 10Amedrontados por causa do tormento dela, ficarão de longe e gritarão:

“ ‘Ai! A grande cidade!

Babilônia, cidade poderosa!

Em apenas uma hora chegou a sua condenação!’

11“Os negociantes da terra chorarão e se lamentarão por causa dela, porque ninguém mais compra a sua mercadoria: 12artigos como ouro, prata, pedras preciosas e pérolas; linho fino, púrpura, seda e tecido vermelho; todo tipo de madeira de cedro e peças de marfim, madeira preciosa, bronze, ferro e mármore; 13canela e outras especiarias, incenso, mirra e perfumes; vinho e azeite de oliva, farinha fina e trigo; bois e ovelhas, cavalos e carruagens, e corpos e almas de seres humanos18.13 Ou corpos, e até almas humanas.

14“Eles dirão: ‘Foram-se as frutas que tanto lhe apeteciam! Todas as suas riquezas e todo o seu esplendor se desvaneceram; nunca mais serão recuperados’. 15Os negociantes dessas coisas, que enriqueceram à custa dela, ficarão de longe, amedrontados com o tormento dela, e chorarão e se lamentarão, 16gritando:

“ ‘Ai! A grande cidade,

vestida de linho fino,

de roupas de púrpura e vestes vermelhas,

adornada de ouro, pedras preciosas e pérolas!

17Em apenas uma hora,

tamanha riqueza foi arruinada!’

“Todos os pilotos, todos os passageiros e marinheiros dos navios e todos os que ganham a vida no mar ficarão de longe. 18Ao verem a fumaça do incêndio dela, exclamarão: ‘Que outra cidade jamais se igualou a esta grande cidade?’ 19Lançarão pó sobre a cabeça e, lamentando-se e chorando, gritarão:

“ ‘Ai! A grande cidade!

Graças à sua riqueza,

nela prosperaram todos os que tinham navios no mar!

Em apenas uma hora ela ficou em ruínas!

20“ ‘Celebrem o que se deu com ela, ó céus!

Celebrem, ó santos, apóstolos e profetas!

Deus a julgou, retribuindo-lhe

o que ela fez a vocês’ ”.

21Então um anjo poderoso levantou uma pedra do tamanho de uma grande pedra de moinho, lançou-a ao mar e disse:

“Com igual violência

será lançada por terra a grande cidade de Babilônia,

para nunca mais ser encontrada.

22Nunca mais se ouvirá em seu meio

o som dos harpistas, dos músicos,

dos flautistas e dos tocadores de trombeta.

Nunca mais se achará dentro de seus muros

artífice algum, de qualquer profissão.

Nunca mais se ouvirá em seu meio

o ruído das pedras de moinho.

23Nunca mais brilhará dentro de seus muros

a luz da candeia.

Nunca mais se ouvirá ali

a voz do noivo e da noiva.

Seus mercadores eram os grandes do mundo.

Todas as nações foram seduzidas por suas feitiçarias.

24Nela foi encontrado sangue de profetas e de santos,

e de todos os que foram assassinados na terra”.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 18:1-24

Ìṣubú Babeli

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí angẹli mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀. 218.2: Isa 21.9; Jr 50.39.Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:

“Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú!

Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù,

àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,

àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,

ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo.

318.3: Jr 25.15,27.Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni

gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.

Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,

àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”

418.4: Isa 48.20; Jr 50.8.Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:

“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’

kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.

518.5: Jr 51.9.Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,

Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.

618.6: Sm 137.8.San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,

kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀

Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.

718.7: Isa 47.8-9.Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,

tí ó sì hùwà wọ̀bìà,

níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;

nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,

‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,

èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’

8Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,

ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;

a ó sì fi iná sun ún pátápátá:

nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

918.9: El 26.16-17.“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,

Babeli ìlú alágbára nì!

Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’

1118.11: El 27.36.“Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́: 1218.12: El 27.12-13,22.Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti Pearli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. 13Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.

14“Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. 1518.15: El 27.36.Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, 16wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì,

tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,

àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali!

1718.17: Isa 23.14; El 27.26-30.Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’

“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, 18wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 1918.19: El 27.30-34.Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,

nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀

ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!

Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’

2018.20: Isa 44.23; Jr 51.48.“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!

Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!

Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!

Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀

nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”

2118.21: Jr 51.63; El 26.21.Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:

“Báyìí ní a ó fi agbára ńlá

bí i Babeli ìlú ńlá ni wó,

a kì yóò sì rí i mọ́ láé.

2218.22: Isa 24.8; El 26.13.Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,

àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè,

ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;

àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé:

Àti ìró ọlọ ní a kì yóò

sì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé;

2318.23: Jr 25.10.Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé;

a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé:

nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé;

nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ.

2418.24: Jr 51.49.Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì,

àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”