2 Reis 21 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

2 Reis 21:1-26

O Reinado de Manassés, Rei de Judá

1Manassés tinha doze anos de idade quando começou a reinar e reinou cinquenta e cinco anos em Jerusalém. O nome de sua mãe era Hefzibá. 2Ele fez o que o Senhor reprova, imitando as práticas detestáveis das nações que o Senhor havia expulsado de diante dos israelitas. 3Reconstruiu os altares idólatras que seu pai, Ezequias, havia demolido e também ergueu altares para Baal e fez um poste sagrado para Aserá, como fizera Acabe, rei de Israel. Inclinou-se diante de todos os exércitos celestes e lhes prestou culto. 4Construiu altares no templo do Senhor, do qual este havia dito: “Em Jerusalém porei o meu nome”. 5Nos dois pátios do templo do Senhor ele construiu altares para todos os exércitos celestes. 6Chegou a queimar o próprio filho em sacrifício, praticou feitiçaria e adivinhação e recorreu a médiuns e a quem consultava os espíritos. Fez o que o Senhor reprova, provocando-o à ira.

7Ele tomou o poste sagrado que havia feito e o pôs no templo, do qual o Senhor tinha dito a Davi e a seu filho Salomão: “Neste templo e em Jerusalém, que escolhi dentre todas as tribos de Israel, porei o meu nome para sempre. 8Não farei os pés dos israelitas andarem errantes novamente, longe da terra que dei aos seus antepassados, se tão somente tiverem o cuidado de fazer tudo o que lhes ordenei e de obedecer a toda a Lei que meu servo Moisés lhes deu”. 9Mas o povo não quis ouvir. Manassés os desviou, a ponto de fazerem pior do que as nações que o Senhor havia destruído diante dos israelitas.

10E o Senhor disse por meio dos seus servos, os profetas: 11“Manassés, rei de Judá, cometeu esses atos repugnantes. Agiu pior do que os amorreus que o antecederam e também levou Judá a pecar com os ídolos que fizera. 12Portanto, assim diz o Senhor, o Deus de Israel: Causarei uma tal desgraça em Jerusalém e em Judá que os ouvidos de quem ouvir a respeito ficarão zumbindo. 13Estenderei sobre Jerusalém o fio de medir utilizado contra Samaria e o fio de prumo usado contra a família de Acabe. Limparei Jerusalém como se limpa um prato, lavando-o e virando-o de cabeça para baixo. 14Abandonarei o remanescente da minha herança e o entregarei nas mãos de seus inimigos. Serão despojados e saqueados por todos os seus adversários, 15pois fizeram o que eu reprovo e me provocaram à ira, desde o dia em que os seus antepassados saíram do Egito até hoje”.

16Manassés também derramou tanto sangue inocente que encheu Jerusalém de um extremo a outro; além disso levou Judá a cometer pecado e fazer o que o Senhor reprova.

17Os demais acontecimentos do reinado de Manassés e todas as suas realizações, inclusive o pecado que cometeu, estão escritos no livro dos registros históricos dos reis de Judá. 18Manassés descansou com os seus antepassados e foi sepultado no jardim do seu palácio, o jardim de Uzá. E seu filho Amom foi o seu sucessor.

O Reinado de Amom, Rei de Judá

19Amom tinha vinte e dois anos de idade quando começou a reinar e reinou dois anos em Jerusalém. O nome de sua mãe era Mesulemete, filha de Haruz; ela era de Jotbá. 20Ele fez o que o Senhor reprova, como fizera Manassés, seu pai. 21Imitou o seu pai em tudo; prestou culto aos ídolos aos quais seu pai havia cultuado e inclinou-se diante deles. 22Abandonou o Senhor, o Deus dos seus antepassados, e não andou no caminho do Senhor.

23Os oficiais de Amom conspiraram contra ele e o assassinaram em seu palácio. 24Mas o povo matou todos os que haviam conspirado contra o rei Amom, e a seu filho Josias proclamou rei em seu lugar.

25Os demais acontecimentos do reinado de Amom e as suas realizações estão escritos no livro dos registros históricos dos reis de Judá. 26Ele foi sepultado em seu túmulo no jardim de Uzá. Seu filho Josias foi o seu sucessor.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 21:1-26

Manase ọba Juda

121.1-9: 2Ki 33.1-9.Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùn-dínlọ́gọ́ta (55). Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba. 2Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 3Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. 4Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” 5Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú. 6Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

7Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé. 8Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn baba ńlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mose fi fún wọn mọ́.” 9Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ.

10Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé: 11“Manase ọba Juda ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Amori lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Juda sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀. 12Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jerusalẹmu àti Juda kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó. 13Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀n kan tí a lò lórí Jerusalẹmu àti lórí Samaria àti òjé ìdiwọ̀n ti a lò lórí ilé Ahabu. Èmi yóò sì nu Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù tí o ń nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò. 14Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, 15nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.”

16Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa.

17Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 1821.18: 2Ki 33.20.Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Amoni ọba Juda

1921.19-24: 2Ki 33.21-25.Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Orúkọ màmá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Meṣulemeti ọmọbìnrin Harusi: ó wá láti Jotba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. 20Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. 21Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀: Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn. 22Ó sì kọ Olúwa Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti Olúwa.

23Àwọn ìránṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárín ilé rẹ̀. 24Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì fi Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ààyè rẹ̀.

25Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Amoni àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 26Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Ussa. Josiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.