2 Crônicas 15 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

2 Crônicas 15:1-19

A Reforma Realizada por Asa

1O Espírito de Deus veio sobre Azarias, filho de Odede. 2Ele saiu para encontrar-se com Asa e lhe disse: “Escutem-me, Asa e todo o povo de Judá e de Benjamim. O Senhor está com vocês quando vocês estão com ele. Se o buscarem, ele deixará que o encontrem, mas, se o abandonarem, ele os abandonará. 3Durante muito tempo Israel esteve sem o verdadeiro Deus, sem sacerdote para ensiná-lo e sem a Lei. 4Mas em sua angústia eles se voltaram para o Senhor, o Deus de Israel; buscaram-no, e ele deixou que o encontrassem. 5Naqueles dias não era seguro viajar, pois muitos distúrbios afligiam todos os habitantes do território. 6Nações e cidades se destruíam umas às outras, pois Deus as estava afligindo com toda espécie de desgraças. 7Mas, sejam fortes e não desanimem, pois o trabalho de vocês será recompensado”.

8Assim que ouviu as palavras e a profecia do profeta Azarias, filho de15.8 Conforme a Vulgata e a Versão Siríaca. O Texto Massorético não traz Azarias, filho de. Odede, o rei Asa encheu-se de coragem. Retirou os ídolos repugnantes de toda a terra de Judá e de Benjamim e das cidades que havia conquistado nos montes de Efraim, e restaurou o altar do Senhor que estava em frente do pórtico do templo do Senhor.

9Depois reuniu todo o povo de Judá e de Benjamim e convocou também os que pertenciam a Efraim, a Manassés e a Simeão que viviam entre eles, pois muitos de Israel tinham passado para o lado do rei Asa, ao verem que o Senhor, o seu Deus, estava com ele.

10Eles se reuniram em Jerusalém no terceiro mês do décimo quinto ano do reinado de Asa. 11Naquela ocasião sacrificaram ao Senhor setecentos bois e sete mil ovelhas e cabras, do saque que haviam feito. 12Fizeram um acordo de todo o coração e de toda a alma de buscar o Senhor, o Deus dos seus antepassados. 13Todo aquele que não buscasse o Senhor, o Deus de Israel, deveria ser morto, gente simples ou importante,15.13 Ou jovens ou idosos, homem ou mulher. 14Fizeram esse juramento ao Senhor em alta voz, bradando ao som de cornetas e trombetas. 15Todo o povo de Judá alegrou-se com o juramento, pois o havia feito de todo o coração. Eles buscaram a Deus com a melhor disposição; ele deixou que o encontrassem e lhes concedeu paz em suas fronteiras.

16O rei Asa chegou até a depor sua avó Maaca da posição de rainha-mãe, pois ela havia feito um poste sagrado repugnante. Asa derrubou o poste, despedaçou-o e queimou-o no vale do Cedrom. 17Embora os altares idólatras não tivessem sido eliminados de Israel, o coração de Asa foi totalmente dedicado ao Senhor durante toda a sua vida. 18Ele trouxe para o templo de Deus a prata, o ouro e os utensílios que ele e seu pai haviam consagrado.

19E não houve mais nenhuma guerra até o trigésimo quinto ano do seu reinado.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 15:1-19

Àtúnṣe asà

1Ẹ̀mí Ọlọ́run wá sórí Asariah ọmọ Odedi. 2Ó jáde lọ bá Asa, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Asa, àti gbogbo Juda àti Benjamini. Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 3Fún ọjọ́ pípẹ́ ni Israẹli ti wà láì sin Ọlọ́run òtítọ́, àti láìní àlùfáà ti ń kọ́ ni, àti láìní òfin. 4Ṣùgbọ́n nínú ìpọ́njú wọn, wọ́n yí padà si Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wọ́n sì wa kiri. Wọ́n sì ri i ní ẹ̀gbẹ́ wọn. 5Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ó léwu kí ènìyàn máa rìn ìrìnàjò kiri, nítorí tí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà wà nínú làálàá ńlá 6Orílẹ̀-èdè kan ń run èkejì àti ìlú kan sí òmíràn nítorí Ọlọ́run ń yọ wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oríṣìíríṣìí ìpọ́njú. 7Ṣùgbọ́n fun ìwọ, jẹ́ alágbára, kí ó má sì ṣe ṣàárẹ̀. Nítorí tí a ó fi èrè sí iṣẹ́ ẹ̀ rẹ.”

8Nígbà tí Asa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Asariah ọmọ Odedi wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó sì mú gbogbo ohun ìríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda àti Benjamini àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní orí òkè Efraimu. Ó tún pẹpẹ Olúwa ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé Olúwa.

9Nígbà naà, ó pe gbogbo Juda àti Benjamini jọ àti àwọn ènìyàn láti Efraimu, Manase àti Simeoni tí ó ti ṣe àtìpó ní àárín wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Israẹli nígbà tí wọ́n rí i wí pé Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

10Wọ́n péjọ sí Jerusalẹmu ní oṣù kẹta ọdún kẹ́ẹ̀dógún ti ìjọba Asa. 11Ní àkókò yìí, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa ọgọ́rùn-ún méje akọ màlúù àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkógun tí wọ́n ti kó padà. 12Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn. 13Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Israẹli, pípa ni á ó pa á láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin. 14Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó ńlá àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè. 15Gbogbo Juda yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri.

1615.16–16.6: 1Ọb 15.13-22.Ọba Asa sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. 17Ṣùgbọ́n a kò mú àwọn ibi gíga náà kúrò ní Israẹli; síbẹ̀síbẹ̀ ọkàn Asa wà ní pípé ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. 18Ó sì mú àwọn ohun mímọ́ náà ti baba rẹ̀ àti àwọn ohun mímọ́ ti òun tìkára rẹ̀ tirẹ̀ wá sínú ilé Ọlọ́run, wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò náà.

19Kò sí ogun mọ́ títí fún ọdún márùn-dínlógójì ti ìjọba Asa.