1 Crônicas 18 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

1 Crônicas 18:1-17

As Vitórias Militares de Davi

1Depois disso Davi derrotou os filisteus e os subjugou, e tirou do controle deles a cidade de Gate e seus povoados.

2Davi derrotou também os moabitas, que ficaram sujeitos a ele, pagando-lhe impostos.

3Além disso, Davi derrotou Hadadezer, rei de Zobá, nas proximidades de Hamate, quando Hadadezer tentava obter o controle na região do rio Eufrates. 4Davi se apossou de mil dos seus carros de guerra, sete mil cavaleiros18.4 Ou condutores de carros e vinte mil soldados de infantaria. Ainda levou cem cavalos de carros de guerra e aleijou todos os outros.

5Quando os arameus de Damasco vieram ajudar Hadadezer, rei de Zobá, Davi matou vinte e dois mil deles. 6Em seguida, estabeleceu guarnições militares no reino dos arameus de Damasco, sujeitando-os a lhe pagarem impostos. E o Senhor dava vitórias a Davi em todos os lugares aonde ia.

7Davi também trouxe para Jerusalém os escudos de ouro usados pelos oficiais de Hadadezer. 8De Tebá18.8 Hebraico: Tibate, variante de Tebá. Veja 2Sm 8.8. e Cum, cidades que pertenciam a Hadadezer, o rei Davi trouxe grande quantidade de bronze, que Salomão usou para fazer o tanque de bronze, as colunas e vários utensílios.

9Quando Toú, rei de Hamate, soube que Davi tinha derrotado todo o exército de Hadadezer, rei de Zobá, 10enviou seu filho Adorão ao rei Davi para saudá-lo e parabenizá-lo por sua vitória na batalha contra Hadadezer, que tinha estado em guerra contra Toú. Com Adorão, mandou todo tipo de utensílios de ouro, de prata e de bronze. 11O rei Davi consagrou esses utensílios ao Senhor, como fizera com a prata e o ouro tomados de todas estas nações: Edom e Moabe, os amonitas e os filisteus e Amaleque.

12Abisai, filho de Zeruia, derrotou dezoito mil edomitas no vale do Sal. 13Depois colocou guarnições militares em Edom, sujeitando todos os edomitas a Davi. O Senhor dava vitórias a Davi em todos os lugares aonde ia.

Os Oficiais de Davi

14Davi reinou sobre todo o Israel, administrando o direito e a justiça a todo o seu povo.

15Joabe, filho de Zeruia, era comandante do exército;

Josafá, filho de Ailude, era o arquivista real;

16Zadoque, filho de Aitube, e Aimeleque18.16 Muitos manuscritos dizem Abimeleque. Veja 2Sm 8.17., filho de Abiatar, eram sacerdotes;

Sausa era secretário;

17Benaia, filho de Joiada, comandava os queretitas e os peletitas;

e os filhos do rei Davi eram seus principais oficiais.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 18:1-17

Àwọn ìṣẹ́gun Dafidi

118.1-13: 2Sa 8.1-14.Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini.

2Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

3Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Ṣoba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate. 4Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá-méjì ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.

5Nígbà ti àwọn ará Siria ti Damasku wá láti ran Hadadeseri ọba Ṣoba lọ́wọ́, Dafidi lu ẹgbàá-méjì wọn bọ lẹ̀. 6Ó sì fi àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ sínú ìjọba Siria ti Damasku, àwọn ará Siria sì ń sìn ní abẹ́ rẹ̀, wọ́n sì mú owó ìṣákọ́lẹ̀ wá. Olúwa sì ń fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní ibi gbogbo tí ó bá lọ.

7Dafidi mú apata wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. 8Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ.

9Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Ṣoba. 10Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá.

11Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.

12Abiṣai ọmọ Seruiah lu méjì-dínlógojì ẹgbẹ̀rin ará Edomu bolẹ̀ ní Àfonífojì Iyọ̀. 13Ó fi ẹgbẹ́ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sìn ní abẹ́ Dafidi. Olúwa fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibí tí ó bá lọ.

Àwọn oníṣẹ́ Dafidi

1418.14-17: 2Sa 8.15-18.Dafidi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀.

15Joabu ọmọ Seruiah jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun;

Jehoṣafati ọmọ Ahiludi jẹ́ akọ̀wé ìrántí;

16Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà;

Safsa jẹ́ akọ̀wé;

17Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ́ olórí àwọn Kereti àti Peleti;

àwọn ọmọ Dafidi sì ni àwọn olóyè oníṣẹ́ ní ọ̀dọ̀ ọba.