2 Kungaboken 25 – NUB & YCB

Swedish Contemporary Bible

2 Kungaboken 25:1-30

Babylonska fångenskapen av Jerusalem

1I Sidkias nionde regeringsår, på den tionde dagen i tionde månaden, kom Nebukadnessar, kungen av Babylonien, tågande med hela sin armé mot Jerusalem och belägrade det. De byggde en belägringsvall omkring staden. 2Belägringen varade ända till kung Sidkias elfte regeringsår.

3På nionde dagen i månaden var hungersnöden i staden så svår att folket inte längre hade någon mat i landet. 4Då stormades staden, och alla trupper flydde på natten genom en port som fanns mellan de båda murarna i närheten av den kungliga trädgården, medan de kaldeiska25:4 Samma som babylonska. trupperna omringade staden. De flydde mot Jordandalen. 5Den kaldeiska armén förföljde kungen och tog honom till fånga på Jerikoslätten. Alla hans män lämnade honom och skingrades. 6Kaldéerna grep honom och förde honom till den babyloniske kungen i Rivla, där denne dömde honom. 7De avrättade hans söner inför honom, och sedan stack man ut ögonen på honom, band honom med kopparkedjor och förde honom till Babylon.

Jerusalem läggs i ruiner

8På sjunde dagen i femte månaden av den babyloniske kungen Nebukadnessars nittonde regeringsår kom Nebusaradan, befälhavaren för livgardet och en av den babyloniske kungens tjänare, till Jerusalem. 9Han brände ner Herrens hus, kungapalatset och även alla andra byggnader av värde i Jerusalem. 10De kaldeiska trupperna som han var befälhavare för rev ner Jerusalems murar. 11Nebusaradan, befälhavaren för livgardet, förde bort i exil resten av dem som var kvar i staden, tillsammans med de desertörer som hade gått över till den babyloniske kungen, 12men några av de fattigaste i landet lämnade befälhavaren kvar för att sköta om vingårdar och åkrar.

13Kaldéerna högg ner kopparpelarna i Herrens hus, ställningen och kopparhavet som fanns där och tog med sig kopparn till Babylonien. 14De tog också kärlen, skovlarna, knivarna, fyrfaten och alla kopparföremål som användes i gudstjänsten. 15Befälhavaren för livgardet tog också fyrfaten och offerskålarna och allt annat av rent silver och guld.

16Pelarna, kopparhavet och ställningen, som Salomo låtit göra till Herrens hus, utgjorde allt som allt så mycket koppar att det inte gick att väga.

17Pelarna var nio meter höga och hade 1,5 meter höga ornament i form av granatäpplen som dekoration runt pelarhuvudet. Allt var gjort av koppar.

18Befälhavaren för livgardet tog till fånga översteprästen Seraja och prästen närmast honom, Sefanja, samt tre av dörrvakterna. 19Från staden tog han en hovman som var befälhavare i armén, fem av kungens närmaste män i staden, och sekreteraren åt den överbefälhavare som skrev ut folket till krigstjänst, samt ytterligare sextio män i staden. 20Nebusaradan, befälhavaren för livgardet, tog dem och förde dem till den babyloniske kungen i Rivla. 21Den babyloniske kungen lät avrätta dem i Rivla i Hamat.

Så fördes Juda bort från sitt land.

Jerusalem efter kapitulationen

(Jer 40:7-9; 41:1-3)

22Nebukadnessar, kungen av Babylonien, satte Gedalja, Achikams son och Shafans sonson, till ledare för dem som blev kvar i Juda. 23Befälhavarna för armén och deras män fick höra att kungen av Babylonien hade utsett Gedalja som ledare. De kom då till honom i Mispa: Ismael, Netanjas son, Jochanan, Kareachs son, Seraja, Tanchumets son från Netofa, Jaasanja, maakatitens son, och deras män. 24Gedalja gav dem och deras män sin ed och sa: ”Var inte rädda för de kaldeiska officerarna! Stanna här i landet och tjäna kungen av Babylonien, så ska det gå er väl.” 25Men i sjunde månaden kom Ismael, Netanjas son, och Elishamas sonson, som var av kunglig släkt, tillsammans med tio män till Mispa. Där dödade de Gedalja och de judar och kaldéer som var hos honom. 26Då flydde allt folk, små såväl som stora, tillsammans med officerarna, till Egypten, för de var rädda för kaldéerna.

Jojakin benådas

(Jer 52:31-34)

27Under det trettiosjunde året som Judas kung Jojakin var i fångenskap, den tjugosjunde dagen i tolfte månaden, samma år som Evil Merodak blev kung i Babylonien, benådade denne Jojakin, Juda kung, och frigav honom ur fängelset. 28Han talade vänligt till honom och gav honom den främsta platsen bland de kungar som var hos honom i Babylon. 29Jojakin fick lägga av sig fångdräkten och alltid äta vid kungens bord under resten av sitt liv. 30Så länge han levde gav kungen honom också ett dagligt underhåll.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 25:1-30

1Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ìjọba Sedekiah. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli yan lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn iṣẹ́ ìdọ̀tí fi yí gbogbo rẹ̀ ká. 2Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìgbóguntì títí di ọdún kọkànlá ti ọba Sedekiah.

3Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 4Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará Babeli wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá Arabah. 5Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, 6wọ́n sì mú un.

Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 7Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.

8Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún ìkọkàn-dínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu; 9ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńláńlá ni ó dáná sun. 10Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 11Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 12Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko.

13Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, Wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli. 14Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ. 15Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

16Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí Solomoni ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ. 17Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun.

18Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta. 19Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú. 20Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 21Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n.

Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

22Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda. 23Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn. 24Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”

25Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù Gedaliah àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará Juda àti àwọn ará Babeli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mispa. 26Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si Ejibiti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Babeli.

Wọ́n tú Jehoiakini sílẹ̀

2725.27-30: Jr 52.31-34.Ní ọdún kẹtà-dínlógójì ìgbèkùn Jehoiakini ọba Juda, ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtà-dínlógbọ̀n oṣù, Efili-Merodaki ọba Babeli, ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú. 28Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli. 29Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30Ní ojoojúmọ́, ọba fún Jehoiakini ní ìpín tirẹ̀ bí ó tí ń bẹ láààyè.