Ieremia 27 – NTLR & YCB

Nouă Traducere În Limba Română

Ieremia 27:1-22

Jugul Babilonului

1La începutul domniei lui Zedechia, fiul lui Iosia, regele lui Iuda, Ieremia a primit Cuvântul acesta din partea Domnului. 2Domnul mi‑a vorbit astfel: „Fă‑ți un jug și niște legături, și pune‑ți‑le pe gât. 3Apoi trimite‑le regelui Edomului, regelui Moabului, regelui fiilor lui Amon, regelui Tyrului și regelui Sidonului, prin mesagerii care au venit în Ierusalim la Zedechia, regele lui Iuda. 4Poruncește‑le să le spună stăpânilor lor astfel: «Așa vorbește Domnul Oștirilor, Dumnezeul lui Israel: 5Eu am făcut pământul, oamenii și animalele care sunt pe fața pământului, cu puterea Mea cea mare și cu brațul Meu întins, și îl dau oricui este drept în ochii Mei. 6Acum, am dat toate aceste țări în mâinile lui Nebucadnețar, împăratul Babilonului, slujitorul Meu. Chiar și vietățile câmpului i le‑am dat ca să‑i slujească. 7Toate neamurile îi vor sluji lui, fiului său și nepotului său până va veni și timpul țării lui. Atunci multe neamuri și împărați puternici o vor supune.

8Dar dacă vreun neam sau vreun regat nu‑i va sluji lui Nebucadnețar, împăratul Babilonului, sau nu‑și va pleca gâtul sub jugul împăratului, atunci voi pedepsi neamul acela cu sabie, cu foamete și cu molimă, zice Domnul, până îl voi nimici prin mâna lui. 9De aceea, să nu ascultați de profeții voștri, de cei care practică divinația între voi9 Pentru divinație, vezi nota de la Deut. 18:10., de visătorii voștri, de prezicătorii9 Vezi nota de la Lev. 19:26. voștri și de vrăjitorii voștri care vă spun: ‘Nu veți sluji împăratului Babilonului!’ 10Căci ei vă profețesc minciuni, ca să fiți duși departe din țara voastră. Eu vă voi izgoni și veți pieri. 11Dar pe neamul care își va pleca gâtul sub jugul împăratului Babilonului și care‑i va sluji, îl voi lăsa în țara lui, zice Domnul, ca s‑o muncească și să locuiască în ea.»“

12Am spus aceleași cuvinte și lui Zedechia, regele lui Iuda: „Plecați‑vă gâtul sub jugul împăratului Babilonului și slujiți‑i lui și poporului său ca să trăiți. 13Pentru ce să muriți, tu și poporul acesta, de sabie, de foamete și de molimă, cum a spus Domnul cu privire la orice neam care nu‑i va sluji împăratului Babilonului? 14Nu ascultați cuvintele profeților care vă spun că nu veți sluji împăratului Babilonului, căci ei vă profețesc minciuni. 15«Nu Eu i‑am trimis, zice Domnul, ci ei profețesc minciuni în Numele Meu. De aceea vă voi izgoni și veți pieri, voi și profeții care vă profețesc.»“

16Am vorbit și preoților și întregului popor, zicând: „Nu ascultați cuvintele profeților, zice Domnul, care vă spun: «Iată, obiectele Casei Domnului vor fi aduse foarte curând din Babilon», căci ei vă profețesc minciuni. 17Nu‑i ascultați, ci slujiți‑i împăratului Babilonului ca să trăiți. Pentru ce să ajungă cetatea aceasta o ruină? 18Dacă ei sunt cu adevărat profeți și dacă este în ei Cuvântul Domnului, atunci să mijlocească la Domnul Oștirilor ca obiectele care au mai rămas în Casa Domnului, în palatul regelui lui Iuda și în Ierusalim să nu fie duse în Babilon. 19Căci așa vorbește Domnul Oștirilor cu privire la stâlpi, la «mare»19 Cu referire la un bazin larg, folosit de preoți pentru îmbăiere., la piedestale și la celelalte obiecte care au mai rămas în cetatea aceasta 20și care n‑au fost luate de Nebucadnețar, împăratul Babilonului, când i‑a dus în captivitate, din Ierusalim în Babilon, pe Iehoiachin, fiul lui Iehoiachim, regele lui Iuda și pe toți nobilii lui Iuda și ai Ierusalimului; 21așa vorbește Domnul Oștirilor, Dumnezeul lui Israel, despre obiectele care au mai rămas în Casa Domnului, în palatul regelui lui Iuda și în Ierusalim: 22«Ele vor fi duse în Babilon și vor rămâne acolo până în ziua când voi veni Eu după ele, zice Domnul. Atunci le voi aduce înapoi și le voi pune în locul acesta.»“

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 27:1-22

Juda yóò sin Nebukadnessari

1Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé: 2Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ. 3Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda. 4Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ: 5Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi. 6Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀. 7Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

8“ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀; Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀. 9Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’ 10Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé. 11Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

12Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè. 13Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli? 14Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín. 15‘Èmi kò rán wọn ni Olúwa wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”

16Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn. 17Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro? 18Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 19Nítorí pé, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà. 20Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu. 21Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti ní Jerusalẹmu: 22‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Babeli, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, Èmi yóò mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”