Књига о Јестири 9 – NSP & YCB

New Serbian Translation

Књига о Јестири 9:1-32

Тријумф Јевреја

1Дванаестог месеца – а то је месец адар9,1 Фебруар/март. – тринаестог дана када је дошло време да се изврши царева реч и његов проглас, непријатељи Јевреја су се понадали да ће завладати над њима. Али све се преокренуло када су Јевреји завладали над својим мрзитељима. 2Јевреји су се окупили у њиховим градовима по свим областима цара Артаксеркса како би побили све који су им желели зло. И нико није могао да им се одупре, јер је страх спопао све народе. 3Сви обласни главари, заповедници, управитељи и цареви службеници су помагали Јеврејима, јер их је спопао страх од Мардохеја. 4Наиме, Мардохеј је био велик на царевом двору и његова слава се проносила кроз све области. Стварно је тај човек, Мардохеј, постајао све већи.

5Тако су Јевреји ударили на све своје непријатеље и сасекли их мачем. Чинили су са својим мрзитељима како су хтели кроз покољ и затирање. 6Јевреји су у престоници Сусан поклали и затрли пет стотина људи; 7и Фарсандата, Далфона и Аспата; 8Пората, Адалију и Аридата; 9Фармаста, Арисаја, Аридаја и Вајезата, 10десеторицу синова Амана, Амадетовог сина и злотвора Јевреја. Убили су их, али нису покупили плен.

11Тог дана су јавили цару број покланих у престоници Сусан. 12На то је цар рекао царици Јестири: „У престоници Сусан Јевреји су поклали и затрли пет стотина људи и десеторицу Аманових синова. Шта ли су тек урадили у остатку царевих области?! Која је твоја молба? Биће ти дано. Шта је то што још желиш? Нека буде.“

13Јестира је одговорила цару: „Ако је цару по вољи, нека се допусти још сутра Јеврејима, који су у Сусану, да чине према данашњем прогласу, и да се на вешала обесе десеторица Аманових синова.“

14Цар је заповедио да ово буде извршено. Издат је проглас у Сусану па су обесили тела десеторице побијених Аманових синова. 15Јевреји, који су били у Сусану, окупили су се четрнаестог дана месеца адара, па су у Сусану побили три стотине људи, али нису покупили плен.

16Остали Јевреји, они по царевим областима, су се окупили, па су устали да бране своје животе. И тако су се решили својих непријатеља поклавши седамдесет пет хиљада својих мрзитеља, али нису покупили плен. 17То се догодило тринаестог дана месеца адара, а четрнаестог дана су одахнули и учинили га даном гозбе и радости.

18Јевреји из Сусана су се окупили тринаестог и четрнаестог, па су одахнули петнаестог дана и учинили га даном гозбе и радости.

19Зато Јевреји са села, они који пребивају у неограђеним градовима, славе четрнаести адар у весељу, гозби, празновању и слању дарова свакоме из суседства.

Озваничење Пурима

20Мардохеј је записао све ове догађаје и разаслао писма свим Јеврејима по областима цара Артаксеркса – и онима који су близу и онима који су далеко – 21како би их обавезао да сваке године славе четрнаестог дана и петнаестог дана месеца адара. 22Наиме, тих дана су Јевреји одахнули од својих непријатеља. Тог месеца се њихова туга преокренула у радост и жалост у срећан дан. Нека за њих то буду дани гозбе и радости када ће слати дарове свакоме из суседства и сиромасима.

23Јевреји су прихватили да празнују тако како су и отпочели, а и то што им је написао Мардохеј. 24Јер Аман, син Амадета Агагеја и злотвор свих Јевреја је наумио да затре све Јевреје. Бацао је пур, то јест жреб да их смете и затре. 25Али када је то дошло пред цара, он је заповедио прогласом да се опозову његови зли науми које је осмислио против Јевреја, и то на његову штету, па су њега и његове синове обесили на вешала. 26Зато су оне дане назвали Пурим, од имена „пур“. Због свих речи овог писма, због онога што су видели у овоме и онога што им се догодило, 27Јевреји су установили и обавезали себе, своје потомке и све који су им били припојени, да неће пропустити да празнују ова два дана, према прогласу који им је дан, сваке године у време које им је одређено; 28да ће се тих дана сећати и празновати их у сваком нараштају, у сваком роду, у свакој области и у сваком граду; да се дани овог Пурима неће пропустити међу Јеврејима и да сећање на њих неће нестати у њиховом потомству.

29Са свим овлашћењем царица Јестира, ћерка Авихејева, је са Мардохејем Јеврејином написала да би потврдили ово друго писмо о Пуриму. 30Он је послао писма са речима мира и истине свим Јеврејима у стотину двадесет седам царских Артаксерксових области, 31да установи дане Пурима у прописано време као што их је установио Јеврејин Мардохеј са царицом Јестиром, онако како су се обавезали и они и њихово потомство прописима о постовима и њиховим нарицањима. 32Тако је Јестирина заповест потврдила ове прописе за Пурим и то је било записано у књигу.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esteri 9:1-32

Àwọn Júù yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun

1Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn. 2Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn. 3Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbèríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Mordekai. 4Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára.

5Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kórìíra wọn. 6Ní ilé ìṣọ́ ti Susa, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run 7Wọ́n sì tún pa Parṣandata, Dalfoni, Aspata, 8Porata, Adalia, Aridata, 9Parmaṣta, Arisai, Aridai àti Faisata, 10Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.

11Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba. 12Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.”

13Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.”

14Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́. 15Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin ní Susa, Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn.

16Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 17Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.

Àjọyọ̀ Purimu

18Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀.

19Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn.

20Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, 21Láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún 22Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní.

23Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Mordekai ti kọ̀wé sí wọn. 24Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnrarẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi. 26(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27Àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. 28A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn.

29Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀. 30Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tà-dínláàádóje (127) ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. 31Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn. 32Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.