New International Version - UK

Jeremiah 19

1This is what the Lord says: ‘Go and buy a clay jar from a potter. Take along some of the elders of the people and of the priests and go out to the Valley of Ben Hinnom, near the entrance of the Potsherd Gate. There proclaim the words I tell you, and say, “Hear the word of the Lord, you kings of Judah and people of Jerusalem. This is what the Lord Almighty, the God of Israel, says: listen! I am going to bring a disaster on this place that will make the ears of everyone who hears of it tingle. For they have forsaken me and made this a place of foreign gods; they have burned incense in it to gods that neither they nor their ancestors nor the kings of Judah ever knew, and they have filled this place with the blood of the innocent. They have built the high places of Baal to burn their children in the fire as offerings to Baal – something I did not command or mention, nor did it enter my mind. So beware, the days are coming, declares the Lord, when people will no longer call this place Topheth or the Valley of Ben Hinnom, but the Valley of Slaughter.

‘“In this place I will ruin[a] the plans of Judah and Jerusalem. I will make them fall by the sword before their enemies, at the hands of those who want to kill them, and I will give their carcasses as food to the birds and the wild animals. I will devastate this city and make it an object of horror and scorn; all who pass by will be appalled and will scoff because of all its wounds. I will make them eat the flesh of their sons and daughters, and they will eat one another’s flesh because their enemies will press the siege so hard against them to destroy them.”

10 ‘Then break the jar while those who go with you are watching, 11 and say to them, “This is what the Lord Almighty says: I will smash this nation and this city just as this potter’s jar is smashed and cannot be repaired. They will bury the dead in Topheth until there is no more room. 12 This is what I will do to this place and to those who live here, declares the Lord. I will make this city like Topheth. 13 The houses in Jerusalem and those of the kings of Judah will be defiled like this place, Topheth – all the houses where they burned incense on the roofs to all the starry hosts and poured out drink offerings to other gods.”’

14 Jeremiah then returned from Topheth, where the Lord had sent him to prophesy, and stood in the court of the Lord’s temple and said to all the people, 15 ‘This is what the Lord Almighty, the God of Israel, says: “Listen! I am going to bring on this city and all the villages around it every disaster I pronounced against them, because they were stiff-necked and would not listen to my words.”’

Notas al pie

  1. Jeremiah 19:7 The Hebrew for ruin sounds like the Hebrew for jar (see verses 1 and 10).

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 19

1Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì. Kí o sì lọ sí Àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ. Kí o sì wí pé ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya. Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi. Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí Àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n Àfonífojì Ìpakúpa.

“ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

10 “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11 Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12 Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 13 Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

14 Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, 15 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”