2 Samuel 9 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

2 Samuel 9:1-13

David and Mephibosheth

1David asked, ‘Is there anyone still left of the house of Saul to whom I can show kindness for Jonathan’s sake?’

2Now there was a servant of Saul’s household named Ziba. They summoned him to appear before David, and the king said to him, ‘Are you Ziba?’

‘At your service,’ he replied.

3The king asked, ‘Is there no-one still alive from the house of Saul to whom I can show God’s kindness?’

Ziba answered the king, ‘There is still a son of Jonathan; he is lame in both feet.’

4‘Where is he?’ the king asked.

Ziba answered, ‘He is at the house of Makir son of Ammiel in Lo Debar.’

5So King David had him brought from Lo Debar, from the house of Makir son of Ammiel.

6When Mephibosheth son of Jonathan, the son of Saul, came to David, he bowed down to pay him honour.

David said, ‘Mephibosheth!’

‘At your service,’ he replied.

7‘Don’t be afraid,’ David said to him, ‘for I will surely show you kindness for the sake of your father Jonathan. I will restore to you all the land that belonged to your grandfather Saul, and you will always eat at my table.’

8Mephibosheth bowed down and said, ‘What is your servant, that you should notice a dead dog like me?’

9Then the king summoned Ziba, Saul’s steward, and said to him, ‘I have given your master’s grandson everything that belonged to Saul and his family. 10You and your sons and your servants are to farm the land for him and bring in the crops, so that your master’s grandson may be provided for. And Mephibosheth, grandson of your master, will always eat at my table.’ (Now Ziba had fifteen sons and twenty servants.)

11Then Ziba said to the king, ‘Your servant will do whatever my lord the king commands his servant to do.’ So Mephibosheth ate at David’s9:11 Septuagint; Hebrew my table like one of the king’s sons.

12Mephibosheth had a young son named Mika, and all the members of Ziba’s household were servants of Mephibosheth. 13And Mephibosheth lived in Jerusalem, because he always ate at the king’s table; he was lame in both feet.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 9:1-13

Dafidi àti Mefiboṣeti

1Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.

2Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, Wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?”

Ó sì dáhùn wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ ni.”

3Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?”

Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”

4Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?”

Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.”

5Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.

6Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un.

Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!”

Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”

7Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”

8Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”

9Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ. 10Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ: ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)

11Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”

12Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti. 13Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.