Mark 14 – NIV & YCB

New International Version

Mark 14:1-72

Jesus Anointed at Bethany

1Now the Passover and the Festival of Unleavened Bread were only two days away, and the chief priests and the teachers of the law were scheming to arrest Jesus secretly and kill him. 2“But not during the festival,” they said, “or the people may riot.”

3While he was in Bethany, reclining at the table in the home of Simon the Leper, a woman came with an alabaster jar of very expensive perfume, made of pure nard. She broke the jar and poured the perfume on his head.

4Some of those present were saying indignantly to one another, “Why this waste of perfume? 5It could have been sold for more than a year’s wages14:5 Greek than three hundred denarii and the money given to the poor.” And they rebuked her harshly.

6“Leave her alone,” said Jesus. “Why are you bothering her? She has done a beautiful thing to me. 7The poor you will always have with you,14:7 See Deut. 15:11. and you can help them any time you want. But you will not always have me. 8She did what she could. She poured perfume on my body beforehand to prepare for my burial. 9Truly I tell you, wherever the gospel is preached throughout the world, what she has done will also be told, in memory of her.”

10Then Judas Iscariot, one of the Twelve, went to the chief priests to betray Jesus to them. 11They were delighted to hear this and promised to give him money. So he watched for an opportunity to hand him over.

The Last Supper

12On the first day of the Festival of Unleavened Bread, when it was customary to sacrifice the Passover lamb, Jesus’ disciples asked him, “Where do you want us to go and make preparations for you to eat the Passover?”

13So he sent two of his disciples, telling them, “Go into the city, and a man carrying a jar of water will meet you. Follow him. 14Say to the owner of the house he enters, ‘The Teacher asks: Where is my guest room, where I may eat the Passover with my disciples?’ 15He will show you a large room upstairs, furnished and ready. Make preparations for us there.”

16The disciples left, went into the city and found things just as Jesus had told them. So they prepared the Passover.

17When evening came, Jesus arrived with the Twelve. 18While they were reclining at the table eating, he said, “Truly I tell you, one of you will betray me—one who is eating with me.”

19They were saddened, and one by one they said to him, “Surely you don’t mean me?”

20“It is one of the Twelve,” he replied, “one who dips bread into the bowl with me. 21The Son of Man will go just as it is written about him. But woe to that man who betrays the Son of Man! It would be better for him if he had not been born.”

22While they were eating, Jesus took bread, and when he had given thanks, he broke it and gave it to his disciples, saying, “Take it; this is my body.”

23Then he took a cup, and when he had given thanks, he gave it to them, and they all drank from it.

24“This is my blood of the14:24 Some manuscripts the new covenant, which is poured out for many,” he said to them. 25“Truly I tell you, I will not drink again from the fruit of the vine until that day when I drink it new in the kingdom of God.”

26When they had sung a hymn, they went out to the Mount of Olives.

Jesus Predicts Peter’s Denial

27“You will all fall away,” Jesus told them, “for it is written:

“ ‘I will strike the shepherd,

and the sheep will be scattered.’14:27 Zech. 13:7

28But after I have risen, I will go ahead of you into Galilee.”

29Peter declared, “Even if all fall away, I will not.”

30“Truly I tell you,” Jesus answered, “today—yes, tonight—before the rooster crows twice14:30 Some early manuscripts do not have twice. you yourself will disown me three times.”

31But Peter insisted emphatically, “Even if I have to die with you, I will never disown you.” And all the others said the same.

Gethsemane

32They went to a place called Gethsemane, and Jesus said to his disciples, “Sit here while I pray.” 33He took Peter, James and John along with him, and he began to be deeply distressed and troubled. 34“My soul is overwhelmed with sorrow to the point of death,” he said to them. “Stay here and keep watch.”

35Going a little farther, he fell to the ground and prayed that if possible the hour might pass from him. 36“Abba, 14:36 Aramaic for father Father,” he said, “everything is possible for you. Take this cup from me. Yet not what I will, but what you will.”

37Then he returned to his disciples and found them sleeping. “Simon,” he said to Peter, “are you asleep? Couldn’t you keep watch for one hour? 38Watch and pray so that you will not fall into temptation. The spirit is willing, but the flesh is weak.”

39Once more he went away and prayed the same thing. 40When he came back, he again found them sleeping, because their eyes were heavy. They did not know what to say to him.

41Returning the third time, he said to them, “Are you still sleeping and resting? Enough! The hour has come. Look, the Son of Man is delivered into the hands of sinners. 42Rise! Let us go! Here comes my betrayer!”

Jesus Arrested

43Just as he was speaking, Judas, one of the Twelve, appeared. With him was a crowd armed with swords and clubs, sent from the chief priests, the teachers of the law, and the elders.

44Now the betrayer had arranged a signal with them: “The one I kiss is the man; arrest him and lead him away under guard.” 45Going at once to Jesus, Judas said, “Rabbi!” and kissed him. 46The men seized Jesus and arrested him. 47Then one of those standing near drew his sword and struck the servant of the high priest, cutting off his ear.

48“Am I leading a rebellion,” said Jesus, “that you have come out with swords and clubs to capture me? 49Every day I was with you, teaching in the temple courts, and you did not arrest me. But the Scriptures must be fulfilled.” 50Then everyone deserted him and fled.

51A young man, wearing nothing but a linen garment, was following Jesus. When they seized him, 52he fled naked, leaving his garment behind.

Jesus Before the Sanhedrin

53They took Jesus to the high priest, and all the chief priests, the elders and the teachers of the law came together. 54Peter followed him at a distance, right into the courtyard of the high priest. There he sat with the guards and warmed himself at the fire.

55The chief priests and the whole Sanhedrin were looking for evidence against Jesus so that they could put him to death, but they did not find any. 56Many testified falsely against him, but their statements did not agree.

57Then some stood up and gave this false testimony against him: 58“We heard him say, ‘I will destroy this temple made with human hands and in three days will build another, not made with hands.’ ” 59Yet even then their testimony did not agree.

60Then the high priest stood up before them and asked Jesus, “Are you not going to answer? What is this testimony that these men are bringing against you?” 61But Jesus remained silent and gave no answer.

Again the high priest asked him, “Are you the Messiah, the Son of the Blessed One?”

62“I am,” said Jesus. “And you will see the Son of Man sitting at the right hand of the Mighty One and coming on the clouds of heaven.”

63The high priest tore his clothes. “Why do we need any more witnesses?” he asked. 64“You have heard the blasphemy. What do you think?”

They all condemned him as worthy of death. 65Then some began to spit at him; they blindfolded him, struck him with their fists, and said, “Prophesy!” And the guards took him and beat him.

Peter Disowns Jesus

66While Peter was below in the courtyard, one of the servant girls of the high priest came by. 67When she saw Peter warming himself, she looked closely at him.

“You also were with that Nazarene, Jesus,” she said.

68But he denied it. “I don’t know or understand what you’re talking about,” he said, and went out into the entryway.14:68 Some early manuscripts entryway and the rooster crowed

69When the servant girl saw him there, she said again to those standing around, “This fellow is one of them.” 70Again he denied it.

After a little while, those standing near said to Peter, “Surely you are one of them, for you are a Galilean.”

71He began to call down curses, and he swore to them, “I don’t know this man you’re talking about.”

72Immediately the rooster crowed the second time.14:72 Some early manuscripts do not have the second time. Then Peter remembered the word Jesus had spoken to him: “Before the rooster crows twice14:72 Some early manuscripts do not have twice. you will disown me three times.” And he broke down and wept.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Marku 14:1-72

A da tùràrí sí ara Jesu

114.1-2: Mt 26.1-5; Lk 22.1-2; Jh 11.47-53.Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ni àjọ ìrékọjá àti tí àìwúkàrà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin sì ń wá ọ̀nà láti mú Jesu ní ìkọ̀kọ̀, kí wọn sì pa á. 2Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “A kò ní mú un ní ọjọ́ àjọ, kí àwọn ènìyàn má bá á fa ìjàngbọ̀n.”

314.3-9: Mt 26.6-13; Lk 7.36-38; Jh 12.1-8.Nígbà tí ó sì wà ní Betani ni ilé Simoni adẹ́tẹ̀ bí ó ti jókòó ti oúnjẹ, obìnrin kan wọlé, ti òun ti alabasita òróró ìkunra olówó iyebíye, ó ṣí ìgò náà, ó sì da òróró náà lé Jesu lórí.

4Àwọn kan nínú àwọn tí ó jókòó ti tábìlì kún fún ìbànújẹ́. Wọ́n sì ń bi ara wọn pé, “Nítorí kí ni a ṣe fi òróró yìí ṣòfò? 5Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.

6Ṣùgbọ́n Jesu wí fún pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ ń yọ ọ́ lẹ́nu fún ṣé nítorí tí ó ṣe ohun rere sí mi? 714.7: De 15.11.Nígbà gbogbo ni àwọn tálákà wà ní àárín yín, wọ́n sì ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ yín. Ẹ sì lè ṣe oore fún wọn nígbàkúgbà tí ẹ bá fẹ́. 814.8: Jh 19.40.Ó ti ṣe èyí tí ó lè ṣe, o ti fi òróró kùn mí ni ara ní ìmúrasílẹ̀ de ìgbà tí wọn yóò sin òkú mi. 9Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, níbikíbi tí wọ́n bá ti wàásù mi, ní gbogbo ayé, wọn kò ní ṣe aláìsọ ohun tí obìnrin yìí ṣe pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”

1014.10-11: Mt 26.14-16; Lk 22.3-6.Nígbà náà ni Judasi Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, láti ṣètò bí yóò ti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. 11Inú wọn dùn láti gbọ́ èyí, wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Nítorí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ àkókò tí ó rọrùn tí òun yóò fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.

Oúnjẹ alẹ́ Olúwa

1214.12-16: Mt 26.17-19; Lk 22.7-13.Ní ọjọ́ kìn-ín-ní àjọ̀dún ìrékọjá tí í ṣe ọjọ́ tí wọ́n máa ń pa ẹran àgùntàn fún ìrúbọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í léèrè pé, “Níbo ni ìwọ fẹ́ kí a lọ pèsè sílẹ̀ tí ìwọ yóò ti jẹ àsè ìrékọjá?”

13Ó rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sínú ìlú, ọkùnrin kan tó ru ìkòkò omi yóò pàdé yín, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 14Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé: Níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’ 15Òun yóò sì mú un yín lọ sí gbàngàn ńlá kan lókè ilé náà, tí a ti ṣe lọ́sọ́. Níbẹ̀ ni kí ẹ pèsè sílẹ̀ dè wá.”

16Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.

1714.17-21: Mt 26.20-25; Lk 22.14,21-23; Jh 13.21-30; Sm 41.9.Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀. 18Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”

19Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”

20Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. 21Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: Ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”

2214.22-25: Mt 26.26-29; Lk 22.17-19; 1Kọ 11.23-26.14.22: Mk 6.41; 8.6; Lk 24.30.Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”

2314.23: 1Kọ 10.16.Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

2414.24: Ek 24.8; Hb 9.20.Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. 25Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

2614.26-31: Mt 26.30-35; Lk 22.33-34,39.Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè olifi lọ.

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun

2714.27: Sk 13.7; Jh 16.32.Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé:

“ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn

àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

2814.28: Mk 16.7.Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”

29Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”

3014.30: Mk 14.66-72; Jh 13.36-38; 18.17-18,25-27.Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

31Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.

Ọgbà Getsemane

3214.32-42: Mt 26.36-46; Lk 22.40-46; Hb 5.7-8.Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.” 33Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. 3414.34: Jh 12.27.Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.”

35Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. 3614.36: Ro 8.15; Ga 4.6; Mk 10.38; Jh 18.11.Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”

37Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 3814.38: Mt 6.13; Lk 11.4.Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú. 40Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.

41Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”

A mú Jesu

4314.43-50: Mt 26.47-56; Lk 22.47-53; Jh 18.2-11.Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Judasi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbàgbà Júù ni ó rán wọn wá.

44Judasi tí fi ààmì fún wọn wí pe, “Ẹni tí mo bá fi ẹnu kò lẹ́nu nínú wọn, òun ní Jesu, Ẹ mú un.” 45Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, Judasi lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrà, ó wí pé, “Rabbi!” ó sì fi ẹnu kò Jesu lẹ́nu. 46Wọ́n sì mú Jesu. 47Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró fa idà rẹ̀ yọ, ó fi ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.

48Nígbà náà Jesu dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú? 4914.49: Lk 19.47; Jh 18.19-21.Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹmpili, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.” 50Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sálọ.

51Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà. 52Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sálọ ní ìhòhò.

Jesu níwájú ìgbìmọ̀ Sahẹndiri

5314.53-65: Mt 26.57-68; Lk 22.54-55,63-71; Jh 18.12-24.Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀. 54Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.

55Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rìí èké sí Jesu, èyí tí ó jọjú dáradára láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí. 56Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu.

57Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní 5814.58: Mk 13.2; 15.29; Ap 6.14; Jh 2.19.“A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹmpili tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ” 59Síbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba.

60Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ síwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jesu léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ̀?” 61Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́.

Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?”

6214.62: Da 7.13; Mk 9.1; 13.26.Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”

6314.63: Ap 14.14; Nu 14.6.Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 6414.64: Le 24.16.Ẹ̀yin fúnrayín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”

Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” 65Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

Peteru sẹ́ Jesu

6614.66-72: Mt 26.69-75; Lk 22.56-62; Jh 18.16-18,25-27; Mk 14.30.Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná. 67Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ti yáná, Ó tẹjúmọ́ ọn.

Ó sì sọ gbangba pé, “Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jesu ara Nasareti.”

68Ṣùgbọ́n Peteru sẹ́, ó ni, “N kò mọ Jesu náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Peteru sì jáde lọ sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ.

69Ọmọbìnrin náà sì tún rí Peteru. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.” 70Ṣùgbọ́n Peteru tún sẹ́.

Nígbà tí ó sí túnṣe díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Peteru wá wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni, ọ̀kan ní ara wọn ni ìwọ í ṣe. Nítorí ará Galili ni ìwọ, èdè rẹ sì jọ bẹ́ẹ̀.”

71Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!”

72Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.