1 Samuel 12 – NIV & YCB

New International Version

1 Samuel 12:1-25

Samuel’s Farewell Speech

1Samuel said to all Israel, “I have listened to everything you said to me and have set a king over you. 2Now you have a king as your leader. As for me, I am old and gray, and my sons are here with you. I have been your leader from my youth until this day. 3Here I stand. Testify against me in the presence of the Lord and his anointed. Whose ox have I taken? Whose donkey have I taken? Whom have I cheated? Whom have I oppressed? From whose hand have I accepted a bribe to make me shut my eyes? If I have done any of these things, I will make it right.”

4“You have not cheated or oppressed us,” they replied. “You have not taken anything from anyone’s hand.”

5Samuel said to them, “The Lord is witness against you, and also his anointed is witness this day, that you have not found anything in my hand.”

“He is witness,” they said.

6Then Samuel said to the people, “It is the Lord who appointed Moses and Aaron and brought your ancestors up out of Egypt. 7Now then, stand here, because I am going to confront you with evidence before the Lord as to all the righteous acts performed by the Lord for you and your ancestors.

8“After Jacob entered Egypt, they cried to the Lord for help, and the Lord sent Moses and Aaron, who brought your ancestors out of Egypt and settled them in this place.

9“But they forgot the Lord their God; so he sold them into the hand of Sisera, the commander of the army of Hazor, and into the hands of the Philistines and the king of Moab, who fought against them. 10They cried out to the Lord and said, ‘We have sinned; we have forsaken the Lord and served the Baals and the Ashtoreths. But now deliver us from the hands of our enemies, and we will serve you.’ 11Then the Lord sent Jerub-Baal,12:11 Also called Gideon Barak,12:11 Some Septuagint manuscripts and Syriac; Hebrew Bedan Jephthah and Samuel,12:11 Hebrew; some Septuagint manuscripts and Syriac Samson and he delivered you from the hands of your enemies all around you, so that you lived in safety.

12“But when you saw that Nahash king of the Ammonites was moving against you, you said to me, ‘No, we want a king to rule over us’—even though the Lord your God was your king. 13Now here is the king you have chosen, the one you asked for; see, the Lord has set a king over you. 14If you fear the Lord and serve and obey him and do not rebel against his commands, and if both you and the king who reigns over you follow the Lord your God—good! 15But if you do not obey the Lord, and if you rebel against his commands, his hand will be against you, as it was against your ancestors.

16“Now then, stand still and see this great thing the Lord is about to do before your eyes! 17Is it not wheat harvest now? I will call on the Lord to send thunder and rain. And you will realize what an evil thing you did in the eyes of the Lord when you asked for a king.”

18Then Samuel called on the Lord, and that same day the Lord sent thunder and rain. So all the people stood in awe of the Lord and of Samuel.

19The people all said to Samuel, “Pray to the Lord your God for your servants so that we will not die, for we have added to all our other sins the evil of asking for a king.”

20“Do not be afraid,” Samuel replied. “You have done all this evil; yet do not turn away from the Lord, but serve the Lord with all your heart. 21Do not turn away after useless idols. They can do you no good, nor can they rescue you, because they are useless. 22For the sake of his great name the Lord will not reject his people, because the Lord was pleased to make you his own. 23As for me, far be it from me that I should sin against the Lord by failing to pray for you. And I will teach you the way that is good and right. 24But be sure to fear the Lord and serve him faithfully with all your heart; consider what great things he has done for you. 25Yet if you persist in doing evil, both you and your king will perish.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 12:1-25

Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli

1Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín. 2Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí. 3Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni ààmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”

4Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”

5Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni ààmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”

Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

6Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti. 7Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.

8“Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.

9“Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà. 10Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’ 11Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.

12“Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín. 13Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín. 14Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára 15ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.

16“Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! 17Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”

18Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.

19Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”

20Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa. 21Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n. 22Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀. 23Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́. 24Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín; Ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. 25Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”