Luke 19 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

Luke 19:1-48

Zacchaeus the Tax Collector

1Jesus entered Jericho and was passing through. 2A man named Zacchaeus lived there. He was a chief tax collector and was very rich. 3Zacchaeus wanted to see who Jesus was. But he was a short man. He could not see Jesus because of the crowd. 4So he ran ahead and climbed a sycamore-fig tree. He wanted to see Jesus, who was coming that way.

5Jesus reached the spot where Zacchaeus was. He looked up and said, “Zacchaeus, come down at once. I must stay at your house today.” 6So Zacchaeus came down at once and welcomed him gladly.

7All the people saw this. They began to whisper among themselves. They said, “Jesus has gone to be the guest of a sinner.”

8But Zacchaeus stood up. He said, “Look, Lord! Here and now I give half of what I own to those who are poor. And if I have cheated anybody out of anything, I will pay it back. I will pay back four times the amount I took.”

9Jesus said to Zacchaeus, “Today salvation has come to your house. You are a member of Abraham’s family line. 10The Son of Man came to look for the lost and save them.”

The Story of Three Slaves

11While the people were listening to these things, Jesus told them a story. He was near Jerusalem. The people thought that God’s kingdom was going to appear right away. 12Jesus said, “A man from an important family went to a country far away. He went there to be made king and then return home. 13So he sent for ten of his slaves. He gave them each about three months’ pay. ‘Put this money to work until I come back,’ he said.

14“But those he ruled over hated him. They sent some messengers after him. They were sent to say, ‘We don’t want this man to be our king.’

15“But he was made king and returned home. Then he sent for the slaves he had given the money to. He wanted to find out what they had earned with it.

16“The first one came to him. He said, ‘Sir, your money has earned ten times as much.’

17“ ‘You have done well, my good slave!’ his master replied. ‘You have been faithful in a very small matter. So I will put you in charge of ten towns.’

18“The second slave came to his master. He said, ‘Sir, your money has earned five times as much.’

19“His master answered, ‘I will put you in charge of five towns.’

20“Then another slave came. He said, ‘Sir, here is your money. I have kept it hidden in a piece of cloth. 21I was afraid of you. You are a hard man. You take out what you did not put in. You harvest what you did not plant.’

22“His master replied, ‘I will judge you by your own words, you evil slave! So you knew that I am a hard man? You knew that I take out what I did not put in? You knew that I harvest what I did not plant? 23Then why didn’t you put my money in the bank? When I came back, I could have collected it with interest.’

24“Then he said to those standing by, ‘Take his money away from him. Give it to the one who has ten times as much.’

25“ ‘Sir,’ they said, ‘he already has ten times as much!’

26“He replied, ‘I tell you that everyone who has will be given more. But here is what will happen to anyone who has nothing. Even what they have will be taken away from them. 27And what about my enemies who did not want me to be king over them? Bring them here! Kill them in front of me!’ ”

Jesus Comes to Jerusalem as King

28After Jesus had said this, he went on ahead. He was going up to Jerusalem. 29He approached Bethphage and Bethany. The hill there was called the Mount of Olives. Jesus sent out two of his disciples. He said to them, 30“Go to the village ahead of you. As soon as you get there, you will find a donkey’s colt tied up. No one has ever ridden it. Untie it and bring it here. 31Someone may ask you, ‘Why are you untying it?’ If so, say, ‘The Lord needs it.’ ”

32Those who were sent ahead went and found the young donkey. It was there just as Jesus had told them. 33They were untying the colt when its owners came. The owners asked them, “Why are you untying the colt?”

34They replied, “The Lord needs it.”

35Then the disciples brought the colt to Jesus. They threw their coats on the young donkey and put Jesus on it. 36As he went along, people spread their coats on the road.

37Jesus came near the place where the road goes down the Mount of Olives. There the whole crowd of disciples began to praise God with joy. In loud voices they praised him for all the miracles they had seen. They shouted,

38“Blessed is the king who comes in the name of the Lord!” (Psalm 118:26)

“May there be peace and glory in the highest heaven!”

39Some of the Pharisees in the crowd spoke to Jesus. “Teacher,” they said, “tell your disciples to stop!”

40“I tell you,” he replied, “if they keep quiet, the stones will cry out.”

41He approached Jerusalem. When he saw the city, he began to weep. 42He said, “I wish you had known today what would bring you peace! But now it is hidden from your eyes. 43The days will come when your enemies will arrive. They will build a wall of dirt up against your city. They will surround you and close you in on every side. 44You didn’t recognize the time when God came to you. So your enemies will smash you to the ground. They will destroy you and all the people inside your walls. They will not leave one stone on top of another.”

Jesus Clears Out the Temple

45Then Jesus entered the temple courtyard. He began to drive out those who were selling there. 46He told them, “It is written that the Lord said, ‘My house will be a house where people can pray.’ (Isaiah 56:7) But you have made it a ‘den for robbers.’ ” (Jeremiah 7:11)

47Every day Jesus was teaching at the temple. But the chief priests and the teachers of the law were trying to kill him. So were the leaders among the people. 48But they couldn’t find any way to do it. All the people were paying close attention to his words.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 19:1-48

Sakeu agbowó òde

119.1: Mk 10.46.Jesu sì wọ Jeriko lọ, ó sì ń kọjá láàrín rẹ̀. 2Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà tí a ń pè ní Sakeu, ó sì jẹ́ olórí agbowó òde kan, ó sì jẹ́ ọlọ́rọ̀. 3Ó sì ń fẹ́ láti rí ẹni tí Jesu jẹ́: kò sì lè rí i, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti nítorí tí òun jẹ́ ènìyàn kúkúrú. 4Ó sì súré síwájú, ó gun orí igi sikamore kan, kí ó bà lè rí i: nítorí tí yóò kọjá lọ níhà ibẹ̀.

5Nígbà tí Jesu sì dé ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i, ó sì wí fún un pé, “Sakeu! Yára, kí o sì sọ̀kalẹ̀; nítorí pé èmi yóò wọ ilé rẹ lónìí.” 6Ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbà á.

719.7: Lk 5.29-30; 15.1-2.Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”

819.8: Lk 7.13; 3.14; Ek 22.1; Le 6.5; Nu 5.6-7.Sakeu sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wò ó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fi fún tálákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”

919.9: Lk 3.8; 13.16; Ro 4.16.Jesu sì wí fún un pé, “Lónìí ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Abrahamu. 10Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”

Òwe minas mẹ́wàá

1119.11: Lk 9.51; 13.22; 17.11; 18.31; 9.27.Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀síwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ́ Jerusalẹmu, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí. 1219.12-28: Mt 25.14-30.19.12: Mk 13.34.Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà. 13Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’

14“Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’

15“Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.

16“Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’

1719.17: Lk 16.10.“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’

18“Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’

19“Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’

20“Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan; 21Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’

22“Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn; 23Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’

24“Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó minas mẹ́wàá.’

25“Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mina mẹ́wàá.’

2619.26: Mt 13.12; Mk 4.25; Lk 8.18.“Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fi fún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. 27Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jẹ ọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhín yìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”

Ó wọ ilé pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

2819.28: Mk 10.32.Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 2919.29-38: Mt 21.1-9; Mk 11.1-10; Jh 12.12-18.Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

3219.32: Lk 22.13.Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

3419.34: Lk 7.13.Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”

35Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. 3619.36: 2Ọb 9.13.Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.

37Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;

3819.38: Sm 118.26; Lk 13.35; 2.14.Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”

3919.39-40: Mt 21.15-16; Hb 2.11.Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”

40Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”

4119.41: Lk 13.33-34.Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 4319.43: Lk 21.21-24; 21.6; Isa 29.3; Jr 6.6; El 4.2.Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 4419.44: 1Pt 2.12.Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”

Jesu nínú tẹmpili

4519.45-46: Mt 21.12-13; Mk 11.15-17; Jh 2.13-17.Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”

4719.47-48: Mk 11.18; Lk 21.37; 22.53.Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.