1 Chronicles 13 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

1 Chronicles 13:1-14

David Brings Back the Ark

1David talked with each of his officers. He wanted to get their advice. Some of them were commanders of thousands of men. Others were commanders of hundreds. 2David spoke to the whole community of Israel. He said, “Let’s send word to the rest of our people no matter how far away they live. They live in all the territories of Israel. Let’s also send word to the priests and Levites who are with them in their towns and on their grasslands. Let’s invite everyone to come and join us. Let’s do it if it seems good to you and if that’s what the Lord our God wants. 3Let’s bring the ark of our God back here to us. We didn’t use it to ask God for advice during the whole time Saul was king.” 4So that’s what the whole community agreed to do. It seemed right to them.

5David gathered together all the Israelites. They came from the area between the Shihor River in Egypt and Lebo Hamath. They came to bring the ark of God from Kiriath Jearim to Jerusalem. 6David went to Baalah of Judah. The whole community of Israel went with him. Baalah is also called Kiriath Jearim. All the people went there to get the ark of God the Lord. He sits on his throne between the cherubim. The ark is named after the Lord.

7The ark of God was placed on a new cart. Then it was moved from Abinadab’s house. Uzzah and Ahio were guiding it. 8David was celebrating with all his might in front of God. So was the whole community of Israel. All of them were singing songs. They were also playing harps, lyres, tambourines, cymbals and trumpets.

9They came to the threshing floor of Kidon. The oxen nearly fell there. So Uzzah reached out his hand to hold the ark steady. 10Then the Lord became very angry with Uzzah. The Lord struck him down because he had put his hand on the ark. So Uzzah died there in front of God.

11David was angry because the Lord’s great anger had broken out against Uzzah. That’s why the place is still called Perez Uzzah to this day.

12David was afraid of God that day. David asked, “How can I ever bring the ark of God back here to me?” 13So he didn’t take the ark to be with him in the City of David. Instead, he took it to the house of Obed-Edom. Obed-Edom was from Gath. 14The ark of God remained with the family of Obed-Edom. It stayed in his house for three months. And the Lord blessed his family. He also blessed everything that belonged to him.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 13:1-14

Gbígbé padà àpótí ẹ̀rí

113.1-14: 2Sa 6.1-11.Dafidi sì gbèrò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ ọgọ́rùn-ún 2Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Israẹli pé, Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jíjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tókù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Israẹli àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọ pọ̀ sọ́dọ̀ wa. 3Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Saulu. 4Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.

5Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu. 6Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Olúwa tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù—gòkè wá.

7Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ. 8Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè.

9Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. 10Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

11Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa.

12Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi? 13Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. 14Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, Olúwa sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.