Luka 4 – NEN & YCB

Kiswahili Contemporary Version (Neno: Bibilia Takatifu)

Luka 4:1-44

Yesu Ajaribiwa Na Shetani

(Mathayo 4:1-11; Marko 1:12-13)

14:1 Lk 1:15-45; 3:3-21; Eze 37:1; Lk 2:27Yesu, akiwa amejaa Roho Mtakatifu, akarudi kutoka Yordani. Akaongozwa na Roho Mtakatifu hadi nyikani, 24:2 Kut 34:28; 1Fal 19:8mahali ambako kwa siku arobaini alikuwa akijaribiwa na ibilisi. Kwa siku zote hizo hakula chochote, hivyo baada ya muda huo akaona njaa.

34:3 Mt 4:3Ibilisi akamwambia, “Ikiwa wewe ni Mwana wa Mungu, amuru jiwe hili liwe mkate.”

44:4 Kum 8:3Yesu akajibu akamwambia, “Imeandikwa: ‘Mtu haishi kwa mkate tu.’ ”

54:5 Mt 24:14Ibilisi akampeleka hadi juu ya mlima mrefu akamwonyesha milki zote za dunia kwa mara moja. 64:6 Yn 14:30Akamwambia, “Nitakupa mamlaka juu ya milki hizi na fahari zake zote, kwa maana zimekabidhiwa mkononi mwangu nami ninaweza kumpa yeyote ninayetaka. 7Hivyo ikiwa utanisujudia na kuniabudu, vyote vitakuwa vyako.”

84:8 Kum 6:3Yesu akamjibu, “Imeandikwa: ‘Mwabudu Bwana Mungu wako na umtumikie yeye peke yake.’ ”

94:9 Mt 4:5Kisha ibilisi akampeleka mpaka Yerusalemu, akamweka juu ya mnara mrefu wa Hekalu, akamwambia, “Kama wewe ndiwe Mwana wa Mungu, jitupe chini kutoka hapa, 104:10 Za 91:11, 12kwa maana imeandikwa:

“ ‘Atakuagizia malaika zake

ili wakulinde;

114:11 Za 91:12nao watakuchukua mikononi mwao,

usije ukajikwaa mguu wako katika jiwe.’ ”

124:12 Kum 6:12Yesu akamjibu, “Imesemwa, ‘Usimjaribu Bwana Mungu wako.’ ”

134:13 Ebr 4:15; Yn 14:30Ibilisi alipomaliza kila jaribu, akamwacha Yesu mpaka wakati mwingine ufaao.

Mwanzo Wa Huduma Ya Galilaya

(Mathayo 4:12-17; Marko 1:14-15)

144:14 Mt 4:12; 9:26Kisha Yesu akarudi mpaka Galilaya, akiwa amejaa nguvu za Roho Mtakatifu, nazo habari zake zikaenea katika sehemu zote za nchi za kandokando. 154:15 Mt 4:23Akaanza kufundisha kwenye masinagogi yao, na kila mmoja akamsifu.

Yesu Akataliwa Nazareti

(Mathayo 13:53-58; Marko 6:1-6)

164:16 Mt 2:23; 13:54Yesu akaenda Nazareti, alipolelewa, na siku ya Sabato alikwenda katika sinagogi kama ilivyokuwa desturi yake. Akasimama ili asome, 174:17 Isa 61:1, 2; 58:6naye akapewa kitabu cha nabii Isaya, akakifungua na kukuta mahali palipoandikwa:

184:18 Yn 3:34“Roho wa Bwana yu juu yangu,

kwa sababu amenitia mafuta

kuwahubiria maskini habari njema.

Amenituma kuwatangazia wafungwa

kufunguliwa kwao,

na vipofu kupata kuona tena,

kuwaweka huru wanaoonewa,

19na kutangaza mwaka wa Bwana uliokubalika.”

204:20 Mt 26:55Kisha akakifunga kitabu, akamrudishia mtumishi na akaketi. Watu wote waliokuwamo katika sinagogi wakamkazia macho. 214:21 Mt 1:22Ndipo akaanza kwa kuwaambia, “Leo Andiko hili limetimia mkiwa mnasikia.”

224:22 Yn 6:42; 7:15Wote waliokuwako wakamsifu na kuyastaajabia maneno yake yaliyojaa neema, wakaulizana, “Je, huyu si mwana wa Yosefu?”

234:23 Mt 2:23; Mk 1:21-28; 2:1-12Yesu akawaambia, “Bila shaka mtatumia mithali hii: ‘Tabibu, jiponye mwenyewe! Mambo yale tuliyosikia kwamba uliyafanya huko Kapernaumu, yafanye na hapa kwenye mji wako.’ ”

244:24 Mt 13:57; Yn 4:44Yesu akasema, “Amin, nawaambia, hakuna nabii anayekubalika katika mji wake mwenyewe. 254:25 1Fal 18:1; Ufu 11:6Lakini ukweli ni kwamba palikuwa na wajane wengi katika Israeli wakati wa Eliya, mbingu zilipofungwa kwa miaka mitatu na miezi sita pakawa na njaa kuu katika nchi nzima. 264:26 1Fal 17:8-16; Mt 11:21Hata hivyo Eliya hakutumwa hata kwa mmoja wao, bali kwa mjane mmoja wa Sarepta katika nchi ya Sidoni. 274:27 2Fal 5:1-14Pia palikuwa na wengi wenye ukoma katika Israeli katika siku za nabii Elisha, lakini hakuna hata mmoja wao aliyetakaswa, isipokuwa Naamani mtu wa Shamu.”4:27 Shamu hapa inamaanisha Syria.

28Watu wote katika sinagogi waliposikia maneno haya, wakakasirika sana. 294:29 Hes 15:35; Ebr 13:12Wakasimama, wakamtoa nje ya mji, wakamchukua hadi kwenye kilele cha mlima mahali ambapo mji huo ulikuwa umejengwa, ili wamtupe chini kutoka kwenye mteremko mkali. 304:30 Yn 8:59; 10:39Lakini yeye akapita papo hapo katikati ya huo umati wa watu akaenda zake.

Yesu Atoa Pepo Mchafu

(Marko 1:21-28)

314:31 Mt 4:13Kisha Yesu akashuka kwenda Kapernaumu, mji wa Galilaya, na katika siku ya Sabato akawa anafundisha. 324:32 Mt 7:28-29Wakashangazwa sana na mafundisho yake, maana maneno yake yalikuwa na mamlaka.

334:33 Mk 1:23Ndani ya sinagogi palikuwa na mtu aliyekuwa amepagawa na pepo mchafu. Naye akapiga kelele kwa nguvu akisema, 344:34 Mt 8:28-29; Mk 1:24; Yak 2:19“Tuache! Tuna nini nawe, Yesu wa Nazareti? Je, umekuja kutuangamiza? Ninakujua wewe ni nani. Wewe ndiwe Aliye Mtakatifu wa Mungu!”

354:35 Mt 8:26; Lk 8:24Basi Yesu akamkemea yule pepo mchafu, akisema, “Nyamaza kimya! Nawe umtoke!” Yule pepo mchafu akamwangusha yule mtu chini mbele yao wote, akatoka pasipo kumdhuru. 364:36 Mt 7:28-29; 10:1Watu wote wakashangaa, wakaambiana, “Mafundisho haya ni ya namna gani? Anawaamuru pepo wachafu kwa mamlaka na nguvu, nao wanatoka!” 374:37 Mt 9:26Habari zake zikaanza kuenea kila mahali katika sehemu ile.

Yesu Awaponya Wengi

(Mathayo 8:14-17; Marko 1:29-34)

384:38 Mt 8:14; Mk 1:29Yesu akatoka katika sinagogi, akaenda nyumbani kwa Simoni. Basi huko alimkuta mama mkwe wa Simoni akiwa ameshikwa na homa kali, nao wakamwomba Yesu amsaidie. 394:39 Lk 4:35, 41Hivyo Yesu akamwinamia na kukemea ile homa, nayo ikamwacha. Akaamka saa ile ile, naye akaanza kuwahudumia.

404:40 Mk 5:23; Mt 4:23Jua lilipokuwa linatua, watu wakamletea Yesu watu wote waliokuwa na maradhi mbalimbali, naye akaweka mikono yake juu ya kila mgonjwa, naye akawaponya. 414:41 Mt 4:3; 8:4Pepo wachafu pia wakawatoka watu wengi, nao walipokuwa wakitoka wakapiga kelele, wakisema: “Wewe ni Mwana wa Mungu!” Lakini Yesu akawakemea na kuwazuia wasiseme, kwa maana walimjua kuwa yeye ndiye Kristo.4:41 Kristo maana yake ni Masiya, yaani Aliyetiwa mafuta.

424:42 Mk 1:35Kesho yake, kulipopambazuka, Yesu alikwenda mahali pa faragha. Watu wengi wakawa wanamtafuta kila mahali, nao walipomwona wakajaribu kumzuia asiondoke. 434:43 Mt 3:2Lakini yeye akawaambia, “Imenipasa kuhubiri habari njema za Ufalme wa Mungu katika miji mingine pia, kwa maana kwa kusudi hili nilitumwa.” 444:44 Mt 4:23Naye aliendelea kuhubiri katika masinagogi ya Uyahudi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 4:1-44

Ìdánwò Jesu

14.1-13: Mt 4.1-11; Mk 1.12-13.Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù; 24.2: De 9.9; 1Ọb 19.8.Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.

3Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

44.4: De 8.3.Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”

5Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. 64.6: 1Jh 5.19.Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. 7Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”

84.8: De 6.13.Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”

9Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí: 104.10-11: Sm 91.11-12.A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,

láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ:

11Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,

kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

124.12: De 6.16.Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

134.13: Lk 22.28.Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.

A kọ Jesu ni Nasareti

144.14: Mt 4.12; Mk 1.14; Mt 9.26; Lk 4.37.Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. 154.15: Mt 4.23; 9.35; 11.1.Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.

164.16-30: Mt 13.53-58; Mk 6.1-6; Isa 13.14-16.Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. 17A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:

18“Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,

Nítorí tí ó fi ààmì òróró yàn mí

láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì.

Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti

ìmúnríran fún àwọn afọ́jú,

àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,

19láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”

20Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”

224.22: Jh 6.42; 7.15.Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”

234.23: Mk 1.21; 2.1; Jh 4.46.Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapernaumu, ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”

244.24: Jh 4.44.Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. 254.25: 1Ọb 17.1,8-16; 18.1; Jk 5.17-18.Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo; 26Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni. 274.27: 2Ọb 5.1-14.Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.”

28Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, 294.29: Ap 7.58; Nu 15.35.Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. 304.30: Jh 8.59; 10.39.Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.

Jesu lé ẹ̀mí èṣù jáde

314.31-37: Mk 1.21-28.Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. 324.32: Mt 7.28; 13.54; 22.33; Mk 11.18; Jh 7.46.Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.

33Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, 34“Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”

35Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.

36Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” 374.37: Lk 4.14; 5.15; Mt 9.26.Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká.

Jesu wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn

384.38-41: Mt 8.14-17; Mk 1.29-34.Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. 39Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

40Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. 41Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi náà.

424.42-43: Mk 1.35-38.Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.” 444.44: Mt 4.23; Mk 1.39; Mt 9.35.Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.