ዘፀአት 16 – NASV & YCB

New Amharic Standard Version

ዘፀአት 16:1-36

መናና ድርጭት

1መላው የእስራኤል ማኅበር ከግብፅ በወጡ በሁለተኛው ወር በዐሥራ አምስተኛው ቀን ከኤሊም ተነሥተው በኤሊምና በሲና መካከል ወደምትገኘው ወደ ሲን ምድረ በዳ መጡ። 2በምድረ በዳውም መላው ማኅበር በሙሴና በአሮን ላይ አጕረመረሙ። 3እስራኤላውያንም እነርሱን እንዲህ አሏቸው፣ “በሥጋ መቀቀያው ምንቸት ዙሪያ ተቀምጠን የፈለግነውን ያህል ምግብ መመገብ በምንችልበት በግብፅ ሳለን፣ ምነው በእግዚአብሔር (ያህዌ) እጅ ሞተን ባረፍነው ኖሮ! እናንተ ግን ይህ ሁሉ ጉባኤ በራብ እንዲያልቅ ወደዚህ ምድረ በዳ አመጣችሁን” አሏቸው።

4ከዚያም እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን አለው፤ “ከሰማይ እንጀራ አዘንብላችኋለሁ። ሕዝቡም በየቀኑ እየወጡ ለዕለት የሚበቃቸውን ይሰበስቡ፤ በዚህም ትእዛዞቼን ይጠብቁ እንደ ሆነ እፈትናቸዋለሁ። 5በስድስተኛው ቀን በሌሎቹ ዕለታት ከሚሰበስቡት ዕጥፍ ሰብስበው ያዘጋጁ።”

6ስለዚህ ሙሴና አሮን ለእስራኤላውያን ሁሉ፣ እንዲህ አሉ፤ “ከግብፅ ምድር ያወጣችሁ እግዚአብሔር (ያህዌ) መሆኑን በዛሬዪቱ ምሽት ታውቃላችሁ። 7በእርሱ ላይ ያሰማችሁትን ማጕረምረም ሰምቷልና በማለዳ እግዚአብሔርን (ያህዌ) ክብር ታያላችሁ፤ ለመሆኑ በእኛስ ላይ የምታጕረመርሙት እኛ ምንድን ነንና ነው?” አሏቸው። 8ሙሴም ንግግሩን በመቀጠል፣ “በእርሱ ላይ ማጕረምረማችሁን ሰምቷልና በምሽት የምትበሉትን ሥጋ፣ በማለዳም የምትፈልጉትን ያህል እንጀራ በሚሰጣችሁ ጊዜ እግዚአብሔር (ያህዌ) መሆኑን ታውቃላችሁ፤ እኛ ማን ነን? በእኛ ላይ አይደለም ያጕረመረማችሁት፤ በእግዚአብሔር (ያህዌ) ላይ ነው እንጂ” አላቸው።

9ከዚያም ሙሴ አሮንን፣ “ ‘ማጕረምረማችሁን እርሱ ሰምቷልና ወደ እግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት ቅረቡ’ ብለህ ለመላው የእስራኤል ማኅበር ተናገር” አለው።

10አሮንም ለመላው የእስራኤል ማኅበር ሲናገር ሳለ ወደ ምድረ በዳው ተመለከቱ፤ በዚያም የእግዚአብሔር (ያህዌ) ክብር በደመናው ላይ ተገልጦ ይታይ ነበር።

11እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን እንዲህ አለው፤ 12“የእስራኤላውያንን ማጕረምረም ሰምቻለሁ፤ ይህን ንገራቸው፤ ‘ፀሓይ ከመጥለቋ በፊት ሥጋ ትበላላችሁ፤ ሲነጋም እንጀራ ትበላላችሁ፤ ከዚያም እኔ እግዚአብሔር አምላካችሁ (ያህዌ ኤሎሂም) መሆኔን ታውቃላችሁ።’ ”

13በዚያች ምሽት ድርጭቶች መጥተው ሰፈሩን አለበሱት፤ በነጋውም በሰፈሩ ዙሪያ ጤዛ ተኝቶበት ነበር። 14ጤዛው ከረገፈ በኋላ በሜዳው ላይ ስስ የሆነ ዐመዳይ የሚመስል የተጋገረ ነገር በምድረ በዳው ላይ ታየ። 15እስራኤላውያንም ይህን ባዩ ጊዜ ምን እንደ ሆነ ባለማወቃቸው እርስ በርሳቸው፣ “ይህ ነገር ምንድን ነው?” ተባባሉ።

ሙሴም፣ “ይህ ትበሉት ዘንድ እግዚአብሔር (ያህዌ) የሰጣችሁ እንጀራ ነው አላቸው። 16እግዚአብሔር (ያህዌ) ያዘዘው ይህ ነው፤ ‘እያንዳንዱ የሚያስፈልገውን ያህል ይሰብስብ፤ በድንኳናችሁ ባለው ሰው ልክ ለእያንዳንዱ አንድ ጎሞር16፥16 ይህ በቍጥር 18፡32፡33 እንዲሁም 36 ላይ ተጠቅሷል፤ ወደ ሁለት ሊትር ያህል ይሆናል። ውሰዱ’ ” ብሎ እግዚአብሔር (ያህዌ) አዝዟል።

17እስራኤላውያንም እንደ ተነገራቸው አደረጉ፤ አንዳንዶች አብዝተው፣ አንዳንዶች ደግሞ አሳንሰው ሰበሰቡ። 18የሰበሰቡትን በጎሞር በሰፈሩ ጊዜ ብዙ የሰበሰበው አልተረፈውም፤ ጥቂት የሰበሰበውም አልጐደለበትም፤ እያንዳንዱ የሰበሰበው የሚያስፈልገውን ያህል ሆነ።

19ሙሴም፣ “ማንም ከዚህ ለነገ ምንም ማስተረፍ የለበትም” አላቸው።

20ሆኖም ግን አንዳንዶቹ ሙሴ የተናገረውን ቸል በማለት ከሰበሰቡት ውስጥ ከፊሉን አስተርፈው አሳደሩ፤ በማግስቱም ጧት ተልቶ መሽተት ጀመረ፤ ስለዚህ ሙሴ ተቈጣቸው።

21በየማለዳው እያንዳንዱ የሚያስፈልገውን ያህል ሰበሰበ፤ ፀሓዩ እየበረታ በሄደም ጊዜ ቀለጠ። 22በስድስተኛው ቀን ለእያንዳንዱ ሰው ሁለት ሁለት ጎሞር16፥22 ምናልባት ወደ 4.5 ሊትር ሊደርስ ይችላል። አድርገው ዕጥፍ ሰበሰቡ፤ የማኅበሩም አለቆች ወደ ሙሴ መጥተው ይህንኑ ነገሩት። 23እርሱም አላቸው፤ “እግዚአብሔር (ያህዌ) ያዘዘው ይህ ነው፤ ‘ነገ ለእግዚአብሔር (ያህዌ) የተቀደሰ ሰንበት በመሆን፣ የዕረፍት ቀን ይሆናል።’ ስለዚህ መጋገር የምትፈልጉትን ጋግሩ፤ መቀቀል የምትፈልጉትን ቀቅሉ። የተረፈውን አስቀምጡ፤ እስከ ጧትም ድረስ አቈዩት።”

24ስለዚህ ሙሴ እንዳዘዘው እስከ ጧት ድረስ አቈዩት፤ አልሸተተም፤ ወይም አልተላም። 25ሙሴም እንዲህ አለ፤ “ዛሬውኑ ብሉት፤ ዛሬ የእግዚአብሔር (ያህዌ) ሰንበት ነውና። ዛሬ በመሬት ላይ ምንም አታገኙም። 26ስድስት ቀን ትሰበስቡታላችሁ፤ በሰባተኛው ቀን በሰንበት ዕለት ግን ምንም ነገር አይኖርም።”

27ሆኖም አንዳንዶቹ በሰባተኛው ቀን ለመሰብሰብ ወጡ፤ ነገር ግን ምንም አላገኙም። 28ከዚያም እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን አለው፤ “ትእዛዞቼንና መመሪያዎቼን ለመፈጸም እስከ መቼ እንቢ ትላላችሁ?16፥28 ዕብራይስጡ የብዙ ቍጥር ያሳያል። 29እግዚአብሔር (ያህዌ) ሰንበትን የሰጣችሁ መሆኑን ልብ በሉ፤ በስድስተኛው ቀን ለሁለት ቀን የሚሆን እንጀራ የሰጣችሁ ለዚህ ነው። በሰባተኛው ቀን እያንዳንዱ ሰው ባለበት ይቈይ፤ ማንም አይወጣም።” 30ስለዚህ ሕዝቡም በሰባተኛው ቀን ዐረፉ።

31የእስራኤልም ሕዝብ ምግቡን መና አሉት16፥31 መና ማለት፣ ምንድን ነው? ማለት ነው (15 ይመ)፤ እርሱም እንደ ድንብላል ዘር ነጭ፣ ጣሙም ከማር እንደ ተጋገረ ቂጣ ነበር። 32ሙሴም አለ፤ “እግዚአብሔር (ያህዌ) ያዘዘን ይህ ነው፤ ‘ከግብፅ ባወጣኋችሁ ጊዜ በምድረ በዳ እንድትበሉ የሰጠኋችሁን እንጀራ ያዩ ዘንድ አንድ ጎሞር መና ወስደህ ለሚመጡት ትውልዶች አቈየው።’ ”

33ስለዚህ ሙሴ አሮንን፣ “አንድ ማሰሮ ወስደህ አንድ ጎሞር መና አስቀምጥበት፤ ለሚመጡት ትውልዶች እንዲቈይም እግዚአብሔር (ያህዌ) ፊት አስቀምጠው” አለው።

34እግዚአብሔር (ያህዌ) ሙሴን እንዳዘዘው አሮን፣ መናው ይጠበቅ ዘንድ በምስክሩ ፊት አስቀመጠው። 35እስራኤላውያን ወደ መኖሪያቸው ምድር እስኪመጡ ድረስ ለአርባ ዓመት መና በሉ፤ ወደ ከነዓን ድንበር እስከሚደርሱ ድረስ መና በሉ።

36አንድ ጎሞር የኢፍ መስፈሪያ አንድ ዐሥረኛ ነው።

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 16:1-36

Oúnjẹ láti ọ̀run

1Ìjọ àwọn ọmọ Israẹli mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Elimu, wọ́n dé sí ijù Sini tí ó wà láàrín Elimu àti Sinai, ni ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. 2Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. 316.3: Ek 14.12; 17.3.Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”

416.4,13: Jh 6.31.Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi. 5Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

6Mose àti Aaroni sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá. 7Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?” 8Mose tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ́ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkùn ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”

9Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”

10Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọsánmọ̀.

11Olúwa sọ fún Mose pé, 12“Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

13Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká. 14Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsi i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀. 1516.15: 1Kọ 10.3.Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i ṣe.

Mose sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ. 16Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ: ‘Kí olúkúlùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùwọ̀n omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”

17Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí a ti sọ fún wọn; àwọn kan kó púpọ̀, àwọn kan kó kékeré. 1816.18: 2Kọ 8.15.Nígbà tí wọ́n fi òṣùwọ̀n omeri wọ̀n-ọ́n, ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù. Ẹnìkọ̀ọ̀kan kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un.

19Mose sì wí fún wọ́n pé, “Kí ẹnikẹ́ni ó má ṣe kó pamọ́ lára rẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì.”

20Ṣùgbọ́n, àwọn kan nínú wọn kò fetí sí Mose; Wọ́n kó lára rẹ̀ pamọ́ di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ohun ti wọ́n kó pamọ́ kún fún ìdin, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rùn. Nítorí náà Mose bínú sí wọn.

21Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí oòrùn bá sì mú, a sì yọ́. 22Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùwọ̀n omeri méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mose. 2316.23: Ek 20.8-11.Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

24Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mose ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin. 25Mose sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní. 26Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”

27Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó. 28Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́? 29Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni oúnjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọ̀ọ̀kan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.” 30Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

3116.31: Nu 11.7,8.Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe. 32Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùwọ̀n omeri manna kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Ejibiti.’ ”

33Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó manna tí ó kún òṣùwọ̀n omeri kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”

34Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, Aaroni gbé manna sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́. 35Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani.

36(Òṣùwọ̀n omeri kan sì jẹ́ ìdákan nínú ìdámẹ́wàá efa.)