호세아 10 – KLB & YCB

Korean Living Bible

호세아 10:1-15

1이스라엘 백성은 무성한 포도나무와 같아서 열매를 많이 맺는다. 열매 가 많을수록 그들은 제단을 많이 만들고 그 땅이 아름다울수록 그들은 돌기둥의 우상을 아름답게 꾸민다.

2그들의 마음이 거짓되므로 그들은 자기들의 죄에 대한 대가를 받아야 한다. 하나님이 그 제단을 헐고 그 돌기둥의 우상을 깨뜨려 버릴 것이다.

3그때 그들이 이렇게 말할 것이다. “우리가 여호와를 두려워하지 않았으므로 우리에게는 왕이 없다. 그러나 우리에게 왕이 있다고 해도 그가 우리를 위해서 무엇을 할 수 있겠는가?”

4그들이 헛된 말을 하고 지키지도 않을 약속으로 계약을 맺으니 소송 문제가 밭 이랑의 독초처럼 야기되고 있다.

5사마리아에 사는 사람들이 10:5 또는 ‘벧-아웬’벧엘의 송아지 우상 때문에 두려워할 것이다. 그 백성이 슬퍼할 것이며 그 우상을 섬기던 제사장들도 슬퍼할 것이다. 이것은 사마리아의 영광이 떠났기 때문이다.

6그 송아지는 앗시리아로 옮겨져서 앗시리아 왕에게 선물로 바쳐질 것이다. 에브라임은 수치를 당하고 이스라엘은 그 10:6 또는 ‘자기들의 계의를’우상을 부끄러워할 것이며

7사마리아와 그 왕은 물거품처럼 사라질 것이다.

8이스라엘 백성이 우상을 섬기는 10:8 히 ‘아웬의’악의 산당은 파괴되고 가시와 엉겅퀴가 자라 그 제단을 덮을 것이니 그들이 높은 산을 향하여 “우리를 가려라” 할 것이며 낮은 산을 향하여 “우리 위에 무너져라” 할 것이다.

9여호와께서 말씀하신다. “이스라엘아, 너는 기브아 시대부터 지금까지 계속 범죄하고 있다. 기브아에서 악을 행하는 자들에게 전쟁이 들이닥치지 않았느냐?

10내가 원하는 때에 너를 벌하겠다. 많은 민족이 모여서 너를 칠 것이다. 네가 범한 숱한 죄에 대하여 너는 벌을 받을 것이다.

11이스라엘은 길들인 송아지와 같아서 곡식 밟기를 좋아하지만 내가 그 아름다운 목에 멍에를 메우고 보다 고되게 부려먹을 것이니 유다는 쟁기질을 하고 이스라엘은 써레질을 할 것이다.

12“너희는 자신을 위해 의의 씨를 심고 사랑의 열매를 거두어라. 너희 마음의 묵은 땅을 갈아라. 지금은 나 여호와를 찾을 때이다. 언젠가는 내가 10:12 또는 ‘의를 비처럼 너희에게 내리시리라’너희에게 구원의 복을 쏟아 부어 주겠다.

13너희는 악을 심어 악을 수확하고 거짓말의 열매를 먹었다. 너희가 너희 힘과 많은 병력을 의지하였으므로

14너희 백성 가운데 내란이 일어나 너희 요새들이 파괴될 것이니 살만왕이 전쟁에서 벧 – 아벨을 파괴하던 때처럼 될 것이다. 그때 어머니와 자식이 함께 던져져 죽음을 당하였다.

15너희 악이 크므로 너희도 벧엘에서 이런 일을 당할 것이며 10:15 또는 ‘새벽에’전쟁이 시작되는 즉시 이스라엘 왕이 죽음을 당할 것이다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Hosea 10:1-15

1Israẹli jẹ́ igi àjàrà tó gbilẹ̀

ó ń so èso fún ara rẹ̀

Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀

bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i

bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere

o bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.

2Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ

báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn.

Olúwa yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀

yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.

3Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba

nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún Olúwa

ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba,

kí ni yóò ṣe fún wa?”

4Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀,

wọ́n ṣe ìbúra èké,

wọ́n da májẹ̀mú;

báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko,

bi i koríko májèlé láàrín oko tí a ro.

5Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samaria bẹ̀rù

nítorí ère abo màlúù tó wà ní Beti-Afeni

Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí

bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀

Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀,

nítorí tí a ti mú lọ sí ìgbèkùn.

6A ó gbé lọ sí Asiria

gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá

a ó dójútì Efraimu;

ojú yóò ti Israẹli nítorí ìgbìmọ̀ rẹ̀

7Bí igi tó léfòó lórí omi ni

Samaria àti àwọn ọba rẹ yóò sàn lọ.

810.8: Lk 23.30; If 6.16.Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà búburú ni a o parun—

èyí ni ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli.

Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,

yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.

Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”

àti fún àwọn òkè kéékèèkéé pé, “Ṣubú lù wá!”

9“Láti ìgbà Gibeah, ni ó ti ṣẹ̀, ìwọ Israẹli

ìwọ sì tún wà níbẹ̀.

Ǹjẹ́ ogun kò lé

ẹ̀yin aṣebi ni Gibeah bá bí?

10Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;

orílẹ̀-èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojúkọ wọn

Láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11Efraimu jẹ́ ọmọ abo màlúù tí a tí kọ́,

to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà;

lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni

èmi ó dí ẹrù wúwo lé.

Èmi yóò mú kí a gun Efraimu bí ẹṣin

Juda yóò tú ilẹ̀,

Jakọbu yóò sì fọ́ ògúlùtu rẹ̀.

1210.12: 2Kọ 9.10.Ẹ gbin òdòdó fún ara yín,

kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin,

Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro,

nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,

títí tí yóò fi dé,

tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

13Ṣùgbọ́n ẹ tí gbin búburú ẹ si ka ibi,

Ẹ ti jẹ èso èké

nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀lé agbára yín

àti àwọn ọ̀pọ̀ jagunjagun yín

14Ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín

kí gbogbo odi agbára yín ba le parun.

Gẹ́gẹ́ bí Ṣalmani ṣe pa Beti-Arbeli run lọ́jọ́ ogun,

nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn

15Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Beteli,

nítorí pé ìwà búburú yín ti pọ̀jù.

Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà,

a o pa ọba Israẹli run pátápátá.