예레미야 24 – KLB & YCB

Korean Living Bible

예레미야 24:1-10

무화과 두 광주리

1바빌로니아의 느부갓네살왕이 유다 왕 여호야김의 아들인 24:1 또는 ‘여고냐’여호야 긴과 유다의 대신들과 목공들과 철공들을 예루살렘에서 포로로 잡아 바빌로니아로 끌고 간 후에 여호와께서 성전 앞에 무화과 두 광주리가 놓인 것을 나에게 보여 주셨다.

2그런데 한 광주리에는 이제 막 익은 좋은 무화과가 담겨 있었고 다른 한 광주리에는 썩어서 먹을 수 없는 무화과가 담겨 있었다.

3그때 여호와께서 “예레미야야, 네가 무엇을 보느냐?” 하고 물으셨다. 그래서 나는 “무화과입니다. 좋은 것은 아주 좋고 나쁜 것은 아주 나빠 먹을 수가 없을 정도입니다” 하고 대답하였다.

4그러자 여호와께서 나에게 말씀하셨다.

5“이스라엘의 하나님 나 여호와가 말한다. 내가 이 곳에서 24:5 원문에는 ‘갈대아인의 땅에’바빌로니아로 보낸 유다의 포로들을 이 좋은 무화과처럼 좋게 여기겠다.

6내가 그들을 보살피고 지키며 다시 그들을 이 땅으로 인도하여 그들을 세우고 헐지 않을 것이며 그들을 심고 뽑지 않을 것이다.

7그리고 내가 여호와임을 아는 마음을 그들에게 주겠다. 그들은 내 백성이 되고 나는 그들의 하나님이 될 것이다. 이것은 그들이 전심으로 나에게 돌아올 것이기 때문이다.

8“그러나 내가 유다의 시드기야왕과 그의 신하들과 그리고 이 땅에 살아 남아 있거나 이집트에 가서 사는 예루살렘 사람들을 썩어서 먹을 수 없는 이 무화과처럼 취급하여

924:9 또는 ‘세상 모든 나라 중에 흩어서’그들이 온 세계의 반감을 사게 하고 내가 그들을 추방하는 곳마다 그들이 수치와 모욕을 당하게 하며 비웃음과 조롱거리가 되게 하고 저주를 받게 하겠다.

10그리고 전쟁과 기근과 무서운 전염병을 보내 내가 그들과 그 조상들에게 준 땅에서 그들이 전멸할 때까지 그들을 칠 것이다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 24:1-10

Agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì

1Lẹ́yìn tí Nebukadnessari ọba Babeli ti kó Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli tán. Olúwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ Olúwa. 2Agbọ̀n kan ni èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó dára bí èyí tí ó tètè pọ́n; èkejì sì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú rékọjá tí kò sì le è ṣe é jẹ.

3Nígbà náà ni Olúwa bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremiah?”

Mo dáhùn pe “Èso ọ̀pọ̀tọ́” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dáradára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”

4Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 5“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjèjì láti Juda sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea 6Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere; Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu. 7Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

8“ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti. 9Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí. 10Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’ ”