여호수아 20 – KLB & YCB

Korean Living Bible

여호수아 20:1-9

도피성

1여호와께서는 여호수아를 통해

2이스라엘 백성에게 이렇게 말씀

3과실로 사람을 죽인 자가 그리로 도망가서 피신하게 하라. 이 곳은 복수하려는 사람을 피하는 곳이다.

4도피성으로 도망하는 자는 그 성문 입구에 서서 그 성의 지도자들에게 일어난 일을 설명하고 그 지도자들은 그를 받아들여 성 안에 있을 곳을 마련해 주어야 한다.

5만일 복수하려고 찾는 자가 그 곳까지 따라와도 성의 지도자들은 그를 내주어서는 안 된다. 그는 본래 사람을 미워해서 죽인 것이 아니라 과실로 죽였기 때문에 보호를 받을 필요가 있다.

6살인자는 공개 재판을 받거나 사건 발생 당시의 대제사장이 죽기까지 그 성에 머물러 있다가 그 후에 자기 집으로 돌아가야 한다.”

7그래서 백성들은 도피성으로 납달리 산간 지대에 있는 갈릴리의 게데스와 에브라임 산간 지대의 세겜과 헤브론으로 알려진 유다 산간 지대의 기럇 – 아르바를 선정하고

8또 여리고 맞은편 요단강 동쪽에서는 르우벤 지파의 광야 평원에 있는 베셀과 갓 지파의 땅에 있는 길르앗의 라못과 므낫세 지파의 땅에 있는 바산의 골란을 선정하였다.

9이 모든 도피성은 이스라엘 백성뿐만 아니라 그들 가운데 사는 외국인도 과실로 사람을 죽였을 경우 그리로 도망가서 보복을 피해 공개 재판을 받을 때까지 피신할 수 있도록 마련된 곳이다.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 20:1-9

Àwọn ìlú ààbò

1Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, 220.2-9: Nu 35.6-34; De 4.41-43; 19.1-13.“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mose, 3kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa. 4Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn. 5Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ láìmọ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. 6Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.”

7Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda. 8Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase. 9Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé ní àárín wọn tí ó ṣèèṣì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.