민수기 10 – KLB & YCB

Korean Living Bible

민수기 10:1-36

두 개의 은나팔

1여호와께서 모세에게 말씀하셨다.

2“너는 은을 두들겨 나팔 두 개를 만 들고 그것을 불어 백성을 소집하며 행진하게 하여라.

3나팔 둘을 길게 불면 모든 백성이 성막 입구 네 앞에 모이게 하고

4나팔을 하나만 불면 10:4 또는 ‘천부장된 족장들’각 집안의 대표자들만 모이게 하라.

5나팔을 짧게 불면 동쪽에 진을 친 지파들이 행진하고

6다시 짧게 불면 남쪽에 진을 친 지파들이 행진하게 하여라. 이와 같이 행진 신호는 나팔을 짧게 불고

7소집 신호는 길게 불도록 하라.

8나팔은 아론의 자손인 제사장들만 불어야 한다. 이것은 너희가 대대로 지켜야 할 규정이다.

9“너희가 약속의 땅에 도착하여 너희를 대적하는 원수들과 싸우러 나갈 때 이 나팔을 불어라. 그러면 너희 하나님 나 여호와가 너희를 기억하고 너희를 원수들에게서 구원해 주겠다.

10또 기쁜 날과 명절과 매월 초하루에 번제물과 화목제물을 드릴 때에도 나팔을 불어라. 그러면 내가 너희를 기억할 것이다. 나는 너희 하나님 여호와이다.”

시내산을 떠나는 이스라엘 백성

11이스라엘 백성이 이집트를 떠나온 지 2년째가 되는 해 2월 20일에 구름이 성막에서 떠오르자

12그들은 시나이 광야에서 출발하여 그 구름이 바란 광야에 멈출 때까지 구름을 따라 행진하였다.

13이것은 여호와께서 모세에게 행진 명령을 내린 후 첫번째 행진이었는데

14이 행렬 선두에는 유다 지파 진영에 속한 자들이 기를 앞세우고 암미나답의 아들 나손이 인솔하는 유다 지파와

15수알의 아들 느다넬이 인솔하는 잇사갈 지파와

16헬론의 아들 엘리압이 인솔하는 스불론 지파가 순서대로 행진하였다.

17그러고 나서 성막이 걷혀지고 게르손 자손과 므라리 자손이 성막을 메고 그 뒤를 따라 출발하였다.

18그 뒤에는 르우벤 지파 진영에 속한 자들이 기를 앞세우고 스데울의 아들 엘리술이 인솔하는 르우벤 지파와

19수리삿대의 아들 슬루미엘이 인솔하는 시므온 지파와

20드우엘의 아들 엘리아삽이 인솔하는 갓 지파가 순서대로 행진하였다.

21그 뒤에는 고핫 자손이 성막의 거룩한 기구들을 메고 행진하였으며 이들이 다음 진영에 도착하기 전에 성막이 세워졌다.

22그 다음은 에브라임 지파 진영에 속한 자들이 기를 앞세우고 암미훗의 아들 엘리사마가 인솔하는 에브라임 지파와

23브다술의 아들 가말리엘이 인솔하는 므낫세 지파와

24기드오니의 아들 아비단이 인솔하는 베냐민 지파가 순서대로 행진하였다.

25그리고 제일 뒤에는 단 지파 진영에 속한 자들이 기를 앞세우고 암미삿대의 아들 아히에셀이 인솔하는 단 지파와

26오그란의 아들 바기엘이 인솔하는 아셀 지파와

27에난의 아들 아히라가 인솔하는 납달리 지파가 순서대로 행진하였다.

28이상은 이스라엘 각 지파가 진영별로 행진한 대열의 순서이다.

29어느 날 모세는 미디안 사람 이드로의 아들인 그의 처남 호밥에게 말하였다. “지금 우리는 약속의 땅으로 가고 있으니 처남도 함께 가세. 우리가 자네를 잘 돌봐 주겠네. 여호와께서는 이스라엘 백성에게 복을 주시겠다고 약속하셨다네.”

30“아니오, 가지 않겠습니다. 나는 10:30 또는 ‘내 고향 내 친척에게로’친척들이 있는 고향으로 돌아가야 합니다.”

31“그러지 말고 함께 가세. 처남은 이 광야 길을 잘 알고 있으니 우리의 좋은 안내자가 될 걸세.

32만일 처남이 우리와 함께 가면 여호와께서 우리에게 주시는 모든 좋은 것을 처남도 함께 누리게 될 것이네.”

33이스라엘 백성은 시내산을 떠나 3일 동안 행진하면서 법궤를 앞세우고 진 칠 곳을 찾았는데

34그들이 행진할 때 낮에는 여호와의 구름이 그들 위에 있었다.

35모세는 법궤가 떠날 때마다 “여호와여, 일어나셔서 주의 원수들을 흩으시고 주를 미워하는 자들이 주 앞에서 도망하게 하소서” 하고 외쳤으며

36법궤가 멈출 때마다 “오! 여호와여, 수백만의 이스라엘 백성에게 돌아오소서” 하였다.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 10:1-36

Fèrè ìpè fàdákà

1Olúwa sọ fún Mose pé: 2Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. 3Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 4Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli yóò péjọ síwájú rẹ. 5Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. 6Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ ààmì fún gbígbéra. 7Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀.

8“Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. 9Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”

Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Sinai

11Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí. 12Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani. 13Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

14Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn. 15Netaneli ọmọ Ṣuari ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Isakari; 16Eliabu ọmọ Heloni ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Sebuluni. 17Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.

18Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn. 19Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni. 20Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi. 21Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

22Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn. 23Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase. 24Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.

25Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn. 26Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, 27Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali; 28Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

29Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

30Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

31Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa. 32Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

33Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn. 34Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

3510.35: Sm 68.1,2.Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé,

“Dìde, Olúwa!

Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká,

kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

36Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé;

“Padà, Olúwa,

Sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”