레위기 12 – KLB & YCB

Korean Living Bible

레위기 12:1-8

해산한 여인의 정결 의식

1여호와께서 모세를 통하여 이스라엘 백성에게 이렇게 말씀하셨다.

2“여자가 임신하여 아들을 낳으면 산모는 7일 동안 부정할 것이다. 이것은 생리 기간 중의 부정과 마찬가지이다.

3생후 8일째가 되면 그 아이의 포피를 잘라 할례를 베풀어야 한다.

4해산한 여인은 그때부터 33일을 지나야 그 피의 부정에서 깨끗해질 것이다. 그 동안에는 거룩한 물건을 만져서도 안 되며 성소에 들어가서도 안 된다.

5“만일 여자가 임신하여 딸을 낳았을 경우에는 2주일 동안 부정할 것이다. 이것은 생리 기간 중의 부정과 마찬가지이다. 그리고 그 산모는 66일을 더 지나야 그 피의 부정에서 깨끗하게 될 것이다.

6“여자가 아들을 낳았든지 딸을 낳았든지 그 부정한 기간이 지나면 그 여인은 번제물로 일 년 된 어린 양 한 마리와, 속죄제물로 집비둘기 새끼나 산비둘기 한 마리를 마련하여 제사장에게 가져갈 것이며

7제사장은 그 제물을 나 여호와 앞에 바쳐 그 여인을 위해 속죄해야 한다. 그러면 그 여인의 부정이 의식상 완전히 깨끗해질 것이다. 이것은 해산한 여자에 관한 규정이다.

8“만일 그 여인이 너무 가난하여 어린 양을 제물로 드릴 형편이 못 되면 산비둘기 두 마리나 집비둘기 새끼 두 마리를 제사장에게 가지고 가서 하나는 번제물로, 하나는 속죄제물로 주도록 하여라. 제사장이 그 여인을 위해 속죄하면 그녀가 의식상 깨끗해질 것이다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 12:1-8

Ìwẹ̀nùmọ́ lẹ́yìn ìbímọ

112.1-8: Lk 2.22-24.Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákokò nǹkan oṣù rẹ̀. 312.3: Gẹ 17.12; Lk 2.21.Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà. 4Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá. 5Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìn-dínláàdọ́rin (66) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

6“ ‘Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá kọjá kí ó mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí àdàbà kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 7Ó gbọdọ̀ fi wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa láti ṣe ètùtù fún obìnrin náà lẹ́yìn náà ni yóò di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

“ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún obìnrin tí ó bá bí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin. 812.8: Lk 2.24.Bí kò bá lágbára àti fi àgùntàn ṣe é, ó gbọdọ̀ le mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún un. Òun yóò sì di mímọ́.’ ”