John 7 – KJV & YCB

King James Version

John 7:1-53

1After these things Jesus walked in Galilee: for he would not walk in Jewry, because the Jews sought to kill him. 2Now the Jews’ feast of tabernacles was at hand. 3His brethren therefore said unto him, Depart hence, and go into Judæa, that thy disciples also may see the works that thou doest. 4For there is no man that doeth any thing in secret, and he himself seeketh to be known openly. If thou do these things, shew thyself to the world. 5For neither did his brethren believe in him. 6Then Jesus said unto them, My time is not yet come: but your time is alway ready. 7The world cannot hate you; but me it hateth, because I testify of it, that the works thereof are evil. 8Go ye up unto this feast: I go not up yet unto this feast; for my time is not yet full come. 9When he had said these words unto them, he abode still in Galilee.

10¶ But when his brethren were gone up, then went he also up unto the feast, not openly, but as it were in secret. 11Then the Jews sought him at the feast, and said, Where is he? 12And there was much murmuring among the people concerning him: for some said, He is a good man: others said, Nay; but he deceiveth the people. 13Howbeit no man spake openly of him for fear of the Jews.

14¶ Now about the midst of the feast Jesus went up into the temple, and taught. 15And the Jews marvelled, saying, How knoweth this man letters, having never learned? 16Jesus answered them, and said, My doctrine is not mine, but his that sent me. 17If any man will do his will, he shall know of the doctrine, whether it be of God, or whether I speak of myself. 18He that speaketh of himself seeketh his own glory: but he that seeketh his glory that sent him, the same is true, and no unrighteousness is in him. 19Did not Moses give you the law, and yet none of you keepeth the law? Why go ye about to kill me? 20The people answered and said, Thou hast a devil: who goeth about to kill thee? 21Jesus answered and said unto them, I have done one work, and ye all marvel. 22Moses therefore gave unto you circumcision; (not because it is of Moses, but of the fathers;) and ye on the sabbath day circumcise a man. 23If a man on the sabbath day receive circumcision, that the law of Moses should not be broken; are ye angry at me, because I have made a man every whit whole on the sabbath day? 24Judge not according to the appearance, but judge righteous judgment. 25Then said some of them of Jerusalem, Is not this he, whom they seek to kill? 26But, lo, he speaketh boldly, and they say nothing unto him. Do the rulers know indeed that this is the very Christ? 27Howbeit we know this man whence he is: but when Christ cometh, no man knoweth whence he is. 28Then cried Jesus in the temple as he taught, saying, Ye both know me, and ye know whence I am: and I am not come of myself, but he that sent me is true, whom ye know not. 29But I know him: for I am from him, and he hath sent me. 30Then they sought to take him: but no man laid hands on him, because his hour was not yet come. 31And many of the people believed on him, and said, When Christ cometh, will he do more miracles than these which this man hath done?

32¶ The Pharisees heard that the people murmured such things concerning him; and the Pharisees and the chief priests sent officers to take him. 33Then said Jesus unto them, Yet a little while am I with you, and then I go unto him that sent me. 34Ye shall seek me, and shall not find me: and where I am, thither ye cannot come. 35Then said the Jews among themselves, Whither will he go, that we shall not find him? will he go unto the dispersed among the Gentiles, and teach the Gentiles? 36What manner of saying is this that he said, Ye shall seek me, and shall not find me: and where I am, thither ye cannot come? 37In the last day, that great day of the feast, Jesus stood and cried, saying, If any man thirst, let him come unto me, and drink. 38He that believeth on me, as the scripture hath said, out of his belly shall flow rivers of living water. 39(But this spake he of the Spirit, which they that believe on him should receive: for the Holy Ghost was not yet given; because that Jesus was not yet glorified.)

40¶ Many of the people therefore, when they heard this saying, said, Of a truth this is the Prophet. 41Others said, This is the Christ. But some said, Shall Christ come out of Galilee? 42Hath not the scripture said, That Christ cometh of the seed of David, and out of the town of Bethlehem, where David was? 43So there was a division among the people because of him. 44And some of them would have taken him; but no man laid hands on him.

45¶ Then came the officers to the chief priests and Pharisees; and they said unto them, Why have ye not brought him? 46The officers answered, Never man spake like this man. 47Then answered them the Pharisees, Are ye also deceived? 48Have any of the rulers or of the Pharisees believed on him? 49But this people who knoweth not the law are cursed. 50Nicodemus saith unto them, (he that came to Jesus by night, being one of them,) 51Doth our law judge any man, before it hear him, and know what he doeth? 52They answered and said unto him, Art thou also of Galilee? Search, and look: for out of Galilee ariseth no prophet. 53And every man went unto his own house.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 7:1-53

Jesu lọ sí àjọ ìpàgọ́

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. 27.2: Le 23.34; De 16.16.Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. 37.3: Mk 3.21,31; Mt 12.46.Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. 4Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” 5Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.

67.6: Mt 26.18; Jh 2.4; 7.30.Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. 77.7: Jh 15.18-21.Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. 8Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” 9Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.

10Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ tan, nígbà náà ni òun sì gòkè lọ sí àjọ náà pẹ̀lú, kì í ṣe ní gbangba, ṣùgbọ́n bí ẹni pé níkọ̀kọ̀. 11Nígbà náà ni àwọn Júù sì ń wá a kiri nígbà àjọ wí pé, “Níbo ni ó wà?”

127.12: Jh 7.40-43.Ìkùnsínú púpọ̀ sì wà láàrín àwọn ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀: nítorí àwọn kan wí pé, “Ènìyàn rere ní í ṣe.”

Àwọn mìíràn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n òun ń tan ènìyàn jẹ ni.” 137.13: Jh 19.38; 20.19.Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní gbangba nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù.

Jesu kọ́ àwọn ènìyàn

14Nígbà tí àjọ dé àárín; Jesu gòkè lọ sí tẹmpili ó sì ń kọ́ni. 15Ẹnu sì ya àwọn Júù, wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ti ṣe mọ ìwé, nígbà tí kò kọ́ ẹ̀kọ́?”

16Jesu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀kọ́ mi kì í ṣe tèmi, bí kò ṣe ti ẹni tí ó rán mi. 17Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò mọ̀ ní ti ẹ̀kọ́ náà, bí ìbá ṣe ti Ọlọ́run, tàbí bí èmi bá sọ ti ara mi. 18Ẹni tí ń sọ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ara rẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, òun ni olóòtítọ́, kò sì sí àìṣòdodo nínú rẹ̀. 197.19: Jh 1.17.Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”

207.20: Jh 8.48; 10.20; Mt 11.18; Mk 3.22.Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”

217.21: Jh 5.2-9.Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. 227.22: Le 12.3; Gẹ 17.10; 21.4.Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 237.23: Mk 3.5; Lk 13.12; 14.4.Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 247.24: Jh 8.15; Isa 11.3; Sk 7.9.Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”

Ṣé Jesu ni Kristi?

25Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn ará Jerusalẹmu wí pé, “ẹni tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa kọ́ yìí? 26Sì wò ó, ó ń sọ̀rọ̀ ní gbangba, wọn kò sì wí nǹkan kan sí i. Àwọn olórí ha mọ̀ nítòótọ́ pé, èyí ni Kristi náà? 277.27: Jh 6.42; 7.41; 9.29.Ṣùgbọ́n àwa mọ ibi tí ọkùnrin yí gbé ti wá: ṣùgbọ́n nígbà tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tí yóò mọ ibi tí ó gbé ti wá.”

287.28: Jh 8.42.Nígbà náà ni Jesu kígbe ní tẹmpili bí ó ti ń kọ́ni, wí pé, “Ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá: èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀. 297.29: Jh 8.55; 17.25; Mt 11.27.Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni mo ti wá, òun ni ó rán mi.”

307.30: Jh 7.44; 10.39; Mk 12.12; Jh 8.20.Nítorí náà wọ́n ń wá ọ̀nà à ti mú un: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e, nítorí tí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé. 317.31: Jh 8.30; 10.42; 11.45.Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbà á gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kristi náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ ààmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

337.33: Jh 8.21; 12.35; 13.33; 14.19; 16.16-19.Nítorí náà Jesu wí fún wọn pé, “Níwọ́n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi. 34Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

357.35: Jk 1.1; 1Pt 1.1; Jh 12.20; Ap 11.20.Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárín àwọn Helleni tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Helleni bí. 36Ọ̀rọ̀ kín ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

377.37: Le 23.36; Jh 4.10,14.Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu. 387.38: Isa 44.3; 55.1; 58.11.Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.” 397.39: Jh 20.22; 12.23.(Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fún ni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jesu lógo.)

407.40: Jh 1.21; Mt 21.11.Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”

41Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.”

Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? 427.42: Mt 5.2; Mt 1.1; Lk 2.4.Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” 43Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. 447.44: Jh 7.30; 10.39.Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

Àìgbàgbọ́ àwọn adarí Júù

45Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

467.46: Mt 7.28.Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

47Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? 48Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? 49Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

507.50: Jh 3.1; 19.39.Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, 51“Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

527.52: 2Ọb 14.25.Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”

53Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.