歴代誌Ⅰ 7 – JCB & YCB

Japanese Contemporary Bible

歴代誌Ⅰ 7:1-40

7

イッサカルの子孫

1イッサカルの子はトラ、プア、ヤシュブ、シムロン。

2トラの子は次のとおりで、みな氏族の長となりました。ウジ、レファヤ、エリエル、ヤフマイ、イブサム、シェムエル。

ダビデ王の時代には、これらの諸氏族出身の勇士は総計二万二千六百人にのぼりました。

3ウジの子はイゼラヘヤ。イゼラヘヤの息子はミカエル、オバデヤ、ヨエル、イシヤなど五人で、みな氏族の長でした。 4彼らはみな数人の妻をめとり、多くの子をもうけたので、その子孫は、ダビデの時代には三万六千の兵力になりました。 5イッサカル族の全氏族から兵役についた者は計八万七千人で、みな系図に載っている勇士でした。

ベミヤミンの子孫

6ベニヤミンの子はベラ、ベケル、エディアエル。

7ベラの子はエツボン、ウジ、ウジエル、エリモテ、イリ。この五人の勇士は各氏族の長で、系図に載っている兵士二万二、〇三四人の指導者でした。

8ベケルの子は次のとおり。ゼミラ、ヨアシュ、エリエゼル、エルヨエナイ、オムリ、エレモテ、アビヤ、アナトテ、アレメテ。

9ダビデの時代には、彼らの子孫から出た勇士は各氏族の長二万二百人に及びました。

10エディアエルの子はビルハン。

ビルハンの子はエウシュ、ベニヤミン、エフデ、ケナアナ、ゼタン、タルシシュ、アヒシャハル。

11彼らはみなエディアエルの諸氏族の長となり、その子孫は、ダビデの時代に一万七千二百人の勇士となりました。

12イルの子はシュピムとフピム。フシムはアヘルの子の一人でした。

ナフタリの子孫

13ヤコブのそばめビルハの子ナフタリの子は、ヤハツィエル、グニ、エツェル、シャルム。

マナセの子孫

14マナセがアラム人のそばめに産ませた子は、アスリエルとギルアデの父のマキル。

15マキルは、フピムとシュピムに妻を見つけてやりました。マキルの妹はマアカ。彼のもう一人の末裔のツェロフハデには娘しかいませんでした。

16マキルの妻もマアカといいましたが、ペレシュという男の子を産みました。その弟はシェレシュで、ウラムとレケムという二人の子がいました。

17ウラムの子はベダン。以上はギルアデの子、マキルの孫、マナセのひ孫です。

18マキルの妹モレケテは、イシュホデ、アビエゼル、マフラを産みました。

19シェミダの子はアフヤン、シェケム、リクヒ、アニアム。

エフライムの子孫

20-21エフライムの子孫は次のとおり。シュテラフ、ベレデ、タハテ、エルアダ、タハテ、ザバデ、シュテラフ、それにエゼルとエルアデ。

エルアデとエゼルは、ガテで家畜を盗もうとして土地の農夫に見つかり、殺されました。 22二人の父エフライムは、長い間喪に服していたので、兄弟たちが彼を慰めました。 23そののち、エフライムの妻は男の子を産みましたが、悲劇のただ中で生まれたその子を、彼はベリア(「災い」の意)と名づけました。

24エフライムの娘シェエラは、下および上のベテ・ホロン、それにウゼン・シェエラを建てました。

25-27エフライムの息子ベリアの家系はレファフ、レシェフ、テラフ、タハン、ラダン、アミフデ、エリシャマ、ヌン、ヨシュアと続きます。

28彼らは、ベテルとその周辺の村々、東方ではナアラン、西方ではゲゼルと周辺の村々、シェケムと周辺の村々、さらにアヤと近郊の町々に住んでいました。

29イスラエルの子ヨセフの子孫のマナセ族は、次の町々と周辺の地域を支配していました。ベテ・シェアン、タナク、メギド、ドル。

アシェルの子孫

30アシェルの子はイムナ、イシュワ、イシュビ、ベリア、姉妹セラフ。

31ベリアの子はヘベル、ビルザイテの父のマルキエル。

32ヘベルの子はヤフレテ、ショメル、ホタム、姉妹シュア。

33ヤフレテの子はパサク、ビムハル、アシュワテ。

34彼の兄弟ショメルの子はアヒ、ロフガ、フバ、アラム。

35彼の兄弟ヘレムの子はツォファフ、イムナ、シェレシュ、アマル。

36-37ツォファフの子はスアハ、ハルネフェル、シュアル、ベリ、イムラ、ベツェル、ホデ、シャマ、シルシャ、イテラン、ベエラ。

38エテルの子はエフネ、ピスパ、アラ。

39ウラの子はアラフ、ハニエル、リツヤ。

40これらアシェルの子孫はみな各氏族の長で、えり抜きの勇士でした。アシェルの子孫のうち、軍人で系図に載せられた者は二万六千人でした。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 7:1-40

Isakari

1Àwọn ọmọ Isakari:

Tola, Pua, Jaṣubu àti Ṣimroni, mẹ́rin ni gbogbo rẹ̀.

2Àwọn ọmọ Tola:

Ussi, Refaiah, Jehieli, Jamai, Ibsamu àti Samuẹli olórí àwọn ìdílé wọn. Ní àkókò ìjọba, Dafidi, àwọn ìran ọmọ Tola tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin alágbára ní ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-ẹgbẹ̀ta (22,600).

3Àwọn ọmọ, Ussi:

Israhiah.

Àwọn ọmọ Israhiah:

Mikaeli, Ọbadiah, Joeli àti Iṣiah. Gbogbo àwọn márààrún sì jẹ́ olóyè. 4Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n ní ọkùnrin ẹgbàá-mẹ́rìndínlógójì tí ó ti ṣe tan fún ogun, nítorí wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àti ìyàwó.

5Àwọn ìbátan tí ó jẹ́ alágbára akọni àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ti àwọn ìdílé Isakari, bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínláàádọ́rin (87,000) ni gbogbo rẹ̀.

Benjamini

6Àwọn ọmọ mẹ́ta Benjamini:

Bela, Bekeri àti Jediaeli.

7Àwọn ọmọ Bela:

Esboni, Ussi, Usieli, Jerimoti àti Iri, àwọn márààrún. Àwọn ni olórí ilé baba ńlá wọn, akọni alágbára ènìyàn. A sì ka iye wọn nípa ìran wọn sí ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ènìyàn (22,034).

8Àwọn ọmọ Bekeri:

Semirahi, Joaṣi, Elieseri, Elioenai, Omri, Jeremoti, Abijah, Anatoti àti Alemeti. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ọmọ Bekeri 9Ìtàn ìdílé wọn láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn tí a kọ lẹ́sẹẹsẹ jẹ́ ti àwọn olórí ìdílé àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ogún ó-lé-nígba (20,200) ọkùnrin alágbára.

10Ọmọ Jediaeli:

Bilhani.

Àwọn ọmọ Bilhani:

Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari. 11Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rúnmẹ́tà-dínlógún ó-lé-nígba akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.

12Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.

Naftali

13Àwọn ọmọ Naftali:

Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.

Manase

14Àwọn ìran ọmọ Manase:

Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi. 15Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Ṣelofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo. 16Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.

17Ọmọ Ulamu:

Bedani.

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase.

18Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila.

19Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́:

Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu.

Efraimu

20Àwọn ìran ọmọ Efraimu:

Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀,

Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀.

Tahati ọmọ rẹ̀ 21Sabadi ọmọ, rẹ̀,

àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀.

Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn 22Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú. 23Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà. 24Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú.

25Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀,

Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀,

26Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀,

Eliṣama ọmọ rẹ̀, 27Nuni ọmọ rẹ̀

àti Joṣua ọmọ rẹ̀.

28Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò. 29Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí.

Aṣeri

30Àwọn ọmọ Aṣeri:

Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera.

31Àwọn ọmọ Beriah:

Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti.

32Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua.

33Àwọn ọmọ Jafileti:

Pasaki, Bimhali àti Asifati.

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti.

34Àwọn ọmọ Ṣomeri:

Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu.

35Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu

Ṣofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali.

36Àwọn ọmọ Ṣofahi:

Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra. 37Beseri, Hodi, Ṣama, Ṣilisa, Itrani àti Bera.

38Àwọn ọmọ Jeteri:

Jefunne, Pisifa àti Ara.

39Àwọn ọmọ Ulla:

Arah, Hannieli àti Reṣia.

40Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin.