歴代誌Ⅰ 23 – JCB & YCB

Japanese Contemporary Bible

歴代誌Ⅰ 23:1-32

23

レビ人の組み分け

1すっかり年老いたダビデはソロモンに王位を譲り、 2その即位式にイスラエルのすべての政治的、宗教的指導者を召集しました。 3レビ族で三十歳以上の男の人数を数えたところ、その合計は三万八千でした。

4-5ダビデはこのように指示しました。「そのうち、二万四千人は神殿の仕事を監督しなさい。六千人は管理者と裁判官、四千人は門衛となり、あとの四千人は私の作った楽器で主を賛美しなさい。」

6ダビデは彼らを、レビの三人の息子の名にちなんで、ゲルションの組、ケハテの組、メラリの組に分けました。

7ゲルションの組は、さらに二人の子の名にちなんで、ラダンの班とシムイの班に分けられました。 8-9その班がまた、ラダンとシムイの子たちの名にちなんで、六つのグループに分けられました。ラダンの子は、指導者エヒエル、ゼタム、ヨエル。シムイの子はシェロミテ、ハジエル、ハラン。

10-11シムイの各氏族には、四人の子の名がつけられました。長はヤハテで、次がジザ。エウシュとベリアは子どもが少なかったので、合わせて一つの氏族を構成しました。

12ケハテの組は、その子の名にちなんで、アムラム、イツハル、ヘブロン、ウジエルの四つの班に分けられました。

13アムラムはアロンとモーセの父です。アロンとその子たちは、人々のささげ物を主に奉納する奉仕に取り分けられました。アロンはいつも主に仕え、御名によって人々を祝福したからです。

14-15神の人モーセについて言えば、その子ゲルショムとエリエゼルはレビ族に入れられました。 16ゲルショムの子たちの長はシェブエルです。 17エリエゼルのひとり息子のレハブヤは子どもが大ぜいいたので、氏族の長となりました。

18イツハルの子たちの長はシェロミテ。

19ヘブロンの子たちの長はエリヤ。第二はアマルヤ、第三はヤハジエル、第四はエカムアム。

20ウジエルの子らの長はミカで、第二はイシヤ。

21メラリの子はマフリとムシ。マフリの子はエルアザルとキシュ。 22エルアザルには息子がなく、娘たちが、いとこに当たるキシュの息子たちと結婚しました。 23ムシの子はマフリ、エデル、エレモテ。

24人口調査の時、二十歳以上のレビ人はみな、以上の氏族やその一族に組み入れられ、神殿の奉仕を割り当てられました。 25ダビデがこう言ったからです。「イスラエルの神、主は平和を与えてくださった。これからは、主はエルサレムにお住みになる。 26レビ人はもう、幕屋や礼拝の器具をいちいち運ばなくてもよい。」

27このレビ族の人口調査は、ダビデが死ぬ前に行った最後のものでした。 28レビ人の仕事は、神殿でいけにえをささげるアロンの子孫である祭司を補佐することでした。また、神殿の管理に当たり、きよめの儀式を行う手伝いもしました。 29供えのパン、穀物のささげ物用の小麦粉、それにオリーブ油で揚げたり、オリーブ油を混ぜ合わせたりした、パン種(イースト菌)を入れない薄焼きのパンなどを用意しました。また、すべての物の重さや大きさをはかり、 30毎日、朝と夕方には、主の前に立って感謝をささげ、賛美しました。 31さらに、焼き尽くすいけにえ、安息日のいけにえ、新月の祝いや各種の例祭用のいけにえも用意しました。そのときに応じて必要な数のレビ人がこれに当たりました。 32彼らは幕屋や神殿の管理を行い、求められることは何でも行って、祭司たちを助けました。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 23:1-32

Àwọn ará Lefi

1Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli.

2Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. 3Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlógún (38,000) 4Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá-méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbàáta (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́. 5Ẹgbàajì (4,000) ni kí ó jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà àti ẹgbàajì (4,000) ni kí o sì jẹ́ ẹni ti yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú ohun èlò orin, mo ti ṣe èyí fún ìdí pàtàkì yìí.

6Dafidi sì pín àwọn ọmọ Lefi sí ẹgbẹgbẹ́ láàrín àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Àwọn ọmọ Gerṣoni

7Àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Gerṣoni:

Laadani àti Ṣimei.

8Àwọn ọmọ Laadani

Jehieli ẹni àkọ́kọ́, Setamu àti Joeli, mẹ́ta ní gbogbo wọn.

9Àwọn ọmọ Ṣimei:

Ṣelomiti, Hasieli àti Harani mẹ́ta ní gbogbo wọn.

Àwọn wọ̀nyí sì ni olórí àwọn ìdílé Laadani.

10Àti ọmọ Ṣimei:

Jahati, Sina, Jeuṣi àti Beriah.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ṣimei mẹ́rin ni gbogbo wọn.

11Jahati sì ni alákọ́kọ́ Sinah sì ni ẹlẹ́kejì, ṣùgbọ́n Jeuṣi àti Beriah kò ní àwọn ọmọ púpọ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ka ara wọn sí ìdílé kan pẹ̀lú ìfilé lọ́wọ́ kan.

Àwọn ará Kohati

12Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli mẹ́rin ni gbogbo wọn.

1323.13: El 28.1.Àwọn ọmọ Amramu.

Aaroni àti Mose.

A sì ya Aaroni sọ́tọ̀ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí láéláé, láti kọjú sí ohun mímọ́ jùlọ, láti fi rú ẹbọ sísun níwájú Olúwa, láti máa ṣe òjíṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti kéde ìbùkún ní orúkọ rẹ̀ títí láéláé. 14Àwọn ọmọ Mose ènìyàn Ọlọ́run ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀yà Lefi.

15Àwọn ọmọ Mose:

Gerṣomu àti Elieseri.

16Àwọn ọmọ Gerṣomu:

Ṣubueli sì ni alákọ́kọ́.

17Àwọn ọmọ Elieseri:

Rehabiah sì ni ẹni àkọ́kọ́.

Elieseri kò sì tún ní ọmọ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Rehabiah wọ́n sì pọ̀ níye.

18Àwọn ọmọ Isari:

Ṣelomiti sì ni ẹni àkọ́kọ́.

19Àwọn ọmọ Hebroni:

Jeriah sì ni ẹni àkọ́kọ́, Amariah sì ni ẹni ẹ̀ẹ̀kejì,

Jahasieli sì ni ẹ̀ẹ̀kẹ́ta àti Jekameamu ẹ̀ẹ̀kẹrin.

20Àwọn ọmọ Usieli:

Mika ni àkọ́kọ́ àti Iṣiah ẹ̀ẹ̀kejì.

Àwọn ará Merari

21Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Àwọn ọmọ Mahili:

Eleasari àti Kiṣi.

22Eleasari sì kú pẹ̀lú Àìní àwọn ọmọkùnrin: Ó ní ọmọbìnrin nìkan. Àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n, àwọn ọmọ Kiṣi, sì fẹ́ wọn.

23Àwọn ọmọ Muṣi:

Mahili, Ederi àti Jerimoti mẹ́ta ni gbogbo wọn.

24Àwọn wọ̀nyí sì ni ọmọ Lefi bí ìdílé wọn. Olórí ìdílé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ lábẹ́ orúkọ wọn, ó sì kà wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, wí pé, àwọn òṣìṣẹ́ tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa 25Nítorí pé Dafidi ti sọ pé Ọlọ́run Israẹli, ti fi ìsinmi fún àwọn ènìyàn tí ó kù tí sì ń gbé Jerusalẹmu títí láéláé. 26Àwọn ọmọ Lefi kò sì tún ru àgọ́ tàbí ọ̀kankan lára àwọn ohun èlò tí wọ́n ń lò níbi ìsìn rẹ̀. 27Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi sí, àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì kà wọ́n, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ọmọ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

28Iṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ni láti ran àwọn ọmọ Aaroni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wọn fún ti ilé Olúwa: láti wà lábẹ́ ìkáwọ́ agbára ìlú, àti ẹ̀gbẹ́ ilé, àti ìwẹ̀nùmọ́ ti gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ àti ṣíṣe ohun tí í ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ilé Olúwa. 29Wọ́n sì wà ní ìkáwọ́ àkàrà tí wọ́n mú jáde láti orí tábìlì, àti ìyẹ̀fun fún ẹbọ, àti àkàrà aláìwú, àti fún púpọ̀ àti èyí tí a pòpọ̀, àti gbogbo onírúurú ìwọ̀n àti wíwọ̀n àti òṣùwọ̀n. 30Wọ́n sì gbọdọ̀ dúró ní gbogbo òwúrọ̀ láti dúpẹ́ àti láti yin Olúwa. Wọ́n sì gbọdọ̀ ṣe irú kan náà ní àṣálẹ́. 31Àti láti rú ẹbọ sísun fún Olúwa ní ọjọ́ ìsinmi àti ní àsìkò oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn. Wọ́n gbọdọ̀ sìn níwájú Olúwa lójoojúmọ́ ní iye tó yẹ àti ní ọ̀nà tí a ti pàṣẹ fún wọn.

32Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà, àwọn ọmọ Lefi gbé ìgbékalẹ̀ jáde fún ìpàdé àgọ́, fún ibi mímọ́ àti, lábẹ́ àwọn arákùnrin àwọn ọmọ Aaroni fún ìsìn ilé Olúwa.