ナホム書 2 – JCB & YCB

Japanese Contemporary Bible

ナホム書 2:1-13

2

滅ぼされるニネベ

1ニネベよ。おまえはもうおしまいだ。

すでに敵の軍隊に囲まれている。

警鐘を鳴らせ。城壁に人を配置し、守りを固め、

全力を尽くして敵の侵入を見張れ。

2神の民の地は、おまえの攻撃で人はいなくなり、

破壊された。

だが主は、彼らの誉れと力とを回復する。

3兵士の盾は太陽の光を受け、真っ赤に輝く。

攻撃開始だ。深紅の軍服を見よ。

飛び跳ねる馬に引かれて、

ぴかぴかの戦車が並んで進んで来るのを見よ。

4あなたの戦車は、たいまつのような光を放ちながら、

向こう見ずに通りを突っ走り、広場を走り抜ける。

5王は役人たちを呼んで叫ぶ。

彼らはあわてふためいてつまずきながら、

守備を固めようと、城壁に向かって走る。

6だが、もう遅い。水門は開かれた。

敵が入って来る。宮殿は大騒ぎだ。

7ニネベの王妃は裸で通りに引き出され、

奴隷として引いて行かれる。

泣き悲しむ侍女たちもいっしょだ。

彼女たちが鳩のように泣く声と、

悲しんで胸を打つ音を聞け。

8ニネベは水のもれる水槽のようだ。

兵士たちは町を見捨てて、こっそり逃げ出す。

呼び戻すことはできない。

「止まれ、止まれ」とニネベが叫んでも、

彼らは走り続ける。

9銀を奪え。金を奪え。

財宝はいくらでもある。

山のような富もはぎ取られてしまう。

10まもなく、この町は人っ子一人いない

散乱状態となる。

心は恐怖におののき、ひざは震え、

彼らはぼう然として青ざめる。

11諸国の間でライオンのようにふるまい、

闘志と大胆さをみなぎらせていた町、

年老いて弱くなった者も、いたいけな子どもも

恐れることなく暮らしていた町、

あの偉大なニネベは今、どこにあるのか。

12ニネベよ、かつての勇猛なライオンよ。

おまえは妻子に食べさせるために

多くの敵を押しつぶし、

町と家を分捕り物と奴隷でいっぱいにした。

13しかし今、全能の主がおまえに立ち向かう。

武器は破壊され、

戦車は使われないままひっそりと放置される。

すぐれた若者も死んで横たわる。

もう、他国を征服して奴隷を連れて来ることもない。

再びこの地を支配できないのだ。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Nahumu 2:1-13

Ìṣubú Ninefe

1Àwọn apanirun ti dìde sí ọ, ìwọ Ninefe

pa ilé ìṣọ́ mọ́,

ṣọ́ ọ̀nà náà

di àmùrè, ẹ̀gbẹ́ rẹ kí ó le,

múra gírí.

2Olúwa yóò mú ọláńlá Jakọbu padà sípò

gẹ́gẹ́ bí ọláńlá Israẹli

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apanirun ti pa ibẹ̀ run,

tí wọ́n sì ba ẹ̀ka àjàrà wọn jẹ́.

3Asà àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì di pupa;

àwọn ológun wọn sì wọ aṣọ òdòdó.

Idẹ tí ó wà lórí kẹ̀kẹ́ ogun ń kọ mọ̀nàmọ́ná

ní ọjọ́ tí a bá pèsè wọn sílẹ̀ tán;

igi firi ni a ó sì mì tìtì.

4Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yóò ya bo àwọn pópónà,

wọn yóò sì máa sáré síwá àti sẹ́yìn ní àárín ìgboro.

Wọn sì dàbí ètùfù iná;

tí ó sì kọ bí i mọ̀nàmọ́ná.

5Ninefe yóò ṣe àṣàrò àwọn ọlọ́lá rẹ̀;

síbẹ̀ wọ́n ń kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà wọn;

wọn sáré lọ sí ibi odi rẹ̀,

a ó sì pèsè ààbò rẹ̀.

6A ó ṣí ìlẹ̀kùn àwọn odò wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀,

a ó sì mú ààfin náà di wíwó palẹ̀.

7A pa á láṣẹ pé ìlú náà, èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀

ni a ó sì kó ní ìgbèkùn lọ.

A ó sì mú un gòkè wá

àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò kérora bí ti ẹyẹ àdàbà,

wọn a sì máa lu àyà wọn.

8Ninefe dàbí adágún omi,

tí omi rẹ̀ sì ń gbẹ́ ẹ lọ.

“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,

ṣùgbọ́n ẹnìkankan kì yóò wo ẹ̀yìn.

9“Ẹ kó ìkógun fàdákà!

Ẹ kó ìkógun wúrà!

Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,

àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”

10Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:

ọkàn pami, eékún ń lu ara wọn,

ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́

àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.

11Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wà

àti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,

níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún tí ń rìn,

àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù

12Kìnnìún tipa ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀,

ó sì fún un ẹran ọdẹ ní ọrùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,

Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀

àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.

13“Kíyèsi i èmi dojúkọ ọ́,”

ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín,

idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run.

Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayé

Ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ

ni a kì yóò sì tún gbọ́ mọ́.”