Openbaring 7 – HTB & YCB

Het Boek

Openbaring 7:1-17

De 144.000 voor Gods troon

1Daarna zag ik vier engelen op de vier hoeken van de aarde staan. Zij hielden de vier winden vast, zodat er nergens een zuchtje wind was. De zee was zo glad als een spiegel en er ritselde geen blad aan de bomen. 2Uit het oosten zag ik een andere engel opkomen, die het zegel van de levende God bij zich had. Hij riep naar de vier engelen die van God macht hadden gekregen om de aarde en de zee schade toe te brengen: 3‘Wacht! Breng nog geen schade toe aan de aarde, de zee en de bomen, want wij moeten eerst het zegel van onze God op het voorhoofd van zijn dienaren drukken.’ 4En ik hoorde hoeveel mensen het zegel kregen: honderdvierenveertigduizend uit het volk van Israël: 5twaalfduizend uit elk van de twaalf stammen, dus uit Juda, Ruben en Gad, 6uit Aser, Naftali en Manasse, 7uit Simeon, Levi en Issaschar, 8uit Zebulon, Jozef en Benjamin.

9Daarna zag ik een ontelbare menigte mensen. Zij kwamen uit alle rassen, volken, stammen en taalgroepen. Zij stonden voor de troon en voor het Lam, met witte kleren aan en palmtakken in de hand. 10Zij riepen luid: ‘Onze redding komt van onze God, die op de troon zit en van het Lam!’ 11Alle engelen stonden om de troon, de ouderlingen en de vier levende wezens. Zij lieten zich voor de troon op de knieën vallen, met hun hoofd voorover en aanbaden God. 12‘Amen,’ zeiden zij. ‘Alle lof, heerlijkheid, wijsheid en dank, alle eer, macht en kracht is voor onze God, voor altijd en eeuwig. Amen.’

13Een van de ouderlingen vroeg mij: ‘Wie zijn die mensen in witte kleren? En waar komen zij vandaan?’ 14Ik antwoordde: ‘Ik weet het niet, maar ú wel. Wilt u het mij zeggen?’ En hij zei tegen mij: ‘Dat zijn de mensen die de grote verdrukking hebben doorstaan. Zij hebben hun kleren wit gewassen in het bloed van het Lam. 15Daarom staan zij voor de troon van God en dienen zij Hem dag en nacht in zijn tempel. Hij die op de troon zit, zal bij hen wonen. 16Zij zullen geen honger of dorst meer hebben en ook niet meer door de brandende zon en de verzengende hitte gehinderd worden, 17want het Lam, dat voor de troon staat, zal hun herder zijn en hen naar de waterbronnen van het leven brengen. En God zal alle tranen van hun ogen afwissen.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 7:1-17

Ọ̀kẹ́ méje-olé-ẹgbàá-méjì èdìdì ìwé

17.1: Sk 6.5.Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. 2Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, 37.3: El 9.4.wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” 4Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.

5Láti inú ẹ̀yà Juda a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Reubeni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Gadi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

6Láti inú ẹ̀yà Aṣeri a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Naftali a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Manase a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

7Láti inú ẹ̀yà Simeoni a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Lefi a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Isakari a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

8Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Josẹfu a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Láti inú ẹ̀yà Benjamini a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá-mẹ́fà (12,000).

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ẹ̀wù funfun

9Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:

“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá

tí o jókòó lórí ìtẹ́,

àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”

11Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12Wí pe:

“Àmín!

Ìbùkún, àti ògo,

àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,

àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!

Àmín!”

13Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”

147.14: Da 12.1; Gẹ 49.11.Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”

Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15Nítorí náà ni,

“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,

tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;

ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.

167.16: Isa 49.10; Sm 121.6.Ebi kì yóò pa wọn mọ́,

bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;

bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn

tàbí oorukóoru kan.

177.17: El 34.23; Sm 23.2; Isa 25.8.Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn,

‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’

‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”