Numeri 11 – HTB & YCB

Het Boek

Numeri 11:1-35

Het volk klaagt

1Het volk begon al snel te klagen over allerlei tegenslagen en de Here hoorde dat. Hij werd toornig en stuurde vuur naar beneden dat rond het volk brandde. 2Daarop schreeuwden de Israëlieten naar Mozes om hulp en toen hij voor hen bad, doofde het vuur. 3Vanaf dat moment heette die plaats Tabera (Brand), omdat het vuur van de Here daar onder de Israëlieten was opgelaaid.

4-5 Toen begonnen de vreemdelingen die waren meegekomen met de uittocht, terug te verlangen naar het goede leven in Egypte. Zij staken daarmee de Israëlieten aan en die begonnen te jammeren: ‘Och, als we maar wat vlees te eten hadden! Denk eens aan die heerlijke vis die we in Egypte konden eten, aan die komkommers en meloenen, aan dat look, die uien en dat heerlijke knoflook. 6We verzwakken helemaal en kunnen geen manna meer zien!’ 7Het manna was ongeveer even groot als korianderzaad en zag er uit als druppels balsemhars die uit de bast van een boom sijpelen. 8De mensen raapten het van de grond en vermaalden het dan in een handmolen of stampten het fijn met een vijzel. Daarna kookten zij het en bakten er koeken van, die net zo smaakten als in olie gebakken koeken. 9Samen met de dauw bedekte het manna ʼs nachts het kamp.

10Mozes hoorde hoe elk gezin bij de ingang van zijn tent stond te klagen. De Here werd steeds toorniger en toen werd het Mozes te veel. 11Hij zei tegen de Here: ‘Waarom straft U mij door dit volk als een zware last op mijn schouders te leggen? 12Zijn het mijn kinderen soms? Ben ík hun vader? Hebt U mij daarom als leider met hen meegestuurd om hen de hele reis naar dat land dat U aan hun nageslacht hebt beloofd, zoet te houden alsof het kleine kinderen zijn? 13Waar moet ik vlees voor al deze mensen vandaan halen? Want zij jammeren tegen mij: “Geef ons vlees.” 14Ik kan niet alleen voor dit hele volk zorgen! Die last is veel te zwaar! 15Als U mij dat wilt aandoen, laat mij dan maar liever sterven, dan ben ik tenminste van alle ellende af.’

16Toen zei de Here tegen Mozes: ‘Ontbied zeventig leiders van Israël voor Mij. Breng hen naar de tabernakel en laten ze bij u gaan staan. 17Ik zal naar beneden komen en met u praten en een deel van de Geest die op u rust, op hen overbrengen zodat zij u kunnen helpen de last van dit volk te dragen. Dan staat u er niet langer alleen voor. 18Zeg tegen het volk dat het zich heiligt, want morgen zal het vlees te eten krijgen. Zeg tegen de Israëlieten: de Here heeft uw gejammer gehoord over alles wat u in Egypte hebt achtergelaten. Hij zal u nu vlees te eten geven. En u zúlt vlees eten! 19-20 Niet maar een of twee dagen of vijf of zelfs twintig dagen, maar een hele maand! U zult vlees eten tot het uw neus uitkomt en u ervan walgt! Want u hebt uw verachting voor de Here, die in uw midden is, laten blijken en gejammerd: “Waarom zijn wij toch uit Egypte weggegaan?” ’ 21Maar Mozes zei: ‘Wij zijn met zeshonderdduizend mensen uit Egypte vertrokken en U belooft ons vlees voor een hele maand! 22Zelfs als we al onze kudden slachten, zou dat nog niet genoeg zijn voor één maand vlees! We zouden elke vis in de zee moeten vangen om uw belofte waar te maken!’ 23Toen zei de Here tegen Mozes: ‘Gelooft u Mij niet? Let maar eens op of mijn woorden uitkomen!’

24Mozes verliet de tabernakel en gaf de boodschap van de Here door aan het volk. Hij riep de zeventig leiders bijeen en posteerde hen rond de tabernakel. 25De Here kwam in de wolk naar beneden en sprak met Mozes en nam een deel van de Geest die op hem rustte en legde die op de zeventig leiders. Toen de Geest op hen rustte, profeteerden zij een korte tijd. 26Maar twee van de zeventig, Eldad en Medad, waren niet naar de tabernakel gegaan en profeteerden in het kamp toen de Geest op hen kwam. 27Een jongeman rende daarop naar Mozes en vertelde hem wat in het kamp gebeurde. 28Jozua, de zoon van Nun, een van Mozesʼ zelfgekozen helpers, protesteerde: ‘Mozes, laten zij toch ophouden!’ 29Maar Mozes antwoordde: ‘Wil jij het voor mij opnemen? Ik zou willen dat heel het volk van de Here profeet was en dat de Here zijn Geest op hen allen legde!’ 30Toen ging Mozes met de leiders terug naar het kamp.

31De Here liet vanuit zee kwartels meevoeren door de wind. Hij liet de vogels in en rond het kamp neerstrijken. Een dagreis ver vlogen kwartels op een hoogte van ongeveer één meter boven de grond. 32Het hele volk ging eropuit om kwartels te vangen. Een karwei dat een dag, een nacht en nog een hele dag in beslag nam! Het minste dat iemand verzamelde, was tweeëntwintighonderd liter! Overal rond het kamp lagen de kwartels te drogen. 33Maar toen iedereen het vlees begon te eten, ontvlamde de toorn van de Here tegen het volk en Hij doodde velen met een plaag. 34Daarom kreeg die kampplaats de naam Kibrot-Hattaäwa (Graven van de Gulzigaards), want daar begroeven zij de mensen die begerig waren naar vlees en terugverlangden naar Egypte. 35Van die plaats trokken zij naar Chaserot, waar zij een tijd bleven.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 11:1-35

Kíkùn àwọn ènìyàn àti iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa

1Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etí ìgbọ́ Olúwa. Ìbínú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí, Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárín wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó. 2Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mose, Mose sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú. 3Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrín wọn.

Ẹran àparò láti ọ̀dọ̀ Olúwa

411.4: 1Kọ 10.6.Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí! 5Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn 6Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi manna nìkan tí a rí yìí!”

7Manna náà dàbí èso korianderi, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi. 8Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe. 9Nígbà tí ìrì bá ẹ̀ sí ibùdó lórí ni manna náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

10Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú. 11Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí. 12Èmi ni mo ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí bí? Àbí èmi ló bí wọn? Tí ìwọ fi sọ fún mi pé, máa gbé wọn sí oókan àyà rẹ, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ ti máa ń gbe ọmọ ọmú lọ sí ilẹ̀ tí o ti búra láti fún àwọn baba ńlá wọn. 13Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’ 14Èmi nìkan kò lè dágbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi. 15Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojúrere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”

16Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrín àwọn ènìyàn wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi. 17Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mí tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.

18“Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Ejibiti jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́. 19Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán, 20Ṣùgbọ́n fún odidi oṣù kan: títí tí ẹran náà yóò fi máa yọ ní imú yín, tí yóò sì sú yín: nítorí pé ẹ ti kẹ́gàn Olúwa tí ó wà láàrín yín, ẹ sì ti sọkún fún un wí pé, “Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ejibiti gan an?” ’ ”

21Ṣùgbọ́n Mose sọ pé, “Mo wà láàrín ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn (600,000) ni ìrìnkiri, ó sì sọ pé, ‘Èmi ó fún wọn ní ẹran láti jẹ fún oṣù kan gbáko!’ 22Ǹjẹ́ bí a tilẹ̀ pa àgbò ẹran àti ọmọ ẹran, yóò ha tó wọn bí? Tàbí bí a tilẹ̀ pa gbogbo ẹja inú omi fún wọn, yóò wa tó bí?”

23Olúwa sì dá Mose lóhùn pé, “Ọwọ́ Olúwa ha kúrú bí? Ìwọ yóò ri nísinsin yìí bóyá ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò ṣẹ tàbí kò ni í ṣẹ.”

24Mose sì jáde, ó sọ ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn. Ó mú àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà Israẹli dúró yí àgọ́ ká. 25Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ìkùùkuu ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì mú lára Ẹ̀mí tó wà lára Mose sí ara àwọn àádọ́rin (70) àgbàgbà náà, Ó sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sọtẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí wọn kò sọtẹ́lẹ̀ mọ́.

26Àwọn ọkùnrin méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Eldadi àti Medadi kò kúrò nínú àgọ́. Orúkọ wọn wà lára àádọ́rin (70) àgbàgbà yìí ṣùgbọ́n wọn kò jáde nínú àgọ́ síbẹ̀ Ẹ̀mí náà bà lé wọn, wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́. 27Ọmọkùnrin kan sì sáré lọ sọ fún Mose pé, “Eldadi àti Medadi ń sọtẹ́lẹ̀ nínú àgọ́.”

28Joṣua ọmọ Nuni tí í ṣe ìránṣẹ́ Mose, láti kékeré tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dáhùn pé, “Mose olúwa mi, dá wọn lẹ́kun!”

29Mose sì wí fún un pé, “Àbí ìwọ ń jowú nítorí mi? Ìbá ti wù mí tó, kí gbogbo àwọn ènìyàn Olúwa jẹ́ wòlíì, kí Olúwa sì fi Ẹ̀mí rẹ̀ sí wọn lára!” 30Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli yìí sì padà sínú àgọ́.

31Afẹ́fẹ́ sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa ó sì kó àparò wá láti inú Òkun. Ó sì dà wọ́n káàkiri gbogbo ibùdó ní ìwọ̀n gíga ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta sórí ilẹ̀, bí ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan ní gbogbo àyíká. 32Ní gbogbo ọjọ́ náà àti òru, títí dé ọjọ́ kejì ni àwọn ènìyàn fi ń kó àparò yìí: Ẹni tó kó kéré jùlọ kó ìwọ̀n homeri mẹ́wàá, wọ́n sì ṣà wọ́n sílẹ̀ fún ara wọn yí gbogbo ibùdó. 33Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹran náà sì wà láàrín eyín wọn, kó tó di pé wọ́n jẹ ẹ́, ìbínú Olúwa sì ru sí àwọn ènìyàn, ó sì pa wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn. 3411.34: 1Kọ 10.6.Torí èyí ni wọ́n ṣe pe ibẹ̀ ní Kibirotu-Hattaafa nítorí pé níbẹ̀ ni wọ́n gbé sìnkú àwọn ènìyàn tó ní ọ̀kánjúwà oúnjẹ sí.

35Àwọn ènìyàn yòókù sì gbéra láti Kibirotu-Hattaafa lọ pa ibùdó sí Haserotu wọ́n sì dúró níbẹ̀.