Exodus 26 – HTB & YCB

Het Boek

Exodus 26:1-37

Instructies voor de bouw van de tabernakel

1‘Maak de tabernakel van tien gekleurde tentdoeken van 12,6 meter lang en 1,8 meter breed. 2Ze moeten worden gemaakt van getwijnd linnen, blauwpurper, roodpurper en scharlaken en er moeten engelfiguren in worden geweven. 3Bevestig vijf doeken aan elkaar voor één zijde van de tent, zodat twee lange zijden ontstaan van elk vijf doeken. 4-5 Maak aan de uiteinden van deze zijden 50 lussen die tegenover elkaar komen te liggen. 6Maak dan 50 gouden haken om de lussen bijeen te halen, zodat de tabernakel één geheel wordt.

7-8 Het dak van de tabernakel moet bestaan uit elf tentdoeken van geitehaar, 13,5 meter lang en 1,8 meter breed. 9Bevestig vijf van deze doeken aan elkaar en doe hetzelfde met de zes andere, zodat het twee lange zijden worden. Het zesde doek hangt aan de voorkant van de tabernakel als een gordijn voor de ingang. 10-11 Maak 50 lussen langs de zijden van deze twee delen en bevestig deze aan elkaar met 50 koperen haken. Zo zullen de twee stukken één geheel vormen. 12-13 Het dak overlapt de zijkanten van de tabernakel dan overal met 45 cm. 14Over de tent komt dan nog een dekkleed van roodgeverfde ramsvellen en daar overheen komt een dekkleed van dassenvellen.

15-16 Het houten geraamte van de tent moet van acaciahout worden gemaakt. De panelen van het geraamte moeten 4,5 meter hoog en 68 cm breed zijn en rechtop staan. 17In de smalle zijden moeten pinnen komen, zodat ze stevig tegen elkaar aan komen te staan. 18-19 Twintig van deze panelen vormen de zuidkant van de tent. Onder die twintig panelen moeten veertig zilveren voetstukken komen, waar de rest van het geraamte in past, twee voetstukken onder elk paneel. 20De noordkant van de tent moet ook uit twintig panelen bestaan, 21met veertig zilveren voetstukken er onder, voor elk paneel twee. 22Voor de westkant van de tent moeten zes panelen worden gebruikt 23en voor elke hoek van de tent twee panelen. 24Van boven en beneden moeten deze panelen worden vastgemaakt met een ring. 25In totaal zullen er dus acht panelen zijn met zestien zilveren voetstukken, onder elk paneel twee.

26-27 Ook de dwarsbalken moeten van acaciahout worden gemaakt. Gebruik er vijf voor elke kant van de tabernakel. 28De middelste dwarsbalk loopt door het hart van de panelen van het ene naar het andere eind van de tabernakel. 29Overtrek de panelen en dwarsbalken met goud en maak gouden ringen als houders voor de dwarsbalken. 30Zet deze tabernakeltent op zoals Ik het u op de berg heb laten zien.

31Maak een gordijn van blauwpurper, roodpurper, scharlaken en getwijnd fijn linnen en weef er engelfiguren in. 32Hang het gordijn aan vier pilaren van acaciahout, overtrokken met goud en met vier gouden haken eraan. De pilaren moeten op zilveren voetstukken staan. 33Hang het gordijn aan de haken. Achter dit gordijn moet de ark met de stenen plaquettes met Gods wetten erop komen te staan. Zo zal het gordijn het Heilige en het Heilige der Heiligen scheiden. 34Leg dan het verzoendeksel op de ark van het verbond in het Heilige der Heiligen. 35Zet de tafel aan de andere kant van het gordijn aan de noordkant van de tabernakel. De kandelaar moet u daar tegenover zetten.

36Ook voor de ingang van de tent moet een gordijn worden gemaakt van blauwpurper, roodpurper, scharlaken en getwijnd fijn linnen. 37Hang dit gordijn aan vijf pilaren van acaciahout, overtrokken met goud, waaraan gouden haken zijn bevestigd. De pilaren moeten op koperen voetstukken staan.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 26:1-37

Àgọ́ náà

126.1-14: Ek 36.8-19.“Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn. 2Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. 3Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. 4Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. 5Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. 6Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

7“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. 8Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. 9Ìwọ ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. Ìwọ ó sì ṣẹ́ aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà. 10Ìwọ ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 11Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan. 12Àti ìyókù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà. 13Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó. 14Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

15“Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 1626.16-29: Ek 36.20-34.Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí. 18Ìwọ ó sì ṣe ogún (20) pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, 19Ìwọ ó sì ṣe ogójì (40) ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 20Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀ 21àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 22kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 23kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn. 24Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà. 25Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

26“Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 27Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà. 28Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà. 29Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30“Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè.

3126.31-37: Ek 36.35-38.“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 32Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin. 33Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 34Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 35Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fìtílà sí òdìkejì rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36“Fún ti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe. 37Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.