1 Kronieken 6 – HTB & YCB

Het Boek

1 Kronieken 6:1-81

De nakomelingen van Levi

1Hier volgen de namen van de zonen van Levi: Gersom, Kehat en Merari. 2Kehats zonen waren Amram, Jishar, Hebron en Uzziël. 3Amrams kinderen waren Aäron, Mozes en Mirjam. Aärons zonen waren Nadab, Abihu, Eleazar en Itamar. 4-10De oudste zonen van de elkaar opvolgende generaties van Aäron waren: Eleazar, de vader van Pinechas, de vader van Abisua, de vader van Bukki, de vader van Uzzi, de vader van Zerahja, de vader van Merajoth, de vader van Amarja, de vader van Ahitub, de vader van Zadok, de vader van Ahimaäz, de vader van Azarja, de vader van Johanan, de vader van Azarja, die hogepriester was van de tempel in Jeruzalem, die door Salomo was gebouwd.

11-15Deze Azarja was de vader van Amarja, de vader van Ahitub, de vader van Zadok, de vader van Sallum, de vader van Hilkia, de vader van Azarja, de vader van Seraja, de vader van Jozadak.

Jozadak werd balling, toen de Here het volk van Juda en Jeruzalem gevangen liet nemen door Nebukadnezar.

16Zoals hierboven aangegeven, waren Gersom, Kehat en Merari de zonen van Levi. 17De zonen van Gersom waren Libni en Simi. 18De zonen van Kehat waren Amram, Jishar, Hebron en Uzziël.

19-21De zonen van Merari waren Machli en Musi. De families van de Levieten waren als volgt naar hun gezinshoofden verdeeld: in de familie van Gersom: Libni, Jahath, Zimma, Joah, Iddo, Zarah en Jeathrai. 22-24In de familie van Kehat: Amminadab, Korach, Assir, Elkana, Ebjasaf, Assir, Tachat, Uriël, Uzzia en Saul. 25-27Het gezin van Elkana was verder verdeeld in de volgende gezinnen van zijn zonen Amasai, Ahimoth, Elkana, Zofai, Nachat, Eliab, Jeroham en Elkana. 28De gezinnen van de familie van Samuël werden geleid door Samuëls zonen: Joël, de oudste, en Abia, de tweede zoon. 29-30 De gezinnen van de familie van Merari werden geleid door zijn zonen Machli, Libni, Simi, Uzza, Simea, Haggia en Asaja.

31Koning David wees deze mannen als koorleiders aan en liet koren vormen om God in de tabernakel te prijzen, nadat hij daar de ark een plaats had gegeven. 32Totdat Salomo de tempel in Jeruzalem had gebouwd, gingen zij daar door met het leiden van de samenzang.

33-38Hier volgen de namen van de nakomelingen van de koorleiders: de zanger Heman kwam uit de familie van Kehat en zijn geslachtsregister ging terug via de volgende personen: Joël, Samuël, Elkana, Jeroham, Eliël, Toah, Suf, Elkana, Mahath, Amassai, Elkana, Joël, Azarja, Zefanja, Tachat, Assir, Ebjasaf, Korach, Jishar, Kehat, Levi en Israël. 39-43Hemans helper was Asaf, wiens stamboom terugging via Berechja, Simea, Michaël, Baëseja, Malkia, Ethni, Zerach, Adaja, Ethan, Zimma, Simi, Jahath, Gersom en Levi. 44-47Hemans tweede helper was Ethan, een lid van de familie van Merari, die aan zijn linkerhand stond. Ethans stamboom liep terug via Kisi, Abdi, Malluch, Hasabja, Amazia, Hilkia, Amzi, Bani, Semer, Machli, Musi, Merari en Levi.

48Hun familieleden, alle andere Levieten, waren belast met allerlei andere taken in de tabernakel. 49Maar alleen Aäron en zijn nakomelingen waren priesters. Tot hun taken behoorde het offeren van brandoffers en reukwerk, alle werkzaamheden die te maken hadden met het binnenste heiligdom, het Heilige der Heiligen, voor de verzoening van Israël met de Here. Zij zorgden ervoor dat alle aanwijzingen die Gods dienaar Mozes had gegeven, werden opgevolgd.

50-53De nakomelingen van Aäron waren Eleazar, Pinechas, Abisua, Bukki, Uzzi, Zerahja, Merajoth, Amarja, Ahitub, Zadok en Ahimaäz. 54Door middel van het lot werden aan de nakomelingen van Aäron die deel uitmaakten van de familie van Kehat, 55de vrijstad Hebron in Juda met de weidegronden er omheen toegewezen. 56-57 Maar de velden en omringende dorpen werden aan Kaleb, de zoon van Jefunne, gegeven. 58-59 De nakomelingen van Aäron kregen ook de volgende steden met weidegronden er omheen: Libna, Jattir, Estemoa, Hilen, Debir, Asan en Bet-Semes. 60Dertien andere steden met het omringende grasland, inclusief Geba, Alemeth en Anathoth, werden door de stam van Benjamin aan de priesters toegewezen. 61Daarna werd er geloot om de verdeling van het land van de overgebleven nakomelingen van de familie van Kehat te regelen en zij kregen tien steden in het gebied van de stam van Manasse.

62De gezinnen van de familie van Gersom kregen door middel van het lot dertien steden in het gebied van Basan van de stammen Issachar, Aser, Naftali en Manasse. 63De gezinnen van de Merari-familie kregen op diezelfde manier twaalf steden van de stammen Ruben, Gad en Zebulon. 64-65 Ook de stammen Juda, Simeon en Benjamin stelden op deze manier door middel van het lot steden beschikbaar aan de Levieten. De namen van deze steden werden daarbij hardop genoemd.

66-69De stam van Efraïm gaf de volgende vrijsteden met het omringende grasland aan de overgebleven gezinnen van de Kehat-familie: Sichem, de vrijstad in het gebergte Efraïm, Gezer, Jokmeam, Bet-Horon, Ajalon en Gath-Rimmon. 70De volgende vrijsteden met het omringende grasland kwamen in handen van de gezinnen van de Kehatieten uit het bezit van de stam van Manasse: Aner en Bileam.

71De vrijsteden met het omringende grasland die de stam van Manasse aan de gezinnen van de Gersom-familie gaf, waren: de vrijstad Golan in Basan en Astharoth. 72De stam van Issachar gaf hun Kedes, Dobrath, 73Ramot en Anem, met uiteraard de omringende weidegronden. 74De stam van Aser gaf hun Masal, Abdon, 75Hukok en Rechob, weer met het omringende grasland. 76De stam van Naftali gaf hun Kedes in Galilea, Hammon en Kirjataïm met het bijbehorende grasland. 77Van de stam van Zebulon kregen zij de steden Rimmono en Tabor. 78-79 Aan de overkant van de Jordaan, tegenover Jericho, gaf de stam van Ruben hun Beser, een woestijnstad, Jahza, Kedemoth en Mefaäth, met de daarbij behorende weidegronden. 80De stam van Gad gaf hun ten slotte Ramot in Gilead, Machanaïm, 81Chesbon en Jazer. Ook hier kregen zij de erbij behorende weidegronden bij.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 6:1-81

Lefi

16.1-15: Gẹ 46.11; Ek 6.16-20; Nu 3.2.Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

2Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.

3Àwọn ọmọ Amramu:

Aaroni, Mose àti Miriamu.

Àwọn ọmọkùnrin Aaroni:

Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

4Eleasari jẹ́ baba Finehasi,

Finehasi baba Abiṣua

5Abiṣua baba Bukki,

Bukki baba Ussi,

6Ussi baba Serahiah,

Serahiah baba Meraioti,

7Meraioti baba Amariah,

Amariah baba Ahitubu

8Ahitubu baba Sadoku,

Sadoku baba Ahimasi,

9Ahimasi baba Asariah,

Asariah baba Johanani,

10Johanani baba Asariah.

(Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11Asariah baba Amariah

Amariah baba Ahitubu

12Ahitubu baba Sadoku.

Sadoku baba Ṣallumu,

13Ṣallumu baba Hilkiah,

Hilkiah baba Asariah,

14Asariah baba Seraiah,

pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki

15A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

16Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

17Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

18Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

19Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20Ti Gerṣoni:

Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati

Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀, 21Joah ọmọkùnrin rẹ̀,

Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀

àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.

22Àwọn ìran ọmọ Kohati:

Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀,

Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. 23Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,

Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.

24Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,

Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.

25Àwọn ìran ọmọ Elkana:

Amasai, Ahimoti

26Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀

Nahati ọmọ rẹ̀, 27Eliabu ọmọ rẹ̀,

Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀

àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.

28Àwọn ọmọ Samuẹli:

Joeli àkọ́bí

àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.

29Àwọn ìran ọmọ Merari:

Mahili, Libni ọmọ rẹ̀.

Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.

30Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀

àti Asaiah ọmọ rẹ̀.

Ilé ti a kọ́ fún àwọn Olórin

31Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. 32Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati:

Hemani olùkọrin,

ọmọ Joeli, ọmọ Samuẹli,

34Ọmọ Elkana ọmọ Jerohamu,

ọmọ Elieli, ọmọ Toha

35Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,

ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli,

ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah

37Ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,

ọmọ Ebiasafi ọmọ Kora,

38ọmọ Isari, ọmọ Kohati

ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;

39Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:

Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, ọmọ Ṣimea,

40Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,

ọmọ Malkiah 41Ọmọ Etini,

ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42Ọmọ Etani, ọmọ Simma,

ọmọ Ṣimei, 43Ọmọ Jahati,

ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;

44láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:

Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi,

ọmọ Malluki, 45Ọmọ Haṣabiah

ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46Ọmọ Amisi ọmọ Bani,

ọmọ Ṣemeri, 47Ọmọ Mahili,

ọmọ Muṣi, ọmọ Merari,

ọmọ Lefi.

48Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run. 49Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.

50Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:

Eleasari ọmọ rẹ̀. Finehasi ọmọ rẹ̀,

Abiṣua ọmọ rẹ̀, 51Bukki ọmọ rẹ̀,

Ussi ọmọ rẹ̀. Serahiah ọmọ rẹ̀,

52Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,

Ahitubu ọmọ rẹ̀, 53Sadoku ọmọ rẹ̀

àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.

546.54-81: Jo 21.1-42.Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn):

55A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. 56Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne. 57Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa, 58Hileni, Debiri, 59Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.

60Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.

61Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.

62Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.

63Sebuluni Àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.

64Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.

67Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri 68Jokimeamu, Beti-Horoni. 69Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.

71Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati 73Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

74Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni, 75Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

76Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa, 79Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

80Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu, 81Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.