1 Kronieken 15 – HTB & YCB

Het Boek

1 Kronieken 15:1-29

De ark keert terug in Jeruzalem

1David bouwde in Jeruzalem enkele paleizen voor zichzelf en zocht ook een geschikte plaats uit voor de ark van God. Hij zette een nieuwe tent op om de ark daarin te plaatsen. 2Hij gaf daarbij de volgende bevelen: ‘Wanneer wij de ark overbrengen naar deze nieuwe tent mogen alleen de Levieten die dragen, want God heeft hen voor dit doel uitgekozen, zij moeten Hem voor altijd dienen.’ 3Daarna riep David heel Israël op naar Jeruzalem te komen om de aankomst van de ark op de plaats van bestemming te vieren. 4-10Dit waren de priesters en Levieten die bij die gebeurtenis aanwezig waren: honderdtwintig leden van de Kehat-familie, onder leiding van Uriël; tweehonderdtwintig leden van de Merari-familie, onder leiding van Asaja; honderddertig leden van de Gersom-familie, met Joël als hun leider; tweehonderd leden van de familie van Elisafan, onder leiding van Semaja; tachtig leden van de familie van Hebron, onder leiding van Eliël en honderdtwaalf leden van de familie van Uzziël, onder leiding van Amminadab. 11David riep de hogepriesters Zadok en Abjathar en de Levietenleiders Uriël, Asaja, Joël, Semaja, Eliël en Amminadab bij zich. 12‘U bent de leiders van de families van de Levieten,’ zei hij. ‘Reinig uzelf en al uw broeders, zodat u de ark van de Here, de God van Israël, naar de plaats kunt brengen die ik daarvoor heb klaargemaakt. 13De Here heeft ons een zware slag toegebracht, omdat u er de vorige maal niet bij was om de ark te dragen en wij ons niet aan Gods voorschrift hielden.’

14Zo onderwierpen de priesters en de Levieten zich aan de reinigingsceremonieën, als voorbereiding op het terugbrengen van de ark van de Here, de God van Israël. 15Daarna namen de Levieten de ark met behulp van de draagstokken op hun schouders, precies zoals Mozes het in opdracht van de Here had voorgeschreven. 16Koning David gaf de leiders van de Levieten tevens opdracht de zangers te voorzien van muziekinstrumenten en zij zongen en speelden luid en vrolijk op harpen, citers en cymbalen. 17Heman, de zoon van Joël, Asaf, de zoon van Berechja, en Ethan, de zoon van Kusaja, uit de familie van Merari, werden door de Levieten aangewezen voor de muzikale leiding. 18-19 De volgende mannen werden gekozen als hun helpers: Zecharja, Ben-Jaäziël, Semiramot, Jehiël, Unni, Eliab, Benaja, Maäseja, Mattithja, Elifele, Mikneja, Obed-Edom en Jeiël, de poortwachters. De koorleiders Heman, Asaf en Ethan bespeelden tevens de koperen cymbalen en 20Zecharja, Aziël, Semiramot, Jehiël, Unni, Eliab, Maäseja en Benaja zongen samen, begeleid door hooggestemde harpen. 21Mattithja, Elifele, Mikneja, Obed-Edom, Jeiël en Azazja bespeelden de citers die acht tonen lager waren gestemd. 22Dirigent was Kenanja, het hoofd van de Levieten, die was gevraagd wegens zijn grote ervaring. 23Berechja en Elkana fungeerden als wachters bij de ark. 24Sebanja, Josafat, Netanel, Amasai, Zecharja, Benaja en Eliëzer—allemaal priesters—liepen vooraan in de stoet en bespeelden trompetten. Ook Obed-Edom en Jehia bewaakten de ark.

25David, de leiders van Israël en de hoge officieren gingen toen blij gestemd naar het huis van Obed-Edom om de ark naar Jeruzalem te brengen. 26En omdat de Here de Levieten hielp de ark veilig naar zijn plek te dragen, offerden zij zeven stieren en zeven lammeren. 27David, de Levieten die de ark droegen, de koorleiders en de dirigent Kenanja waren allen gekleed in linnen gewaden. David droeg bovendien nog een linnen lijfrok. 28Zo brachten de leiders van Israël de ark onder gejuich naar Jeruzalem, onder begeleiding van het schallen van bazuinen en trompetten, het rinkelen van cymbalen en met muziek van harp en citer. 29Maar toen de ark in Jeruzalem aankwam, voelde Davids vrouw Michal, de dochter van koning Saul, een diepe minachting voor David. Zij keek namelijk vanuit een raam toe en zag hoe hij huppelde en danste als een blij kind.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 15:1-29

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí Jerusalẹmu

115.1–16.3: 2Sa 6.12-19.Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. 2Nígbà náà Dafidi wí pé, Kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé.

3Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

4Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi péjọ papọ̀:

5Ọgọ́fà nínú àwọn ọmọ Kohati;

Urieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

6Igba ó lé ogún nínú àwọn ọmọ Merari;

Asaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

7Àádóje nínú àwọn ọmọ Gerṣoni;

Joeli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

8Igba nínú àwọn ọmọ Elisafani;

Ṣemaiah olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

9Ọgọ́rin nínú àwọn ọmọ Hebroni;

Elieli olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

10Méjìléláàdọ́fà nínú àwọn ọmọ Usieli;

Amminadabu olórí àti àwọn ẹbí rẹ̀.

11Dafidi sì ránṣẹ́ pe Sadoku, Abiatari tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àti Urieli, Asaiah. Joeli, Ṣemaiah, Elieli àti Amminadabu tí wọ́n jẹ́ Lefi. 12Ó sì fi fún wọn pé, Ẹ̀yin ni olórí àwọn ìdílé Lefi; ẹ̀yin àti àwọn Lefi ènìyàn yín, ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ lè gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, lọ sí ibi tí mó ti pèsè sílẹ̀ fún un. 13Nítorí tí ẹ̀yin ọmọ Lefi kò gbe gòkè wá ní ìgbà àkọ́kọ́ ti Olúwa Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ ko lù wá. Àwa kò sì ṣe ìwádìí lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí a ti ń ṣe é gẹ́gẹ́ bí ọ́nà tí a là sílẹ̀. 14Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, Ọlọ́run Israẹli. 15Nígbà náà ni àwọn Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run pẹ̀lú ọ̀pá ní èjìká wọn gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

16Dafidi sọ fún àwọn olórí àwọn Lefi láti yan àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí akọrin láti kọ orin ayọ̀, pẹ̀lú àwọn ohun èlò orin olókùn, dùùrù, àti símbálì.

17Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; àti nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, àti nínú àwọn ọmọ Merari arákùnrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah; 18àti pẹ̀lú wọn àwọn arákùnrin wọn tí a yàn bí olùrànlọ́wọ́ wọn: Sekariah, Jaasieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Unni, Eliabu, Benaiah, Maaseiah, Mattitiah, Elifelehu, Mikimeiah, àti Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn aṣọ́bodè.

19Àwọn akọrin sì ni Hemani, Asafu, àti Etani ti àwọn ti kimbali idẹ tí ń dún kíkan; 20Sekariah, Asieli, Ṣemiramotu, Jehieli, àti Unni, Eliabu, Maaseiah àti Benaiah àwọn tí ó gbọdọ̀ ta ohun èlò orin olókùn gẹ́gẹ́ bí alamoti, 21Àti Mattitiah, Elifelehu, Mikneiah, Obedi-Edomu, Jeieli àti Asasiah ni ó ní láti ta ohun èlò olóhùn gooro, láti darí gẹ́gẹ́ bí ṣeminiti. 22Kenaniah olórí àwọn ará Lefi ni ó wà ní ìkáwọ́ orin èyí sì ni ojúṣe nítorí ó mòye nípa rẹ̀.

23Berekiah àti Elkana ni kí ó wà gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí. 24Ṣebaniah, Jehoṣafati, Netaneli, Amasai, Sekariah, Benaiah àti Elieseri ní àwọn àlùfáà, tí o ń fún ìpè níwájú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. Obedi-Edomu àti Jehiah ni ó sì gbọdọ̀ jẹ́ olùṣọ́nà fún àpótí ẹ̀rí.

25Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn. 26Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ. 27Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun. 28Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú Olúwa gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro.

29Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.