4. Mose 35 – HOF & YCB

Hoffnung für Alle

4. Mose 35:1-34

Die Städte der Leviten und die Zufluchtsorte für Totschläger

(5. Mose 19,1‒13)

1Die Israeliten lagerten in der moabitischen Steppe östlich des Jordan, gegenüber von Jericho. Dort ließ der Herr ihnen durch Mose sagen:

2-3»Gebt den Leviten in euren Stammesgebieten Städte, in denen sie wohnen können! Überlasst ihnen mit den Städten auch Weideland für ihre Viehherden! 4Die Weidefläche soll sich auf jeder Seite der Stadt 500 Meter weit ins Land erstrecken, 5so dass jede ihrer vier Seiten mindestens einen Kilometer lang ist. 6-7Gebt den Leviten insgesamt 48 Städte! Sechs davon sollen als Zufluchtsorte für Menschen dienen, die ohne Absicht jemanden getötet haben. 8Achtet darauf, dass es bei der Auswahl der Städte gerecht zugeht. Die Stämme mit großen Gebieten sollen mehr Städte abtreten als die Stämme mit weniger Land.«

9Weiter sprach der Herr zu Mose: 10»Sag den Israeliten:

Wenn ihr den Jordan überquert und ins Land Kanaan kommt, 11sollt ihr Zufluchtsstädte bestimmen, in die jeder von euch fliehen kann, der ohne Absicht einen Menschen getötet hat. 12Dort ist er vor der Blutrache sicher, bis ihr den Fall öffentlich vor Gericht untersucht habt. 13Wählt dazu sechs Städte aus, 14drei hier im Osten und drei drüben im Land Kanaan. 15Sie bieten jedem von euch Schutz, auch den Ausländern, die bei euch zu Gast sind oder ständig bei euch leben. Jeder, der unabsichtlich einen Menschen getötet hat, soll dorthin fliehen.

16-18Wer einen anderen aber mit einem Gegenstand aus Metall, Stein oder Holz erschlägt, ist ein Mörder und muss sterben. 19Der nächste Verwandte des Ermordeten soll ihn töten, sobald er ihn findet. 20-21Denn wer aus Hass und Feindschaft einen Menschen erschlägt oder mit einem Wurfgeschoss oder mit der Faust tödlich verletzt, muss auf jeden Fall mit dem Tod bestraft werden.

22Anders ist es, wenn jemand nicht aus Feindschaft, sondern unabsichtlich einen Menschen tötet, indem er ihn aus Versehen zu Boden stößt, mit einem Wurfgeschoss trifft 23oder einen Stein auf ihn fallen lässt. 24In diesem Fall soll die Volksgemeinschaft vor Gericht darüber urteilen, ob der Bluträcher ihn töten darf. Haltet euch dabei an dieses Gesetz! 25Wird der Angeklagte freigesprochen, dann sollt ihr ihn vor der Rache schützen und in die Zufluchtsstadt zurückbringen, in die er geflohen war. Dort muss er bleiben, bis der Hohepriester stirbt, der gerade im Amt ist. 26Wenn der Totschläger aber die Stadt verlassen sollte, in die er geflohen ist, verliert er seinen Schutz. 27Trifft der Bluträcher ihn außerhalb der Stadt an und tötet ihn, dann macht er sich nicht schuldig. 28Denn der Totschläger soll bis zum Tod des Hohenpriesters an seinem Zufluchtsort bleiben. Erst danach kann er nach Hause zu seinem Grund und Boden zurückkehren. 29Dieses Gesetz gilt für euch und eure Nachkommen überall, wo ihr lebt.

30Ein Mörder muss zum Tod verurteilt werden, aber nur dann, wenn mindestens zwei Zeugen gegen ihn aussagen. Eine einzelne Zeugenaussage reicht dazu nicht aus.

31Ein Mörder kann sich nicht freikaufen. Ihr dürft kein Geld von ihm annehmen, sondern müsst ihn auf jeden Fall töten. 32Nehmt auch kein Geld von einem Totschläger an! Er darf sich nicht das Recht erkaufen, seine Zufluchtsstadt zu verlassen und nach Hause zurückzukehren, bevor der Hohepriester gestorben ist.

33Ihr sollt das Land, in dem ihr lebt, nicht entweihen. Entweiht wird es, wenn jemand darin einen anderen Menschen ermordet. Es kann nur dadurch wieder rein werden, dass der Mörder selbst sein Leben lässt. 34Euer Land soll rein sein, denn ich, der Herr, wohne mitten unter euch Israeliten!«

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 35:1-34

Ìlú fún àwọn ọmọ Lefi

135.1-8: Le 25.32-34; Jo 21.1-42.Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní Jordani tí ó rékọjá láti Jeriko, Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti fún àwọn Lefi ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Israẹli yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú. 3Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.

4“Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1,500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà. 5Lẹ́yìn náà, wọn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àríwá. Pẹ̀lú ìlú ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.

Ìlú ààbò

635.6,9-34: De 19.1-13.“Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ibi ìsásí, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì (42) ìlú sí i. 7Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjì-dínláàádọ́ta (48) ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. 8Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.”

935.9-28: De 19.2-4; Jo 20.1-9.Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10“Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani, 11Yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ìsásí fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sálọ síbẹ̀. 12Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má ba à kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́. 13Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín. 14Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jordani, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kenaani tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí. 15Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Israẹli, fún àjèjì àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrín wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sálọ síbẹ̀.

16“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa, apànìyàn náà. 17Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà. 18Tàbí tí ènìyàn bá mú ohun èlò igi ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì lẹ̀ ẹ́ pa ènìyàn, tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni; pípa ní a ó pa apànìyàn náà. 19Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà; tí ó bá bá a, yóò pa á. 20Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú. 21Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.

22“ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe 23tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀tá rẹ̀, láti ṣe é léṣe, 24Àwọn àpéjọ gbọdọ̀ dájọ́ láàrín rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25Àpéjọ gbọdọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì rán an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbọdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi ààmì òróró yàn.

26“ ‘Ṣùgbọ́n ti ẹni tí a fi sùn kan bá jáde kọjá ààlà ìlú ìsásí tí ó sá sí. 27Tí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì ri ní ìta ìlú náà, olùgbẹ̀san lè pa ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn láìjẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn. 28Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà.

29“ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé.

3035.30: De 17.6; 19.15.“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. Kì yóò jẹ́rìí sí ẹnìkan láti pa.

31“ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí apànìyàn, tí ó jẹ̀bi kí ó kú. Ṣùgbọ́n pípa ni kí a pa á.

32“ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.

33“ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Àtúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀. 34Má ṣe sọ di àìmọ́, ilẹ̀ tí ẹ ń gbé, àti èyí tí mo ń gbé, nítorí Èmi Olúwa ń gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.’ ”