התגלות 10 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

התגלות 10:1-11

1לאחר מכן ראיתי מלאך גיבור אחר יורד מן השמים. הוא היה עטוף בענן, ומעל ראשו מעין קשת; פניו זרחו כשמש, רגליו דמו לעמודי אש 2ובידו החזיק ספר קטן פתוח. רגלו הימנית דרכה על הארץ, 3והוא קרא קריאה אדירה כשאגת אריה. בתגובה לקריאתו הרימו שבעת הרעמים את קולם והחלו לדבר.

4בשעה שדיברו שבעת הרעמים רציתי לכתוב את דבריהם, אך שמעתי קול מן השמים שציווה עלי: ”דברי הרעמים הם סוד. אל תעלה אותם על הנייר!“

5המלאך הגיבור, שראיתיו עומד על הים ועל הארץ, הרים את יד ימינו כלפי השמים 6ונשבע בשמו של החי לנצח, האלוהים אשר ברא את השמים, הארץ, הים ואת כל אשר בהם: ”לא יהיה עיכוב נוסף! 7בימי תקיעת המלאך השביעי בשופרו, כאשר יחל לתקוע, יתגלה סודו של אלוהים, כפי שבישר לעבדיו הנביאים.“

8הקול אשר שמעתי מן השמים דיבר אלי שנית: ”לך, קח את הספר הקטן ופתוח מיד המלאך שעומד על הים ועל הארץ.“

9ניגשתי אליו וביקשתי ממנו את הספר. ”קח ואכול אותו“, אמר לי המלאך. ”בפיך יהיה טעמו כדבש, אך לאחר שתבלע אותו הוא יהיה מר בבטנך!“

10לקחתי את הספר מהמלאך ואכלתי אותו. בפי היה טעמו כדבש, אך לאחר שבלעתי אותו כאבה בטני וחשתי במרירות.

11”עליך לשוב ולנבא על ארצות, עמים, שבטים, שפות ומלכים רבים“, אמר אלי המלאך.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 10:1-11

Àwọn angẹli àti ìwé kékeré

1Mó sì rí angẹli mìíràn alágbára ò ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, a fi àwọsánmọ̀ wọ̀ ọ́ ni aṣọ; òṣùmàrè sì ń bẹ ní orí rẹ̀, ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ọ̀wọ́n iná. 2Ó sì ní ìwé kékeré kan tí a ṣí ní ọwọ́ rẹ̀; ó sì fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún lé Òkun, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì lé ilẹ̀. 3Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn. 4Nígbà tí àwọn àrá méje fọhùn, mo múra àti kọ̀wé: mo sì gbọ́ ohùn láti ọ̀run wá ń wí fún pé, “Fi èdìdì di ohun tí àwọn àrá méje náà sọ, má sì ṣe kọ wọ́n sílẹ̀.”

510.5: De 32.40; Da 12.7.Angẹli náà tí mo rí tí ó dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀, sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sí òkè ọ̀run: 6Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, ayé ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ pé, “Kí yóò si ìjáfara mọ́. 7Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn angẹli keje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”

8Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí o ṣí lọ́wọ́ angẹli tí o dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀.”

910.9: El 2.8; 3.1-3.Mo sì tọ angẹli náà lọ, mo sì wí fún pé, “Fún mi ní ìwé kékeré náà.” Ó sì wí fún mi pé, “Gbà kí o sì jẹ ẹ́ tan: yóò dàbí oyin.” 10Mo sì gba ìwé kékeré náà ni ọwọ́ angẹli náà mo sì jẹ ẹ́ tan; ó sì dùn lẹ́nu mi bí oyin; bí mo sì tí jẹ ẹ́ tan, inú mi korò. 1110.11: Jr 1.10.A sì wí fún mi pé, “Ìwọ ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti orílẹ̀ àti èdè, àti àwọn ọba.”