הבשורה על-פי יוחנן 12 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

הבשורה על-פי יוחנן 12:1-50

1ששה ימים לפני חג הפסח שב ישוע לבית־עניה, כפרו של אלעזר שהשיבו לחיים, 2ונערכה לכבודו ארוחת ערב חגיגית. אלעזר ישב עם ישוע בין האורחים, ואילו מרתא שרתה את האורחים. 3מרים לקחה מרקחת יקרה העשויה משמנים ובשמים ריחניים, משחה את רגליו של ישוע וניגבה אותן בשערותיה, ריח הניחוח מילא את כל הבית.

4אחד מתלמידיו אשר עמד להסגירו, יהודה איש קריות שמו, קרא: 5”המרקחת הזאת שווה הרבה כסף! היא הייתה יכולה למכור אותה ולחלק את הכסף לעניים.“ 6הוא לא דיבר מתוך דאגה לעניים, אלא מתוך דאגה לעצמו. יהודה היה הגזבר של קבוצת התלמידים, ולעתים קרובות משך מכספי הקבוצה לצרכיו הפרטיים.

7”הנח לה“, אמר ישוע. ”היא עשתה זאת כהכנה לקבורתי. 8העניים נמצאים אתכם תמיד, ואילו אני איני נמצא אתכם תמיד.“

9יהודים רבים שמעו על ביקורו של ישוע, ועל כן באו לראות אותו ואת אלעזר שהקים לתחייה. 10‏-11בינתיים החליטו ראשי הכוהנים להרוג גם את אלעזר, כי בגללו נהרו למקום יהודים רבים והאמינו שישוע הוא המשיח.

12למחרת התפשטה השמועה בכל העיר שישוע היה בדרכו לירושלים. אנשים רבים מבין החוגגים 13לקחו בידיהם כפות תמרים, הלכו לקראת ישוע וקראו: ”יחי המשיח! יחי מלך ישראל! ברוך הבא בשם ה׳ מלך ישראל!“

14ישוע בא לקראתם רכוב על חמור, ובכך קיים את הנבואה:12‏.14 יב 14 זכריה ט 9 15”אל תיראי, בת ציון, הנה מלכך יבוא לך רוכב על עיר בן אתונות.“

16תחילה לא הבינו תלמידיו שישוע קיים למעשה את הנבואה הזאת, אולם לאחר שישוע נתפאר בכבוד הם נזכרו במעשיו השונים אשר קיימו נבואות רבות מכתבי־הקודש.

17אנשים רבים בקהל אשר ראו את ישוע מקים את אלעזר לחיים, ספרו על כך לאחרים. 18אנשים רבים יצאו לקראתו, כי שמעו על הפלא הגדול שחולל.

19אולם הפרושים היו אובדי עצות. ”רואים אתם, נוצחנו. כל העולם נמשך אחריו!“ קראו. 20בין העולים לירושלים בחג הייתה גם קבוצת יוונים. 21הם הלכו לפיליפוס מבית־צידה שבגליל וביקשו: ”אדוני, אנחנו רוצים לפגוש את ישוע.“ 22פיליפוס מסר את ההודעה ל‎אַנְדְּרֵי, והשניים הלכו להתייעץ עם ישוע.

23”הגיעה השעה שיפואר בן־האדם“, אמר להם ישוע. 24”אני אומר לכם ברצינות: גרגר חיטה שנטמן באדמה צריך למות לפני שיוכל לשאת פרי רב, אחרת יישאר סתם גרגר בודד. 25האוהב את חייו על־פני האדמה – יאבד אותם; והשונא את חייו על־פני האדמה יזכה בחיי נצח.

26”הרוצה להיות תלמידי צריך ללכת בעקבותי, כי המשרתים אותי חייבים להיות במקום שאני נמצא. אלוהים אבי יכבד את כל אלה שהולכים בעקבותי ומשרתים אותי. 27כעת נבהלה נפשי, אולם איני יכול לבקש מאבי שיצילני מגורלי, שהרי לשם כך באתי לעולם. 28אבי, פאר את שמך!“

לפתע נשמע קול מהשמים: ”כבר פארתי ואוסיף לפאר.“ 29כל הנוכחים שמעו את הקול, אולם חלקם חשב שהיה זה קול רעם, וחלקם אמר שמלאך דיבר עם ישוע.

30”הקול הזה היה למענכם ולא למעני“, אמר להם ישוע. 31”עכשיו הגיע מועד משפטו של העולם, ושר העולם הזה (השטן) יגורש. 32וכאשר אנשא מן הארץ אמשוך אלי את כולם.“ 33הוא אמר זאת כדי לרמוז להם כיצד ימות.

34”אולם אנחנו למדנו מהתורה שהמשיח יחיה לנצח ולא ימות לעולם, אם כן מדוע אתה אומר שבן־האדם צריך להנשא מן הארץ? מי בן־האדם הזה?“ שאלו אותו.

35”האור יישאר אתכם עוד זמן קצר בלבד“, אמר ישוע. ”על כן, תנצלו את העובדה הזאת והתהלכו באור כל עוד אתם יכולים, מפני שעם רדת החשכה לא תוכלו למצוא את דרככם. 36האמינו באור לפני שיהיה מאוחר מדי, כדי שגם אתם תהיו בני האור.“ לאחר שסיים את דבריו הלך לדרכו, והם לא ראו אותו. 37על־אף הניסים הרבים שחולל ישוע, אנשים רבים לא האמינו שהוא המשיח. 38הנביא ישעיהו חזה מצב זה כשאמר:12‏.38 יב 38 ישעיהו נג 1 ”ה׳, מי האמין לשמועתנו, וזרוע ה׳ על־מי נגלתה?“ 39לכן הם לא יכלו להאמין. ישעיהו אף ניבא:12‏.39 יב 39 ראה ישעיהו ו 10 40”אלוהים סנוור את עיניהם והקשיח את לבם. משום כך הם אינם יכולים לראות, להבין או לשוב אליו כדי שירפא אותם.“ 41הנביא ישעיהו אמר דברים אלה על ישוע מפני שראה בחזונו את תפארתו.

42מנהיגי יהודים רבים האמינו כי ישוע הוא המשיח, אך לא הודו בזאת בפני איש, כי פחדו שהפרושים יטילו עליהם חרם. 43לאנשים אלה היה חשוב יותר לזכות בכבוד מבני־אדם מאשר מאלוהים.

44”אם אתם מאמינים בי, אתם מאמינים למעשה באלוהים“, קרא ישוע. 45”שהרי כל הרואה אותי רואה למעשה את שולחי. 46באתי להאיר ולזרוח בעולם חשוך זה, כדי שכל המאמין בי לא יתעה יותר בחשכה. 47לא באתי לשפוט את העולם, כי אם להושיעו, ועל כן לא אשפוט את אלה השומעים את דברי ואינם מקיימים אותם. 48דברי האמת שדיברתי ישפטו ביום הדין את כל אלה שדחוני ולעגו לי. 49כי איני מדבר אליכם על דעת עצמי; אני מוסר לכם מה שציווה עלי אבי לומר לכם. 50אני מוסר לכם בדיוק מה שמסר לי אבי, כי אני יודע שמצוותו תביא לכם חיי נצח.“

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 12:1-50

A fi ààmì òróró yàn Jesu ni Betani

112.1-8: Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Lk 7.37-38.Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.

412.4: Jh 6.71; 13.26.Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5“Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 612.6: Lk 8.3.Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.

712.7: Jh 19.40.Nígbà náà ni Jesu wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi. 8Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sá à ní tálákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

9Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. 1012.10: Mk 14.1.Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú; 11Nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.

Jesu gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerusalẹmu

1212.12-15: Mt 21.4-9; Mk 11.7-10; Lk 19.35-38.Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 1312.13: Sm 118.25; Jh 1.49.Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,

“Hosana!”

“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Olùbùkún ni ọba Israẹli!”

14Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

1512.15: Sk 9.9.“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni;

Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,

o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”

1612.16: Mk 9.32; Jh 2.22.Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

17Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ ààmì yìí. 19Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

Jesu sọ nípa ikú rẹ̀

2012.20: Jh 7.35; Ap 11.20.Àwọn Giriki kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ: 2112.21: Jh 1.44; 6.5.Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Filipi wá, ẹni tí í ṣe ará Betisaida tí Galili, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jesu!” 22Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu.

2312.23: Jh 13.1; 17.1; Mk 14.35,41.Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo. 2412.24: 1Kọ 15.36.Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé alikama bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, yóò sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 2512.25: Mt 10.39; Mk 8.35; Lk 9.24; 14.26.Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun. 26Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti pe níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.

2712.27: Jh 11.33; Mt 26.38; Mk 14.34.“Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kín ni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí. 2812.28: Mk 1.11; 9.7.Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”

Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!” 29Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán: àwọn ẹlòmíràn wí pé, “angẹli kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

30Jesu sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín. 3112.31: Jh 16.11; 2Kọ 4.4; Ef 2.2.Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde. 3212.32: Jh 3.14; 8.28.Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé, èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!” 33Ṣùgbọ́n ó wí èyí, ó ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóò kú.

3412.34: Sm 110.4; Isa 9.7; El 37.25; Da 7.14.Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé: ìwọ ha ṣe wí pé, ‘A ó gbé ọmọ ènìyàn sókè? Ta ni ó ń jẹ́ ọmọ ènìyàn yìí’?”

3512.35: Jh 7.33; 9.4; Ef 5.8; 1Jh 2.11.Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà díẹ̀ sí i ni ìmọ́lẹ̀ wà láàrín yín, ẹ máa rìn nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má ṣe bá yín: ẹni tí ó bá sì ń rìn ní òkùnkùn kò mọ ibi òun ń lọ. 3612.36: Lk 16.8; Jh 8.59.Nígbà tí ẹ̀yin ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀!” Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì jáde lọ, ó fi ara pamọ́ fún wọn.

Àwọn júù n tẹ̀síwájú nínú àìgbàgbọ́

37Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. 3812.38: Isa 53.1; Ro 10.16.Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:

“Olúwa, ta ni ó gba ìwàásù wa gbọ́

Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé:

4012.40: Isa 6.10; Mt 13.14.“Ó ti fọ́ wọn lójú,

Ó sì ti sé àyà wọn le;

kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,

kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,

kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

4112.41: Isa 6.1; Lk 24.27.Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

4212.42: Jh 9.22; Lk 6.22.Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu: 43Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.

4412.44: Mt 10.40; Jh 5.24.Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi. 4512.45: Jh 14.9.Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi. 4612.46: Jh 1.4; 8.12; 9.5.Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.

4712.47: Jh 3.17.“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là. 4812.48: Mt 10.14-15.Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. 49Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí. 50Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀: nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”