אגרת פולוס הראשונה אל-הקורנתים 9 – HHH & YCB

Habrit Hakhadasha/Haderekh

אגרת פולוס הראשונה אל-הקורנתים 9:1-27

1האם אינני אדם חופשי? האם אינני שליח האדון? האם לא ראיתי את האדון ישוע במו עיני? האם לא אני הבאתי אתכם לאמונה במשיח? 2אולי לא נשלחתי אל אנשים אחרים, אך ללא ספק נשלחתי אליכם, שהרי באתם לאמונה במשיח באמצעותי.

3זוהי תשובתי למטילים בי ספק. 4האם אין לי בכלל זכויות? האם איני רשאי להתארח בבתיכם כמו השליחים האחרים? 5האם אין לנו זכות לשאת אישה מאמינה, כמו השליחים האחרים ואחי האדון וגם ‎כֵּיפָא? 6האם רק בר־נבא ואני מוכרחים להמשיך לעבוד לפרנסתנו, בעוד שאתם תומכים בכסף בשליחים האחרים? 7איזה חייל משלם מכיסו את הוצאותיו בתפקיד? או האם שמעתם פעם על כורם שאינו רשאי לטעום מהענבים שגידל? איזה רועה אינו רשאי לשתות מעט מחלב העדר שעליו הוא שומר? 8אינני מצטט לכם כללים שהומצאו על־ידי בני־אדם; אני מצטט לכם את דבר ה׳! 9הרי כתוב בתורת משה:9‏.9 ט 9 דברים כה 4 ”לא תחסם שור בדישו“. הסבורים אתם שה׳ חשב רק על השור כשציווה זאת? 10האם לא חשב אלוהים גם עלינו? ברור שכן! אלוהים רצה ללמדנו שהמאמינים שעובדים למען האדון ללא משכורת, צריכים לקבל תמיכה כלכלית מאלה המנצלים את שירותיהם. גם לחורש וגם לקוצר מגיע שכר מהיבול.

11אנחנו זרענו בלבכם זרע רוחני. האם אנו מגזימים בבקשנו בתמורה מעט מזון ובגדים? 12אתם מספקים מזון ובגדים לשליחים האחרים המלמדים אתכם, ואתם נוהגים כהלכה, אך האין זכותנו גדולה משלהם? למרות זאת מעולם לא ניצלנו זכות זאת, אלא סיפקנו בעצמנו את כל צרכינו ללא עזרתכם. מעולם לא דרשנו תמורה, מחשש שבגלל דרישה זאת תפסיקו את התעניינותכם בבשורת המשיח שהבאנו לכם.

13האם אינכם יודעים שאלוהים נתן רשות לעובדי בית־המקדש לקחת לעצמם מה שהם צריכים מבין המנחות שהוקרבו לאלוהים? גם משרתי המזבח מקבלים חלק מהמזון המוקרב לה׳. 14באותה דרך ציווה אלוהים שמטיפי הבשורה יקבלו תמיכה מהשומעים. 15ובכל זאת, מעולם לא ביקשתי מכם אגורה אחת! וגם עכשיו איני מנסה לרמוז לכם במכתבי שברצוני לקבל מהיום והלאה את המגיע לי. למעשה אני מעדיף לגווע ברעב, מאשר לאבד את הסיפוק וההנאה שיש לי מכך שאני מלמד אתכם חינם, ללא כל תשלום או תמורה. 16אין לי סיבה להתפאר בהטפת הבשורה, שכן זוהי חובתי ואוי לי אם לא אבשר אותה.

17אילו הייתי מתנדב מרצוני לשרת את האדון, אולי היה האדון מעניק לי שכר מיוחד. אך מצבי שונה: אלוהים עצמו בחר בי והפקיד בידי את הבשורה, ומשום כך אין לי ברירה. 18מהו שכרי בנסיבות אלה? שכרי הוא השמחה והסיפוק שאני מקבל מהפצת הבשורה בחינם, ללא כל גמול ומבלי לדרוש משהו בחזרה. 19למצב כזה יש יתרון חשוב מאוד: איני חייב דבר לאיש, כי איש אינו משלם לי שכר. ובכל זאת בחרתי מרצוני החופשי להיות עבד לכולם, כדי שאוכל להביא את בני־האדם לאמונה במשיח.

20עם היהודים אני מתנהג כיהודי, כדי שאוכל לרכוש את אמונם ולספר להם על אודות המשיח. אינני מתווכח עם הגרים ששומרים את חוקי התורה, למרות שאיני מסכים איתם, כי ברצוני לעזור להם. 21בהיותי בין הגויים אני משתף איתם פעולה, כל עוד איני עושה דבר שנוגד את אמונתי. כך אני רוחש את אמונם ויכול לעזור להם.

22בהיותי בין אלה שמצפונם מציק להם על כל דבר קטן, איני מתנהג כ”יודע הכול“ ואיני מזלזל בהם. משום כך הם מניחים לי לעזור להם. אתם רואים שאני משתדל למצוא מכנה־משותף עם כל אחד, כדי שאוכל לספר לו על המשיח, וכך יוכל להיוושע. 23מדוע אני טורח כל־כך? – כדי שבני־האדם ישמעו את הבשורה, וכדי שאני עצמי אתברך כאשר אראה אותם באים לאמונה במשיח.

24ידוע לכם שבכל מרוץ יש מתחרים רבים, אבל רק אחד מנצח וזוכה בפרס. רוצו גם אתם כך במטרה לזכות בפרס. 25אם ברצונכם לנצח בתחרות, עליכם להתכחש לעצמכם, ולשכוח את כל מה שעלול להפריע לכם במרוץ. 26לכן אני רץ ישר למטרה, ולכל צעד קדימה יש משמעות גדולה. אני נלחם כדי לנצח. אני מתייחס למרוץ ברצינות רבה ובכובד ראש.

27אני מקשיח על גופי ככל הספורטאים – אני מאמנו לעשות מה שהוא צריך ולא מה שהוא רוצה. אחרת אני חושש שמא, לאחר שהטפתי לאחרים, אני עצמי אפסל ולא אוכל להשתתף במרוץ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 9:1-27

Àwọn ẹ̀tọ́ aposteli

19.1: 1Kọ 9.19; 2Kọ 12.12; 1Tẹ 2.6; Ap 9.3,17; 1Kọ 15.8.Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? 2Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.

3Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. 49.4: 1Kọ 9.14.Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? 59.5: 1Kọ 7.7-8; Mt 12.46; 8.14; Jh 1.42.Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa. 69.6: Ap 4.36.Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?

7Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran? 8Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì? 99.9: De 25.4; 1Tm 5.18.Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi? 109.10: 2Tm 2.6.Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè. 119.11: Ro 15.27.Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara? 129.12: 2Kọ 6.3.Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?

Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìhìnrere Kristi.

139.13: De 18.1.Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ. 149.14: Mt 10.10; Lk 10.7-8.Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìhìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìhìnrere.

159.15: 2Kọ 11.10.Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù. 16Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 179.17: 1Kọ 4.1; Ga 2.7.Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 189.18: 2Kọ 11.7.Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

19Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 209.20: Ro 11.14.Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 219.21: Ro 2.12,14.Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 229.22: 2Kọ 11.29; Ro 15.1; 1Kọ 10.33; Ro 11.14.Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.

249.24: Hb 12.1.Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. 259.25: 2Tm 2.5; 4.8; Jk 1.12; 1Pt 5.4.Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. 26Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú ààmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. 27Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.