Apocalipsis 16 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

Apocalipsis 16:1-21

Las siete copas de la ira de Dios

1Oí una voz que desde el templo decía a gritos a los siete ángeles: «¡Id y derramad sobre la tierra las siete copas del furor de Dios!»

2El primer ángel fue y derramó su copa sobre la tierra, y a toda la gente que tenía la marca de la bestia y que adoraba su imagen le salió una llaga maligna y repugnante.

3El segundo ángel derramó su copa sobre el mar, y el mar se convirtió en sangre como de gente masacrada, y murió todo ser viviente que había en el mar.

4El tercer ángel derramó su copa sobre los ríos y los manantiales, y estos se convirtieron en sangre. 5Oí que el ángel de las aguas decía:

«Justo eres tú, el Santo,

que eres y que eras,

porque juzgas así:

6ellos derramaron la sangre de santos y de profetas,

y tú les has dado a beber sangre, como se merecen».

7Oí también que el altar respondía:

«Así es, Señor Dios Todopoderoso,

verdaderos y justos son tus juicios».

8El cuarto ángel derramó su copa sobre el sol, al cual se le permitió quemar con fuego a la gente. 9Todos sufrieron terribles quemaduras, pero ni así se arrepintieron; en vez de darle gloria a Dios, que tiene poder sobre esas plagas, maldijeron su nombre.

10El quinto ángel derramó su copa sobre el trono de la bestia, y el reino de la bestia quedó sumido en la oscuridad. La gente se mordía la lengua de dolor 11y, por causa de sus padecimientos y de sus llagas, maldecían al Dios del cielo, pero no se arrepintieron de sus malas obras.

12El sexto ángel derramó su copa sobre el gran río Éufrates, y se secaron sus aguas para abrir paso a los reyes del oriente. 13Y vi salir de la boca del dragón, de la boca de la bestia y de la boca del falso profeta tres espíritus malignos que parecían ranas. 14Son espíritus de demonios que hacen señales milagrosas y que salen a reunir a los reyes del mundo entero para la batalla del gran día del Dios Todopoderoso.

15«¡Cuidado! ¡Vengo como un ladrón! Dichoso el que se mantenga despierto, conservando su ropa, no sea que ande desnudo y pase vergüenza por su desnudez».

16Entonces los espíritus de los demonios reunieron a los reyes en el lugar que en hebreo se llama Armagedón.

17El séptimo ángel derramó su copa en el aire, y desde el trono del templo salió una fuerte voz que decía: «¡Ya está hecho!» 18Y hubo relámpagos, estruendos, truenos y un violento terremoto. Nunca, desde que el género humano existe en la tierra, se había sentido un terremoto tan grande y violento. 19La gran ciudad se partió en tres, y las ciudades de las naciones se desplomaron. Dios se acordó de la gran Babilonia y le dio a beber de la copa llena del vino del furor de su castigo. 20Entonces huyeron todas las islas y desaparecieron las montañas. 21Del cielo cayeron sobre la gente enormes granizos, de casi cuarenta kilos cada uno.16:21 granizos … cada uno. Lit. granizos como talentos. Y maldecían a Dios por esa terrible plaga.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 16:1-21

Àwọn ago ìbínú Ọlọ́run

116.1: Isa 66.6; Sm 69.24.Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹmpili wá, ń wí fún àwọn angẹli, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ago ìbínú Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì sí orí ayé.”

216.2: Ek 9.10-11; De 28.35.Èkínní sì lọ, ó sì tú ago tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní ààmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.

316.3-4: Ek 7.17-21.Èkejì sì tú ago sínú Òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alààyè sì kú nínú Òkun.

4Ẹ̀kẹta sì tú ago tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀. 5Mo sì gbọ́ angẹli ti omi wí pé:

“Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ,

tí ó sì ti wà,

nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.

616.6: Sm 79.3.Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,

ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”

716.7: Sm 119.137.Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé:

“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,

òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”

8Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára. 9A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.

1016.10: Ek 10.21.Ẹ̀karùnún sì tú ago tirẹ̀ sórí ìtẹ́ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì ṣókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora. 11Wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.

1216.12: Isa 11.15-16.Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Eufurate; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèsè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà-oòrùn wá. 1316.13: 1Ọb 22.21-23; Ek 8.3.Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dragoni náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá. 14Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.

1516.15: 1Tẹ 5.2.“Kíyèsi i; ń bọ̀ bi olè, ìbùkún ni fún ẹni tí ń ṣọ́nà, tí ó sì ń pa aṣọ rẹ̀ mọ́, kí ó má bá a rìn ni ìhòhò, wọn a sì rí ìtìjú rẹ̀.”

1616.16: 2Ọb 9.27.Ó sì gbá wọn jọ́ sí ibìkan tí a ń pè ní Amagedoni ní èdè Heberu.

1716.17: Isa 66.6.Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 1816.18: Ek 19.16; Da 12.1.Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 2116.21: Ek 9.23.Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.