1 Reyes 2 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

1 Reyes 2:1-46

Últimas instrucciones de David

2:10-121Cr 29:26-28

1David ya estaba próximo a morir, así que le dio estas instrucciones a su hijo Salomón:

2«Según el destino que a todos nos espera, pronto partiré de este mundo. ¡Cobra ánimo y pórtate como un hombre! 3Cumple los mandatos del Señor tu Dios; sigue sus sendas y obedece sus decretos, mandamientos, leyes y preceptos, los cuales están escritos en la ley de Moisés. Así prosperarás en todo lo que hagas y por dondequiera que vayas, 4y el Señor cumplirá esta promesa que me hizo: “Si tus descendientes cuidan su conducta y me son fieles con toda el alma y de todo corazón, nunca faltará un sucesor tuyo en el trono de Israel”.

5»Ahora bien, tú mismo sabes que Joab hijo de Sarvia derramó sangre en tiempo de paz como si estuviera en guerra, y mató a Abner hijo de Ner y a Amasá hijo de Jéter, los dos comandantes de los ejércitos israelitas, manchándose así de sangre las manos.2:5 las manos. Lit. su cinturón y sus sandalias. 6Por tanto, usa la cabeza y no lo dejes llegar a viejo y morir en paz.2:6 no lo dejes llegar a viejo y morir en paz. Lit. no dejes que sus canas bajen en paz al Seol. 7En cambio, sé bondadoso con los hijos de Barzilay de Galaad y permíteles comer a tu mesa, pues ellos me ampararon cuando huía de tu hermano Absalón.

8»También encárgate de Simí hijo de Guerá, ese benjaminita de Bajurín que me lanzó terribles maldiciones cuando me dirigía a Majanayin. Es cierto que, cuando fue al Jordán a recibirme, le juré por el Señor que no lo condenaría a muerte. 9Sin embargo, no tienes ya por qué perdonarle la vida. Tú eres inteligente, y sabrás qué hacer con él; aunque ya es viejo, hazle sufrir una muerte sangrienta».2:9 aunque … sangrienta. Lit. haz que sus canas bajen con sangre al Seol.

10David murió y fue sepultado en la ciudad que lleva su nombre. 11Había reinado siete años en Hebrón y treinta y tres en Jerusalén, así que en total reinó en Israel cuarenta años. 12Le sucedió en el trono su hijo Salomón, y así se consolidó firmemente su reino.

Salomón consolida el reino

13Adonías hijo de Jaguit fue a ver a Betsabé, madre de Salomón, y Betsabé le preguntó:

―¿Vienes en son de paz?

―Sí —respondió él—; 14tengo algo que comunicarte.

―Habla —contestó ella.

15―Como tú sabes —dijo Adonías—, el reino me pertenecía, y todos los israelitas esperaban que yo llegara a ser rey. Pero ahora el reino ha pasado a mi hermano, que lo ha recibido por voluntad del Señor. 16Pues bien, tengo una petición que hacerte, y espero que me la concedas.

―Continúa —dijo ella.

17―Por favor, pídele al rey Salomón que me dé como esposa a Abisag la sunamita; a ti no te lo negará.

18―Muy bien —contestó Betsabé—; le hablaré al rey en tu favor.

19Betsabé fue a ver al rey Salomón para interceder en favor de Adonías. El rey se puso de pie para recibirla y se inclinó ante ella; luego se sentó en su trono y mandó que pusieran otro trono para su madre; y ella se sentó a la derecha del rey.

20―Quiero pedirte un pequeño favor —dijo ella—. Te ruego que no me lo niegues.

―Dime de qué se trata, madre mía. A ti no puedo negarte nada.

21Ella continuó:

―Concédele a tu hermano Adonías casarse con Abisag la sunamita.

22―Pero ¿cómo puedes pedirme semejante cosa? —respondió el rey a su madre—. Es mi hermano mayor, y cuenta con el apoyo del sacerdote Abiatar y de Joab hijo de Sarvia. ¡Realmente me estás pidiendo que le ceda el trono!

23Dicho esto, el rey Salomón juró por el Señor: «¡Que Dios me castigue sin piedad si no hago que Adonías pague con su vida por esa petición! 24El Señor me ha establecido firmemente en el trono de mi padre, y conforme a su promesa me ha dado una dinastía. Por tanto, tan cierto como que él vive, ¡juro que hoy mismo Adonías morirá!»

25En seguida, el rey Salomón le dio a Benaías hijo de Joyadá la orden de matar a Adonías. 26Al sacerdote Abiatar, el rey mismo le ordenó: «Regresa a tus tierras en Anatot. Mereces la muerte, pero por el momento no voy a quitarte la vida, pues compartiste con David mi padre todas sus penurias, y en su presencia llevaste el arca del Señor omnipotente». 27Fue así como, al destituir Salomón a Abiatar del sacerdocio del Señor, se cumplió la palabra que el Señor había pronunciado en Siló contra la familia de Elí.

28Joab había conspirado con Adonías, aunque no con Absalón, así que, al oír que Adonías había muerto, fue a refugiarse en el santuario del Señor, agarrándose de los cuernos del altar. 29Cuando le dijeron a Salomón que Joab había huido al santuario, y que estaba junto al altar, el rey le ordenó a Benaías hijo de Joyadá que fuera a matarlo. 30Benaías fue al santuario del Señor y le dijo a Joab:

―El rey te ordena que salgas.

―¡No! —respondió Joab—. ¡De aquí solo me sacarás muerto!

Benaías fue y le contó al rey lo que había dicho Joab.

31―¡Pues dale gusto! —ordenó el rey—. ¡Mátalo y entiérralo! De ese modo me absolverás a mí y a mi familia de la sangre inocente que derramó Joab. 32El Señor hará recaer sobre su cabeza la sangre que derramó, porque a espaldas de mi padre atacó Joab a Abner hijo de Ner, que era comandante del ejército de Israel, y a Amasá hijo de Jéter, que era comandante del ejército de Judá. Así mató a filo de espada a dos hombres que eran mejores y más justos que él. 33¡Que la culpa de esas muertes recaiga para siempre sobre la cabeza de Joab y de sus descendientes! ¡Pero que la paz del Señor permanezca para siempre con David y sus descendientes, y con su linaje y su trono!

34Benaías hijo de Joyadá fue y mató a Joab, e hizo que lo sepultaran en su hacienda de la estepa. 35Entonces el rey puso a Benaías hijo de Joyadá sobre el ejército en lugar de Joab, y al sacerdote Sadoc lo puso en lugar de Abiatar. 36Luego mandó llamar a Simí y le dijo:

―Constrúyete una casa en Jerusalén, y quédate allí. No salgas a ninguna parte, 37porque el día que salgas y cruces el arroyo de Cedrón, podrás darte por muerto. Y la culpa será tuya.

38―De acuerdo —le respondió Simí al rey—. Yo estoy para servir a mi señor el rey, y acataré tus órdenes.

Simí permaneció en Jerusalén por un buen tiempo, 39pero tres años más tarde dos de sus esclavos escaparon a Gat, donde reinaba Aquis hijo de Macá. Cuando le avisaron a Simí que sus esclavos estaban en Gat, 40aparejó su asno y se fue allí a buscarlos y traerlos de vuelta. 41Al oír Salomón que Simí había ido de Jerusalén a Gat y había regresado, 42lo mandó llamar y le dijo:

―Yo te hice jurar por el Señor, y te advertí: “El día que salgas a cualquier lugar, podrás darte por muerto”. Y tú dijiste que estabas de acuerdo y que obedecerías. 43¿Por qué, pues, no cumpliste con tu juramento al Señor ni obedeciste la orden que te di?

44El rey también le dijo a Simí:

―Tú bien sabes cuánto daño le hiciste a mi padre David; ahora el Señor se vengará de ti por tu maldad. 45En cambio, yo seré bendecido, y el trono de David permanecerá firme para siempre en presencia del Señor.

46Acto seguido, el rey le dio la orden a Benaías hijo de Joyadá, y este fue y mató a Simí. Así se consolidó el reino en manos de Salomón.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Ọba 2:1-46

Dafidi pàṣẹ fún Solomoni

1Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀.

2Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, 3kí o sì wòye ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, 4Olúwa kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’

5“Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí Balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara Sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 6Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà.

7“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ.

8“Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé: ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.”

10Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. 11Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún (40), ọdún méje (7) ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ní Jerusalẹmu. 122.12: 1Ki 29.23.Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

Ìtẹ́ ọba Solomoni fìdímúlẹ̀

13Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”

Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” 14Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”

Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.”

15Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Olúwa wá. 16Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ó wí pé, “O lè wí.”

17Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (Òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.”

18Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”

19Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

20Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.”

Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.”

21Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.”

22Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!”

23Nígbà náà ni Solomoni ọba fi Olúwa búra pé: “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! 24Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé Olúwa wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” 25Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú.

26Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” 27Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.

28Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 29A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”

30Benaiah sì wọ inú àgọ́ Olúwa, ó sì wí fún Joabu pé, “ọba sọ wí pé, Jáde wá.”

Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Èmi yóò kú níhìn-ín.”

Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.”

31Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. 32Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnrarẹ̀ lọ. 33Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.”

34Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari.

36Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. 37Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá Àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.”

38Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

39Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” 40Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati.

41Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà, 42Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’ 43Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra Olúwa mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?”

44Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, Olúwa yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ. 45Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú Olúwa títí láéláé.”

46Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣimei, ó sì pa á.

Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Solomoni.