1 Crónicas 4 – CST & YCB

Nueva Versión Internacional (Castilian)

1 Crónicas 4:1-43

Descendientes de Judá

1Los descendientes de Judá en línea directa fueron Fares, Jezrón, Carmí, Jur y Sobal. 2Reaías hijo de Sobal fue el padre de Yajat, y Yajat fue el padre de Ajumay y de Lajad. Estas fueron las familias de los zoratitas.

3Los hijos4:3 Los hijos (mss. de LXX); El padre (TM). de Etam fueron Jezrel, Ismá e Idbás. La hermana de ellos fue Jazelelponi. 4También fueron sus hijos Penuel, padre de Guedor, y Ezer, padre de Jusá. Estos fueron los descendientes de Jur, primogénito de Efrata, padre4:4 padre. Alt. fundador (también en vv. 5,12,14,17,18,21). de Belén.

5Asur, padre de Tecoa, tuvo dos esposas, Helá y Nara. 6Nara fue la madre de Ajusán, Héfer, Temeni y Ajastarí. Estos fueron los hijos de Nara.

7Los hijos de Helá fueron Zéret, Yezojar y Etnán.

8Cos fue el padre de Anub, de Zobebá y de las familias de Ajarjel hijo de Harún.

9Jabés fue más importante que sus hermanos. Cuando su madre le puso ese nombre, dijo: «Con aflicción lo he dado a luz».4:9 En hebreo, Jabés suena como la palabra que significa dolor o aflicción. 10Jabés le rogó al Dios de Israel: «Bendíceme y ensancha mi territorio; ayúdame y líbrame del mal, para que no padezca aflicción». Y Dios le concedió su petición.

11Quelub, hermano de Sujá, fue el padre de Mejir, y Mejir fue el padre de Estón; 12Estón fue el padre de Bet Rafá, de Paseaj y de Tejiná, padre de Ir Najás.4:12 Ir Najás. Alt. la ciudad de Najás. Estos fueron los habitantes de Reca.

13Los hijos de Quenaz fueron Otoniel y Seraías.

Los hijos de Otoniel fueron Jatat 14y Meonotay, padre de Ofra.

Seraías fue el padre de Joab, padre de Ge Carisín,4:14 de Ge Carisín. Alt. del valle de Carisín. (La palabra carisín significa herreros). porque sus habitantes eran herreros.

15Los hijos de Caleb hijo de Jefone fueron Iru, Elá y Naán. Elá fue el padre de Quenaz.

16Los hijos de Yalelel fueron Zif, Zifá, Tirías y Asarel.

17Los hijos de Esdras fueron Jéter, Méred, Éfer y Jalón. Una de las esposas de Méred —con la cual tuvo a Miriam, Samay e Isba, padre de Estemoa— 18era Bitiá, hija del faraón. La otra esposa de Méred era de la tribu de Judá, y con ella tuvo a Jéred, padre de Guedor, a Héber, padre de Soco, y a Jecutiel, padre de Zanoa.

19Queilá, el garmita, y Estemoa, el macateo, fueron hijos de la esposa de Hodías, es decir, de la hermana de Naján.

20Los hijos de Simón fueron Amnón, Riná, Ben Janán y Tilón.

Los hijos de Isí fueron Zojet y Ben Zojet.

21Los descendientes de Selá hijo de Judá fueron Er, padre de Lecá; Ladá, padre de Maresá y de las familias que trabajan el lino en Bet Asbea; 22también descendientes de Selá fueron Joaquín, y los habitantes de Cozebá, Joás y Saraf, quienes (según crónicas muy antiguas) antes de volver a Belén4:22 antes de volver a Belén (véanse LXX y Vulgata); en TM, texto de difícil traducción. se casaron con mujeres moabitas.4:22 se casaron con mujeres moabitas. Alt. dominaron en Moab. 23Estos eran alfareros que habitaban en Netaín y Guederá, donde se quedaron al servicio del rey.

Descendientes de Simeón

4:28-33Jos 19:2-9

24Los descendientes de Simeón fueron Nemuel, Jamín, Jarib, Zera y Saúl. 25El hijo de Saúl fue Salún, el de Salún, Mibsán, y el de Mibsán, Mismá.

26Los descendientes de Mismá en línea directa fueron Jamuel, Zacur y Simí. 27Simí tuvo dieciséis hijos y seis hijas; pero sus hermanos tuvieron pocos hijos, por lo cual sus familias no fueron tan numerosas como las de los descendientes de Judá. 28Se establecieron en Berseba, Moladá, Jazar Súal, 29Bilhá, Esen, Tolad, 30Betuel, Jormá, Siclag, 31Bet Marcabot, Jazar Susín, Bet Biray y Sajarayin. Estas fueron sus ciudades hasta el reinado de David. 32Sus aldeas fueron Etam, Ayin, Rimón, Toquén y Asán —cinco en total—, 33más todas las aldeas que estaban alrededor de aquellas ciudades hasta la región de Baal. Estos fueron los lugares que habitaron, según sus registros genealógicos.

34Mesobab, Jamlec, Josías hijo de Amasías, 35Joel, Jehú hijo de Josibías, hijo de Seraías, hijo de Asiel; 36Elihoenay, Jacoba, Yesojaías, Asaías, Adiel, Jesimiel, Benaías, 37Ziza hijo de Sifi, hijo de Alón, hijo de Jedaías, hijo de Simri, hijo de Semaías: 38todos estos eran jefes de sus clanes. Como sus familias patriarcales llegaron a ser muy numerosas, 39fueron hasta la entrada de Guedor, al este del valle, en busca de pastos para sus ganados. 40Allí encontraron pastos buenos y abundantes, y una tierra extensa, tranquila y pacífica. En ese lugar habían vivido los descendientes de Cam. 41Los jefes mencionados anteriormente llegaron en los días de Ezequías, rey de Judá. Atacaron los campamentos de los descendientes de Cam y las viviendas4:41 las viviendas. Alt. los meunitas. que encontraron, y los destruyeron por completo. Y, como en esa región había pastos para sus ganados, se quedaron allí en lugar de ellos, donde habitan hasta el día de hoy. 42Quinientos de sus soldados, que eran descendientes de Simeón y estaban bajo las órdenes de Pelatías, Nearías, Refaías y Uziel, hijos de Isí, fueron a la montaña de Seír. 43Después de destruir a los fugitivos del pueblo de Amalec que habían quedado, se establecieron allí, donde habitan hasta el día de hoy.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 4:1-43

Ìran Juda

1Àwọn ọmọ Juda:

Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.

2Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.

3Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu:

Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi 4Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.

5Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.

6Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.

7Àwọn ọmọ Hela:

Sereti Sohari, Etani, 8Àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.

9Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.” 10Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.

11Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni. 12Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.

13Àwọn ọmọ Kenasi:

Otnieli àti Seraiah.

Àwọn ọmọ Otnieli:

Hatati àti Meonotai. 14Meonotai sì ni baba Ofira.

Seraiah sì jẹ́ baba Joabu,

baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.

15Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne:

Iru, Ela, àti Naamu.

Àwọn ọmọ Ela:

Kenasi.

16Àwọn ọmọ Jehaleeli:

Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.

17Àwọn ọmọ Esra:

Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni.

Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.

18Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.

19Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu:

Baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.

20Àwọn ọmọ Ṣimoni:

Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni.

Àwọn ọmọ Iṣi:

Soheti àti Beni-Soheti.

21Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda:

Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.

22Jokimu, ọkùnrin Koṣeba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́). 23Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.

Simeoni

244.24: Gẹ 46.10; Ek 6.15; Nu 26.12,13.Àwọn Ọmọ Simeoni:

Nemueli, Jamini, Jaribi, Sera àti Saulu;

25Ṣallumu sì jẹ́ ọmọ Saulu, Mibsamu ọmọ rẹ̀ Miṣima ọmọ rẹ̀.

26Àwọn ọmọ Miṣima:

Hamueli ọmọ rẹ̀ Sakkuri ọmọ rẹ̀ àti Ṣimei ọmọ rẹ̀.

27Ṣimei sì ní ọmọkùnrin mẹ́rìn-dínlógún àti ọmọbìnrin mẹ́fà, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin kò ní ọmọ púpọ̀; Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìdílé wọn kò sì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Juda. 284.28-33: Jo 19.2-8.Wọ́n sì ń gbé ní Beerṣeba, Molada, Hasari-Ṣuali, 29Àti ní Biliha, àti ní Esemu, àti ní Toladi, 30Betueli, Horma, Siklagi, 31Beti-Markaboti Hormah; Hasari Susimu, Beti-Biri àti Ṣaraimi. Àwọn wọ̀nyí ni ìlú wọn títí di ìgbà ọba Dafidi, 32agbègbè ìlú wọn ni Etamu, Aini, Rimoni, Tokeni, Aṣani àwọn ìlú márùn-ún, 33àti gbogbo ìletò wọn, tí ó wà yí ìlú náà ká, dé Baali. Àwọn wọ̀nyí ni ibùgbé wọn.

Àti ìtàn ìdílé wọ́n.

34Meṣobabu àti Jamleki,

Josa ọmọ Amasiah, 35Joeli,

Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

36àti pẹ̀lú Elioenai, Jaakoba, Jeṣohaiah,

Asaiah, Adieli, Jesimieli, Benaiah,

37àti Sisa ọmọ Ṣifi ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah.

38Àwọn ọkùnrin tí a dárúkọ lókè yìí àwọn ni ìjòyè ìdílé wọn.

Àwọn ìdílé sì pọ̀ sí i gidigidi, 39Wọ́n sì lọ sí ojú ọ̀nà Gedori. Lọ títí dé ìlà-oòrùn àfonífojì láti wá koríko fún àwọn agbo ẹran wọn 40Wọ́n sì rí koríko tútù tí ó dára ilẹ̀ náà gbòòrò ó sì ní àlàáfíà ó sì gbé jẹ́. Àwọn ọmọ Hamu ni ó ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

41Àwọn ọkùnrin tí a kọ orúkọ rẹ̀ sókè, dé ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Wọ́n sì kọlu àwọn ará Hamu ní àgọ́ wọn àti pẹ̀lú àwọn ará Mehuni tí a rí níbẹ̀ tí ó sì pa wọ́n run pátápátá títí di òní yìí. Wọ́n sì ń gbé ní ipò wọn, nítorí pé koríko ń bẹ níbẹ̀ fún agbo ẹran wọn. 42Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ará Simeoni, lábẹ́ ìdarí pẹ̀lú Pelatiah, Neariah, Refaiah àti Usieli, àwọn ọmọ Iṣi, gbógun sí àwọn òkè ìlú ti Seiri. 43Wọ́n sì pa àwọn ará Amaleki tí ó kù, àwọn tí ó ti sálà, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.