Matej 3 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

Matej 3:1-17

Propovijedanje Ivana Krstitelja

1U to vrijeme Ivan Krstitelj počne propovijedati u judejskoj pustinji: 2“Pokajte se za grijehe i obratite se Bogu jer je nebesko kraljevstvo blizu!” 3Prorok Izaija govorio je o Ivanu kad je prorokovao:

“On je glas koji viče u pustinji:

‘Pripremite put za Gospodnji dolazak!

Poravnajte za njega staze!’”3:3 Izaija 40:3.

4Ivanova odjeća bila je istkana od devine dlake, a bio je opasan kožnim pojasom. Hranio se skakavcima i divljim medom. 5Ljudi su k njemu dolazili iz Jeruzalema i iz cijele jordanske okolice. 6Ispovijedali su mu svoje grijehe, a on ih je krstio u rijeci Jordanu.

7Ali kad ugleda mnoge farizeje i saduceje da se dolaze krstiti, reče im: “Zmijska legla! Tko li vas je samo upozorio da pobjegnete Božjemu gnjevu koji stiže? 8Dokažite svojim životom i djelima da ste se odvratili od grijeha i obratili Bogu.3:8 U grčkome: Rodite dakle plodom dostojnim obraćenja. 9Ne zavaravajte se da vam je dovoljno reći: ‘Mi smo Abrahamovi potomci!’ jer vam kažem da Bog može i od ovoga kamenja podignuti Abrahamovu djecu! 10Sjekira Božjeg suda već je uzdignuta da u korijenu sasiječe stabla. Svako stablo koje ne daje dobrog roda bit će posječeno i bačeno u vatru.

11Ja vodom krstim one koji se pokaju od svojih grijeha; no dolazi netko veći od mene, toliko velik da mu ja nisam dostojan ni robom biti.3:11 U grčkome: ni ponijeti sandale. On će vas krstiti Svetim Duhom i ognjem. 12Očistit će svoje gumno i odvojiti pljevu od pšenice; pšenicu će spremiti u svoju žitnicu, a pljevu sažeći neugasivim ognjem.”

Isusovo krštenje

(Mk 1:9-11; Lk 3:21-22; Iv 1:32-34)

13Tada Isus dođe iz Galileje na Jordan da ga Ivan krsti. 14Ivan ga je odvraćao. “Zar da ti dođeš k meni,” reče mu, “a zapravo bi ti mene trebao krstiti!”

15Ali Isus mu odgovori: “Pusti to, jer nam valja ispuniti pravednu Božju volju.” Tada ga je Ivan krstio.

16Nakon krštenja Isus iziđe iz vode. I gle! Nebesa se otvore i on ugleda Božjega Duha kako silazi kao golub i spušta se na njega. 17Začuje se glas:: “Ovo je moj ljubljeni Sin. On je moja radost!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 3:1-17

Johanu onítẹ̀bọmi tún ọnà náà ṣe

13.1-12: Mk 1.3-8; Lk 3.2-17; Jh 1.6-8,19-28.Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea. 23.2: Mt 4.17; Da 2.44; 4.17; Mt 10.7.Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” 3Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé:

“Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù,

‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,

ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”

43.4: 2Ọb 1.8; Sk 13.4; Le 11.22.Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. 5Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani. 6Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani.

73.7: Mt 12.34; 23.33; 1Tẹ 1.10.Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn Farisi àti Sadusi tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. 93.9: Jh 8.33; Ro 4.16.Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún Abrahamu. 103.10: Mt 7.19.Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná.

11“Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. 123.12: Mt 13.30.Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

Ìtẹ̀bọmi Jesu

133.13-17: Mk 1.9-11; Lk 3.21-22; Jh 1.31-34.Nígbà náà ni Jesu ti Galili wá sí odò Jordani kí Johanu bá à lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un. 14Ṣùgbọ́n Johanu kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ìbá bamitiisi fún mi, ìwọ sì tọ̀ mí wá?”

15Jesu sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Johanu gbà, ó sì ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

16Bí ó si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún Jesu tán, Ó jáde láti inú omi. Ní àkókò náà ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún un, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, ó sì bà lé e. 173.17: Mt 12.18; 17.5; Mk 9.7; Lk 9.35; Sm 2.7; Isa 42.1.Ohùn kan láti ọ̀run wá sì wí pé, “Èyí sì ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”