2 Korinćanima 7 – CRO & YCB

Knijga O Kristu

2 Korinćanima 7:1-16

1Budući da imamo ta obećanja, dragi moji, očistimo se od svega što prlja naše tijelo i naš duh. Trudimo se biti što je više moguće svetima, u strahu Božjemu.

Pavao se raduje pokajanju Crkve

2Otvorite za nas srca jer nikome od vas nismo nanijeli zla, nikoga nismo zaveli na krivi put, niti smo koga na prevaru iskoristili. 3Ne kažem vam to da bih vas osuđivao. Rekao sam vam već da ste zauvijek u našemu srcu. Živimo i umiremo s vama. 4Čvrsto se u vas pouzdajem i veoma se ponosim vama. Uvelike ste me utješili unatoč svoj našoj nevolji. Silno se radujem.

5Kad smo stigli u Makedoniju, nije bilo odmora za naša slaba ljudska bića. Sa svih su nas strana, naprotiv, snašle nevolje: izvana sukobi, a iznutra tjeskoba. 6Ali nas je Bog, koji tješi potištene, utješio Titovim dolaskom. 7Ne samo njegovim dolaskom nego i ohrabrenjem koje ste mu pružili. Kad nam je kazao o vašoj velikoj želji da vas posjetim, o tome koliko ste žalosni zbog onoga što se dogodilo i o vašoj žarkoj ljubavi prema meni, još sam se više razveselio.

8Nije mi više žao što sam vam napisao ono pismo, iako mi je bilo žao jer znam da sam vas njime nakratko ražalostio. 9Ali sada se radujem—ne što sam vas ražalostio, već zato što vas je ta žalost navela na pokajanje. Bila je to žalost po Božjoj volji, pa vam tako nismo nanijeli nikakvu štetu. 10Božja žalost donosi pokajanje koje vodi spasenju, kao što žalost ovoga svijeta vodi u smrt. 11Pogledajte samo kakvu je gorljivost proizvela u vama ta žalost po Božjoj volji! Takvo opravdavanje! Takvo negodovanje, takav strah! Toliku čežnju! Toliki žar! Toliku želju da se krivac kazni! Postupili ste najispravnije što ste mogli. 12Nisam vam pisao ni radi prijestupnika ni radi onoga kome je nanesena nepravda, već zato da pred Bogom pokažete svoju žarku ljubav prema nama.

13Uz to ohrabrenje posebno smo se razveselili i Titovoj radosti zbog toga što ste ga umirili da ne bude zabrinut. 14Ja sam vas i prije pred njim hvalio i niste me postidjeli. Kao što sam vama govorio istinu, tako se i ono čime sam se hvalio pred Titom pokazalo istinitim. 15Njegovo je srce prema vama još otvorenije kad se prisjeti kako ste ga primili s velikim poštovanjem, duboko zabrinuti. 16Radujem se što se u svemu mogu pouzdati u vas.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 7:1-16

1Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ayọ̀ Paulu

27.2: 2Kọ 6.12-13.Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. 37.3: 2Kọ 6.11-12.Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. 4Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.

57.5: 2Kọ 2.13; 4.8.Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. 67.6: 2Kọ 2.13; 7.13-14.Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; 7Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

87.8: 2Kọ 2.2.Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. 9Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. 10Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. 11Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà. 127.12: 2Kọ 7.8; 2.3,9.Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run. 13Nítorí náà, a tí fi ìtùnú yín tù wá nínú.

Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Titu ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára. 14Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójútì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Titu sì jásí òtítọ́. 15Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń rántí ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á. 16Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.