馬太福音 4 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

馬太福音 4:1-25

耶穌受試探

1後來,耶穌被聖靈帶到曠野,去受魔鬼的試探。 2耶穌禁食了四十晝夜後,很饑餓。 3試探者前來對祂說:「如果你是上帝的兒子,可以叫這些石頭變成食物。」

4耶穌回答說:「聖經上說,『人活著不是單靠食物,乃是靠上帝口中的每一句話。』」

5魔鬼又帶祂進聖城,讓祂站在聖殿的最高處, 6說:「如果你是上帝的兒子,就跳下去吧!因為聖經上說,『上帝會差遣祂的天使用手托住你,不讓你的腳碰在石頭上。』」

7耶穌回答說:「聖經上也說,『不可試探主——你的上帝。』」

8魔鬼再帶耶穌到一座極高的山上,把世上萬國及其榮華富貴展示給祂看, 9說:「如果你俯伏敬拜我,我就把這一切都給你。」

10耶穌說:「撒旦,走開!聖經上說,『要敬拜主——你的上帝,單單事奉祂。』」

11於是魔鬼離開了耶穌,這時有天使前來伺候祂。

開始傳道

12耶穌聽見約翰被捕入獄,就回到加利利13後來,祂離開拿撒勒迦百農住。迦百農靠近湖邊,在西布倫拿弗他利地區。 14這就應驗了以賽亞先知的話:

15西布倫拿弗他利

沿海一帶及約旦河東、外族人居住的加利利啊!

16你們住在黑暗中的人看見了大光,

活在死亡陰影下的人被光照亮了!」

17從那時起,耶穌開始傳道:「悔改吧,因爲天國臨近了!」

呼召門徒

18耶穌沿著加利利湖邊行走的時候,看見被稱為彼得西門安得烈兩兄弟正在撒網打魚,他們是漁夫。 19耶穌對他們說:「來跟從我!我要使你們成為得人的漁夫。」 20他們立刻撇下漁網,跟從了耶穌。 21耶穌再往前走,又看見雅各約翰兩兄弟正和父親西庇太一起在船上補漁網。耶穌呼召他們, 22他們馬上離開漁船,辭別父親,跟從了耶穌。

教導和醫治

23耶穌走遍加利利,在各個會堂裡教導人,宣講天國的福音,醫治人們各樣的疾病。 24祂的名聲傳遍了整個敘利亞。人們把一切患病的,就是患各種疾病的、疼痛的、癲癇的、癱瘓的,以及被鬼附身的都帶到祂面前,祂都醫治了他們。 25因此,有大群的人跟從了祂,他們來自加利利低加坡里耶路撒冷猶太約旦河東。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 4:1-25

Ìdánwò Jesu

14.1-11: Mk 1.12-13; Lk 4.1-13; Hb 2.18; 4.15.Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. 24.2: El 34.28; 1Ọb 19.8.Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. 3Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

44.4: De 8.3.Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

54.5: Mt 27.53; Ne 11.1; Da 9.24; If 21.10.Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 64.6: Sm 91.11-12.Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ

wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn

kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

74.7: De 6.16.Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

8Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

104.10: De 6.13; Mk 8.33.Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

114.11: Mt 26.53; Lk 22.43.Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wàásù

124.12: Mk 1.14; Lk 4.14; Mt 14.3; Jh 1.43.Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 134.13: Jh 2.12; Mk 1.21; Lk 4.23.Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:

154.15: Isa 9.1-2.“ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali

ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,

Galili ti àwọn kèfèrí.

16Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn

tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,

àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú

ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

174.17: Mk 1.15; Mt 3.2; 10.7.Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́

184.18-22: Mk 1.16-20; Lk 5.1-11; Jh 1.35-42.Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

21Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Jesu ṣe ìwòsàn

234.23-25: Mk 1.39; Lk 4.15,44; Mt 9.35; Mk 3.7-8; Lk 6.17.Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.