路加福音 21 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

路加福音 21:1-38

窮寡婦的奉獻

1耶穌抬頭觀看,見有錢人正把捐項投進奉獻箱裡, 2又見一個窮寡婦投進兩個小銅錢, 3就說:「我實在告訴你們,這位窮寡婦奉獻的比其他人都多。 4因為他們不過奉獻了自己剩餘的,但這窮寡婦卻奉獻了她賴以為生的一切。」

預言將來的事

5有些人正在談論由精美的石頭和珍貴的供物所裝飾的聖殿, 6耶穌說:「你們現在所見到的,將來有一天要被完全拆毀,找不到兩塊疊在一起的石頭。」

7他們問:「老師,這些事什麼時候會發生呢?發生的時候有什麼預兆呢?」

8耶穌回答說:「你們要小心提防,不要被迷惑。因為將來會有許多人冒我的名來,說,『我就是基督』,或說,『時候到了』,你們切勿跟從他們。 9你們聽見打仗和叛亂的事,不要害怕,因為這些事一定會先發生,但末日將不會立刻來臨。」

10耶穌接著說:「民族將與民族互鬥,國家將與國家相爭, 11將有大地震,各處將有饑荒和瘟疫,天上也將出現恐怖的景象和大異兆。

12「這些事情出現之前,人們要拘捕你們,迫害你們,把你們押到會堂和監牢,你們將為了我的名而被君王和官長審問。 13那時,正是你們為我做見證的好機會。 14你們要立定心志,不要為怎樣申辯而憂慮, 15因為我會賜給你們口才、智慧,使你們的仇敵全無反駁的餘地。 16你們將被父母、弟兄、親戚、朋友出賣,你們有些人會被他們害死。 17你們將為我的名而被眾人憎恨, 18但你們連一根頭髮也不會失落。 19你們只要堅忍到底,必能保全自己的靈魂。

20「你們看見耶路撒冷被重兵包圍時,就知道它被毀滅的日子快到了。 21那時,住在猶太地區的人要趕快逃到山上去,住在城裡的人要跑到城外,住在鄉村的人不要進城, 22因為那是報應的日子,要應驗聖經的全部記載。 23那時,孕婦和哺育嬰兒的母親們可就遭殃了!因為將有大災難降在這地方,烈怒要臨到這些人民。 24他們要死在刀劍之下,要被擄到外國去。耶路撒冷要被外族人蹂躪,直到外族人肆虐的日期滿了為止。

25「日月星辰必顯出異兆,怒海洶湧、波濤翻騰,令各國驚恐不安。 26天體必震動,人類想到世界要面臨的事都嚇得魂不附體。 27那時,他們要看見人子駕著雲、帶著能力和極大的榮耀降臨。 28當這些事發生時,你們要昂首挺胸,因為你們蒙救贖的日子近了。」

警醒禱告

29耶穌又講了一個比喻:「看看無花果樹和其他樹木吧。 30當你們看見樹木發芽長葉時,就知道夏天近了。 31同樣,當你們看見這些事情發生時,就知道上帝的國近了。

32「我實在告訴你們,這個世代還沒有過去,這一切都要發生。 33天地都要消逝,但我的話永不消逝。

34「你們要小心,不要被宴樂、醉酒和人生的掛慮所拖累,免得那日子像網羅般突然臨到你們, 35因為那日子將要這樣臨到世上每一個人。 36你們要時刻警醒,常常禱告,使你們能逃過這一切將要發生的災難,並能站在人子面前。」

37耶穌每天在聖殿裡講道,晚上則到城外的橄欖山上過夜。 38百姓一早都趕去聖殿聽祂的教導。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Luku 21:1-38

Oore opó

121.1-4: Mk 12.41-44.Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. 2Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. 3Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: 4Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”

Àwọn ààmì ìkẹyìn ayé

521.5-23: Mt 24.1-19; Mk 13.1-17.Bí àwọn kan sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa tẹmpili, bí a ti fi òkúta dáradára àti ẹ̀bùn ṣe é ní ọ̀ṣọ́, fun Ọlọ́run, Jesu wí pé 621.6: Lk 19.43-44; Mk 14.58; 15.29; Ap 6.14.“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

721.7: Lk 17.20; Ap 1.6.Wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti ààmì kín ni yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”

821.8: Lk 17.23; Mk 13.21; 1Jh 2.18.Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má bá à mú yín ṣìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kristi náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn. 9Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”

1021.10: 2Ki 15.6; Isa 19.2.Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba. 11Ilẹ̀-rírì ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ohun ẹ̀rù, àti ààmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.

1221.12-17: Mt 10.17-21.21.12: Ap 25.24; Jh 16.2.“Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí Sinagọgu, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi. 1321.13: Fp 1.12.Ẹ o si jẹ́rìí nípa mi. 1421.14-15: Lk 12.11-12.Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ ní ọkàn yín pé ẹ ko ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn. 15Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú. 1621.16: Lk 12.52-53.A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; on ó sì mú kì a pa nínú yín. 1721.17: Mt 10.22; Jh 15.18-25.A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi. 1821.18: Lk 12.7; Mt 10.30; Ap 27.34; 1Sa 14.45.Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé. 1921.19: Mt 10.22; If 2.7.Nínú ìdúró ṣinṣin yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.

2021.20-22: Lk 19.41-44; 23.28-31; 17.31.“Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí ti a fi ogun yí Jerusalẹmu ká, ẹ mọ̀ nígbà náà pé, ìsọdahoro rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀. 21Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 2321.23: Lk 23.29.Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 2421.24: Ro 11.25; Isa 63.18; Da 8.13; If 11.2.Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

2521.25-27: Mt 24.29-30; Mk 13.24-26.21.25: If 6.12-13; Isa 13.10; Jl 2.10; Sf 1.15.“Ààmì yóò sì wà ní oorun, àti ní òṣùpá, àti ní ìràwọ̀; àti lórí ilẹ̀ ayé ìdààmú fún àwọn orílẹ̀-èdè nínú ìpayà híhó Òkun àti ìgbì omi. 26Àyà àwọn ènìyàn yóò máa já fún ìbẹ̀rù, àti ìrètí nǹkan wọ̀nyí tí ń bọ̀ sórí ayé: nítorí àwọn agbára ọ̀run ni a ó mì tìtì. 2721.27: Lk 9.27; Da 7.13-14.Nígbà náà ni wọn ó sì rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. 2821.28: Lk 18.7-8.Ṣùgbọ́n nígbà tí nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, ǹjẹ́ kí ẹ wo òkè, kí ẹ sì gbé orí yín sókè; nítorí ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀.”

2921.29-33: Mt 24.32-35; Mk 13.28-31.Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ẹ kíyèsi igi ọ̀pọ̀tọ́, àti sí gbogbo igi; 30Nígbà tí wọ́n bá rúwé, ẹ̀yin rí i, ẹ sì mọ̀ fúnra ara yín pé, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kù fẹ́ẹ́rẹ́. 31Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, nígbà tí ẹ̀yin bá rí nǹkan wọ̀nyí tí o ṣẹ, kí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.

3221.32: Lk 9.27.“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ìran yìí kì yóò rékọjá, títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ. 3321.33: Lk 16.17.Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá: ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

3421.34: Lk 12.45; Mk 4.19; 1Tẹ 5.6-7.“Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn. 35Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé. 3621.36: Mk 13.33.Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

3721.37: Lk 19.47; Mk 11.19.Lọ́sàn án, Jesu a sì máa kọ́ni ní tẹmpili: lóru, a sì máa jáde lọ í wọ̀ ní òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. 38Gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá ní tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.