士師記 20 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

士師記 20:1-48

討伐基比亞

1於是,從別示巴以及基列的全體以色列人萬眾一心,來到米斯巴,聚集在耶和華面前。 2以色列各支派的首領都參加了這次上帝子民的聚會,當時有四十萬持刀的步兵。 3便雅憫人也聽見以色列人聚集在米斯巴的消息。以色列人問那個利未人:「請告訴我們,這件邪惡的事是怎麼發生的。」 4利未人,就是被害女子的丈夫說:「我和我的妾到便雅憫基比亞住宿。 5那天晚上,基比亞人包圍我們住宿的房子,要殺死我。他們把我的妾蹂躪致死。 6我就把她的屍體切成塊,送到以色列的各個地區,讓以色列人都知道基比亞人做了邪惡、無恥的事。 7以色列人啊,你們看該怎麼處理吧!」

8眾人起來異口同聲地說:「我們誰也不回帳篷,誰也不回家。 9現在我們要抽籤去攻打基比亞10我們要從各支派中抽出十分之一的人負責運糧,等軍隊到達基比亞後,就可以討伐在以色列做出這種卑鄙之事的基比亞人。」 11於是,以色列人團結一致,一起去攻打那城。

12他們派人去對便雅憫各地的人說:「你們中間怎麼發生了這種邪惡的事! 13現在把那些基比亞的無賴交出來,我們要處死他們,從以色列剷除罪惡。」便雅憫人卻充耳不聞, 14還從各城聚集到基比亞以色列人打仗。 15便雅憫人從各城召集了兩萬六千刀兵,還從基比亞召集了七百精兵。 16軍中有七百精兵善用左手甩石,毫髮不差。 17其他十一個以色列支派則召集了四十萬善戰的刀兵。

18以色列人到伯特利去求問上帝,說:「我們當中哪個支派應當先去攻打便雅憫人呢?」耶和華說:「猶大支派。」

19第二天清早,以色列人就在基比亞附近安營, 20擺開陣勢,準備攻打便雅憫人。 21便雅憫人從基比亞出來,當天殺了以色列軍兩萬二千人。 22以色列人重整士氣,仍在第一天列陣的地方列陣。 23列陣之前,他們在耶和華面前一直哀哭到晚上。他們求問耶和華,說:「我們應該再去攻打我們的同胞便雅憫人嗎?」耶和華說:「可以去。」

24第二天,以色列人前去攻打便雅憫人。 25便雅憫人從基比亞出來迎戰,又殺了以色列軍一萬八千刀兵。 26以色列全軍來到伯特利,坐在耶和華面前哀哭,那天他們一直禁食到晚上,又在耶和華面前獻上燔祭和平安祭。 27-28那時,上帝的約櫃就在那裡,亞倫的孫子、以利亞撒的兒子非尼哈任祭司。以色列人求問耶和華,說:「我們應該再去攻打我們的同胞便雅憫人嗎?還是退兵?」耶和華說:「去攻打吧,因為明天我必把他們交在你們手中。」

29以色列人在基比亞周圍設下伏兵。 30第三天,以色列人又像前兩次一樣在基比亞列陣,攻打便雅憫人。 31便雅憫人前來迎戰,被以色列人誘到城外。他們又像前兩次一樣擊殺以色列人,大約三十名以色列人死在通往基比亞伯特利的兩條路上。 32便雅憫人說:「我們又打敗他們了。」但以色列人已經商議好,用詐敗的方法誘敵離城到大路上來。 33以色列全軍在巴力·他瑪列陣反攻,埋伏在基比亞西面的以色列人也衝了出來。 34有一萬以色列精兵從正面攻打基比亞,戰事非常激烈。便雅憫人大禍臨頭了仍懵然不知。 35耶和華幫助以色列人戰勝了便雅憫人。那天,以色列人殺了便雅憫兩萬五千一百刀兵。 36便雅憫人這才意識到自己戰敗了。

原來以色列人在便雅憫人面前詐敗,因為他們已在基比亞附近設下伏兵。 37那些伏兵迅速衝進基比亞,殺了全城的人。 38以色列人和伏兵已有約定,伏兵在城內點起一股濃煙時, 39以色列人便轉身殺回。便雅憫人殺了詐敗的以色列軍大約三十人,以為像以前一樣打敗了他們。 40這時基比亞城已濃煙滾滾,便雅憫人回頭觀望,只見全城濃煙四起。 41以色列人轉身殺了回來,便雅憫人大驚失色,知道大禍臨頭了。 42他們從以色列人面前轉身逃往曠野,卻無法逃脫。以色列人從各城出來夾攻他們。 43以色列人圍攻便雅憫人,一路追殺他們直到基比亞的東邊。 44便雅憫人共死了一萬八千名勇士。 45餘下的人都逃往曠野的臨門岩,沿途有五千人被殺。以色列人追殺他們,一直追到基頓,又消滅了他們兩千人。 46那天,便雅憫人共死了兩萬五千名英勇的刀兵, 47只有六百人逃到了臨門岩,在那裡住了四個月。 48以色列人回師便雅憫境內,將各城的男女老少以及牲畜全部殺死,又放火燒毀所有的城邑。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Onidajọ 20:1-48

Àwọn ọmọ Israẹli bá ará Benjamini jà

1Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli láti Dani dé Beerṣeba, àti láti ilẹ̀ Gileadi jáde bí ẹnìkan ṣoṣo wọ́n sì péjọ síwájú Olúwa ni Mispa. 2Àwọn olórí gbogbo àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli dúró ní ipò wọn ní àpéjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ogún ọ̀kẹ́ ọkùnrin ológun ti àwọn àti idà wọn. 3(Àwọn ẹ̀yà Benjamini gbọ́ wí pé àwọn ọmọ Israẹli yòókù ti gòkè lọ sí Mispa.) Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli wí pé, “Ẹ sọ fún wa báwo ni iṣẹ́ búburú ṣe ṣẹlẹ̀.”

4Ará Lefi náà, ọkọ obìnrin tí wọ́n pa fèsì pé, “Èmi àti àlè mi wá sí Gibeah ti àwọn ará Benjamini láti sùn di ilẹ̀ mọ́ níbẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ní òru àwọn ọkùnrin Gibeah lépa mi wọ́n sì yí ilé náà po pẹ̀lú èrò láti pa mí. Wọ́n fi ipá bá àlè mi lòpọ̀, òun sì kú. 6Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli. 7Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

8Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀. 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí: Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa. 10A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún (100) láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún ún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.” 11Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

12Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín? 13Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.”

Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli. 14Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 15Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah. 16Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé).

17Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

18Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli (ilé Ọlọ́run) wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”

19Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah). 20Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah. 21Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá-mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà. 22Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́. 23Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?”

Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì. 25Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

26Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà (ọrẹ ìrẹ́pọ̀) sí Olúwa. 27Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀, 28Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?”

Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

29Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sápamọ́ yí Gibeah ká. 30Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí. 31Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti pàdé wọn, àwọn ọmọ Israẹli sì tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ́gun àwọn ọmọ Israẹli bí i ti àtijọ́ dé bi pé wọ́n pa bí ọgbọ̀n ọkùnrin ní pápá àti ní àwọn òpópó náà—àwọn ọ̀nà tí ó lọ sí Beteli àti èkejì sí Gibeah. 32Nígbà tí àwọn Benjamini ń wí pé, “Àwa ti ń ṣẹ́gun wọn bí i ti ìṣáájú,” àwọn ọmọ Israẹli ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá kí a lè fà wọ́n kúrò ní ìlú sí ojú òpópó náà.”

33Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli dìde kúrò ní ipò wọn, wọ́n sì tẹ̀dó ogun ní Baali-Tamari, àwọn ọmọ-ogun Israẹli tí wọ́n sápamọ́ sínú igbó jáde kúrò níbi tí wọ́n wà ní ìwọ̀-oòrùn Gibeah. 34Nígbà náà ni ẹgbàá-márùn ún (10,000) àwọn àṣàyàn ológun àwọn ọmọ Israẹli gbógun ti Gibeah láti iwájú ogun náà le gidigidi dé bí i pé àwọn ẹ̀yà Benjamini kò funra pé ìparun wà nítòsí. 35Olúwa ṣẹ́gun Benjamini níwájú àwọn ọmọ Israẹli, ní ọjọ́ náà àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbàá-méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà (25,000) ọkùnrin Benjamini, gbogbo wọn fi idà dìhámọ́ra ogun. 36Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì rí pé wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn.

Àwọn ọkùnrin Israẹli fàsẹ́yìn níwájú àwọn ẹ̀yà Benjamini nítorí pé wọ́n fọkàn tán àwọn tí ó wà ní ibùba ní ẹ̀bá Gibeah. 37Àwọn ọkùnrin tí wọ́n lúgọ yára jáde wọ́n sì tètè wọ Gibeah, wọ́n fọ́nká wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìlú náà. 38Àwọn ọkùnrin Israẹli àti àwọn tí o ba ní ibùba sínú igbó ti fún ara wọn ní ààmì pé, kí àwọn tí ó ba ní ibùba fi èéfín ṣe ìkùùkuu ńlá láti inú ìlú náà, 39nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Israẹli yípadà, wọ́n sá gun.

Àwọn ọmọ Benjamini sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun àti ní pípa àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó to ọgbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Àwa ń ṣẹ́gun wọn bí ìgbà ìjà àkọ́kọ́.” 40Ṣùgbọ́n nígbà tí ìkùùkuu èéfín bẹ̀rẹ̀ sí ní rú sókè láti inú ìlú náà wá, àwọn ẹ̀yà Benjamini yípadà wọ́n sì rí èéfín gbogbo ìlú náà ń gòkè sí ojú ọ̀run. 41Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yípadà sí wọn, ẹ̀rù gidigidi sì ba àwọn ará Benjamini nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn wà nínú ewu. 42Wọ́n sì sá níwájú àwọn ọmọ Israẹli sí apá àṣálẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò le sálà kúrò lọ́wọ́ ogun náà. Àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó jáde láti inú àwọn ìlú wọn wá pa wọ́n run níbẹ̀. 43Wọ́n yí àwọn ẹ̀yà Benjamini ká, wọ́n lépa wọn, wọ́n sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní ibi ìsinmi wọn ní agbègbè ìlà-oòrùn Gibeah. 44Ẹgbàá-mẹ́sàn án (18,000) àwọn ẹ̀yà Benjamini ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni jagunjagun. 45Bí wọ́n ṣe ṣíjú padà tí wọ́n sì ń sálọ sí apá ijù lọ sí ọ̀nà àpáta Rimoni ni àwọn ọmọ Israẹli pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọkùnrin ní àwọn òpópónà. Wọ́n lépa àwọn ẹ̀yà Benjamini títí dé Gidomu, wọ́n sì tún bi ẹgbàá (2,000) ọkùnrin ṣubú.

46Ní ọjọ́ náà ẹgbàá-méjìlá ó lé ẹgbẹ̀rún (25,000) jagunjagun Benjamini tí ń fi idà jagun ní ó ṣubú, gbogbo wọn jẹ́ akọni ológun. 47Ṣùgbọ́n ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin yípadà wọ́n sì sá nínú ààlà lọ sí àpáta Rimoni, níbi tí wọ́n wà fún oṣù mẹ́rin. 48Àwọn ọkùnrin Israẹli sì padà sí àwọn ìlú Benjamini wọn sì fi idà pa gbogbo ohun tí ó wà nínú àwọn ìlú wọn àti àwọn ẹran àti gbogbo ohun tí wọn ba níbẹ̀. Gbogbo ìlú tí wọ́n bá ní ojú ọ̀nà ni wọ́n fi iná sun.