啟示錄 11 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

啟示錄 11:1-19

兩位見證人

1有一根杆子賜給我當量尺,同時有聲音吩咐我說:「起來,量一量上帝的殿和祭壇,並數點在殿裡敬拜的人。 2你不用量聖殿的外院,因為這部分已經給了外族人,他們要踐踏聖城四十二個月。 3我要賜權柄給我的兩個見證人,他們將身穿麻衣,傳道一千二百六十天。」

4這兩位見證人就是豎立在世界之主面前的那兩棵橄欖樹和兩座燈臺。 5若有人要傷害他們,他們便從口中噴出火焰,燒滅敵人;若有人企圖加害他們,必定會這樣被殺。 6他們擁有權能,在傳道期間可以關閉天空使雨不降在地上,又有權使水變成血,並隨時用各樣的災禍擊打世界。

7當他們做完見證以後,從無底坑上來的獸要和他們交戰,並戰勝他們,把他們殺掉。 8他們便陳屍在大城的街上,這大城按寓意名叫所多瑪,又名埃及,是他們的主被釘在十字架上的地方。 9三天半之久,他們的屍體不得埋葬,各民族、各部落、各語言族群、各國家的人都觀看他們的屍體。 10地上萬民便興高采烈,互相送禮道賀,因為這兩位先知曾使地上的人受苦。

11三天半過後,上帝的生命之氣進入二人裡面,他們便站立起來。看見的人都害怕極了! 12接著天上有大聲音呼喚他們說:「上這裡來!」他們就在敵人的注視下駕雲升上天去。 13就在那一刻,發生了強烈的地震,那座城的十分之一倒塌了,因地震死亡的共七千人,生還者都在恐懼中將榮耀歸給天上的上帝。

14第二樣災難過去了,第三樣災難又接踵而來!

第七位天使吹號

15第七位天使吹響號角的時候,天上有大聲音說:「世上的國度現在已經屬於我們的主和祂所立的基督了。祂要作王,直到永永遠遠。」 16在上帝面前,坐在自己座位上的二十四位長老都一同俯伏敬拜上帝,說:

17「主啊!昔在、今在的全能上帝啊!

我們感謝你,

因你已施展大能作王了。

18世上的列國曾向你發怒,

現在是你向他們發烈怒的日子了。

時候已到,你要審判死人,

你要賞賜你的奴僕、先知、聖徒

和一切不論尊卑敬畏你名的人,

你要毀滅那些毀壞世界的人。」

19那時,天上上帝的聖殿敞開了,殿內的約櫃清晰可見,又有閃電、巨響、雷鳴、地震和大冰雹。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìfihàn 11:1-19

Àwọn ẹlẹ́rìí méjì

111.1: El 40.3.A sì fi ìfèéfèé kan fún mi tí o dàbí ọ̀pá-ìwọ̀n: ẹnìkan sì wí pé, “Dìde, wọn tẹmpili Ọlọ́run, àti pẹpẹ, àti àwọn tí ń sìn nínú rẹ̀. 211.2: Sk 12.3; Isa 63.18; Lk 21.24.Sì fi àgbàlá tí ń bẹ lóde tẹmpili sílẹ̀, má sì ṣe wọ́n ọ́n; nítorí tí a fi fún àwọn aláìkọlà: ìlú mímọ́ náà ni wọn ó sì tẹ̀ mọ́lẹ̀ ní oṣù méjìlélógójì. 3Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ ọ̀fọ̀.” 411.4: Sk 4.3,11-14.Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. 511.5: 2Ọb 1.10; Jr 5.14.Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run: báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run. 611.6: 1Ọb 17.1; Ek 7.17,19.Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.

711.7: Da 7.3,7,21.Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n. 811.8: Isa 1.9.Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú. 9Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì. 10Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró.

1111.11: El 37.5,10.Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn. 1211.12: 2Ọb 2.11.Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn.

13Ní wákàtí náà omìmì-ilẹ̀ ńlá kan sì mì, ìdámẹ́wàá ìlú náà sì wó, àti nínú omìmì-ilẹ̀ náà ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ènìyàn ní a pa; ẹ̀rù sì ba àwọn ìyókù, wọn sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.

14Ègbé kejì kọjá; sì kíyèsi i, ègbé kẹta sì ń bọ̀ wá kánkán.

Ìpè méje

1511.15: Sm 22.28; Da 7.14,27.Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,

“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;

òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”

16Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17wí pé:

“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,

tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,

nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,

ìwọ sì ti jẹ ọba.

1811.18: Sm 2.1.Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,

àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,

àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,

àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,

àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;

àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”

1911.19: 1Ọb 8.1-6; 2.A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.