創世記 6 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 6:1-22

人類的邪惡

1人類在地上逐漸增多,生了女兒。 2上帝的兒子們6·2 上帝的兒子」可能指塞特的後代,天使或有權勢的人。看見人的女兒漂亮,就隨意選來做妻子。 3耶和華說:「人既然是血肉之軀,我的靈不會永遠住在人的裡面,然而人還可以活一百二十年。」 4從那時起,地上出現了一些巨人,他們是上古有名的勇士,是上帝的兒子和人的女兒所生的後代。

5耶和華看見人罪惡深重,心中終日思想惡事, 6就後悔在地上造了人,心裡傷痛, 7說:「我要把所造的人從地上除掉,連同一切飛禽走獸和爬蟲都除掉,我後悔造了他們。」 8只有挪亞在耶和華面前蒙恩。

上帝命挪亞造方舟

9以下是有關挪亞的記載。

挪亞是個義人,在當時的世代是個純全無過的人,他與上帝同行。 10挪亞生了三個兒子:雅弗

11當時的世界在上帝眼中非常敗壞,充滿了暴行。 12上帝看見世界敗壞了,因為世人行為敗壞。 13祂對挪亞說:「世人惡貫滿盈,他們的結局到了。我要把他們跟大地一起毀滅。 14你要為自己用歌斐木建造一艘方舟,裡面要有艙房,內外都要塗上柏油。 15你建造的方舟要長一百三十三米,寬二十二米,高十三米。 16舟頂要有五十釐米高的透光口,門開在方舟的側面,整艘方舟要分為上、中、下三層。 17看啊,我要使洪水在地上氾濫,毀滅天下。地上一切有氣息的生靈都要滅亡。 18但我要跟你立約,你與妻子、兒子和兒媳都可以進方舟。 19每種動物你要帶兩隻進方舟,雌雄各一隻,好保存牠們的生命。 20各種飛禽走獸和爬蟲要按種類每樣一對到你那裡,好保住生命。 21你要為自己和這些動物預備各種食物,貯存起來。」

22挪亞就照著上帝的吩咐把事情都辦好了。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 6:1-22

Ìkún omi

16.1-4: Jb 1.6; 2.1.Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. 2Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. 3Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

46.4: Nu 13.33.Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

5Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. 6Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. 7Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” 8Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa.

96.9: 2Pt 2.5.Wọ̀nyí ni ìtàn Noa.

Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. 10Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

11Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. 12Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. 13Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. 14Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà-ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. 15Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. 16Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. 17Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. 18Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ. 19Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. 20Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. 21Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”

226.22: Hb 11.7.Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.