傳道書 9 – CCBT & YCB

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

傳道書 9:1-18

1我仔細思想、探究這些事,就知道義人、智者及他們的行事為人都由上帝掌管,人無法知道前面等待自己的是愛還是恨。 2義人和惡人、好人和壞人、潔淨的和污穢的、獻祭的和不獻祭的、行善的和犯罪的、敢於起誓的和不敢起誓的人,最終的命運都一樣。 3在日光之下有一件可悲的事,就是人最終的命運都一樣。再者,人內心都充滿邪惡,活著的時候行事狂妄,最後都步入死亡。 4有生命就有希望,一條活狗總比一頭死獅子強。 5因為活著的人還知道自己終有一死,但死了的人什麼都不知道,再也得不到任何賞賜,他們被忘得一乾二淨。 6他們的愛、恨和嫉妒早已不復存在,他們再也無法參與日光之下的事。

7去歡歡喜喜、快快樂樂地吃喝吧!因為上帝已經悅納你所做的。 8你的衣服要經常保持潔白,頭上也不要缺少膏油。 9在你虛空的人生中,就是在上帝所賜、日光之下虛空的歲月裡,你要與愛妻快樂度日,因為這是你一生在日光之下的勞碌中所當得的。 10凡你的手能做的,都要盡力去做,因為在你要去的陰間沒有工作,沒有計劃,也沒有知識和智慧。 11我又發現,日光之下,跑得快的未必能得獎,強大的未必能得勝,智者未必得溫飽,聰明人未必有財富,博學者未必受愛戴,因為時機和境遇左右眾人。 12再者,人無法知道何時大難臨頭。禍患突然臨到時,人根本無法擺脫,就像魚落入險惡的網中,又像鳥兒陷入網羅。 13我看見日光之下有一種智慧,對我來說意義深遠。 14有一個勢力強大的君王來攻擊一個人口不多的小城,他建造營壘圍困這城。 15這城裡有一個貧窮的智者,他用智慧拯救了這城,但事後人們卻把他遺忘了。 16我認為智慧勝過武力,然而那位窮人的智慧卻被輕視,他所說的話也無人理會。 17智者的細語勝過官長在愚人中的喊叫。 18智慧勝過兵器,但一個罪人卻能破壞許多善事。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Oniwaasu 9:1-18

Àyànmọ́ kan náà fún gbogbo wọn

1Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. 2Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.

Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere

bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀

bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra

bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.

3Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. 4Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!

5Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú

ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan

wọn kò ní èrè kankan mọ́,

àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.

6Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn

àti ìlara wọn ti parẹ́:

láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín

nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

7Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe. 8Máa wọ aṣọ funfun nígbàkúgbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. 9Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

11Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn

Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára

tàbí ogun fún alágbára

bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n

tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye

tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;

ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.

12Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:

Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú

tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn

gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi

tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

Ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ lọ

13Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn: 14Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16Nítorí náà mo sọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

17Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ

ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.

18Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,

ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.