约翰福音 8 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

约翰福音 8:1-59

淫妇获赦

1众人都回家去了,耶稣却上了橄榄山。 2第二天清晨,祂又回到圣殿。百姓聚集在祂那里,祂就坐下来教导他们。 3这时候,律法教师和法利赛人带来一个通奸时被捉的女人,让她站在众人面前, 4然后问耶稣:“老师,这个女人是在通奸时被捉到的。 5摩西的律法,我们要用石头把她打死,你说该怎么处置她呢?”

6他们这样问是要使耶稣落在他们的圈套里,可以有借口控告祂。耶稣却只是弯着腰用指头在地上写字。 7他们不断地追问耶稣,于是祂直起腰来,对他们说:“你们中间谁没有罪,谁就先拿石头打她吧。” 8说完,又弯下腰在地上写字。

9他们听了这句话,就从老到少一个一个地走了,只剩下耶稣和那个女人在那里。 10耶稣直起腰来,说:“妇人,他们到哪里去了?没有人定你的罪吗?”

11她说:“主啊,没有。”

耶稣说:“我也不定你的罪。回去吧,从今以后不要再犯罪了。”

世界的光

12耶稣又对众人说:“我是世界的光,凡跟从我的,必不会走在黑暗里,必要得到生命的光。”

13法利赛人对祂说:“你自己为自己做见证,你的见证不真实。”

14耶稣说:“即便我自己为自己做见证,我的见证仍是真实的,因为我知道自己从哪里来、要到哪里去,你们却不知道我从哪里来、要到哪里去。 15你们只凭外表判断别人,我却不判断人。 16就算我判断人,我的判断也是正确的,因为我不是独自一人,还有差我来的父与我同在。 17你们的律法不是说两个人做见证就有效吗? 18我是自己为自己做见证,差我来的父也为我做见证。”

19他们问:“你的父在哪里?”

耶稣回答说:“你们不认识我,也不认识我的父。如果你们认识我,也会认识我的父。” 20耶稣在圣殿的库房这样教导人,但没有人抓祂,因为祂的时候还没有到。

警告不信的人

21耶稣又对他们说:“我要走了,你们会寻找我,你们将死在自己的罪中。我去的地方,你们不能去。”

22犹太人说:“祂说祂去的地方我们不能去,难道祂想自杀吗?”

23耶稣对他们说:“你们是从下面来的,我是从上面来的。你们属于这世界,我不属于这世界。 24所以我说你们将死在自己的罪中,你们如果不相信我就是8:24 耶稣用“我就是”这个词提醒听众祂就是出埃及记3:14节提到的那位自有永有的上帝,8:28同。那一位,一定会死在自己的罪中。”

25他们问:“你到底是谁?”

耶稣回答说:“我不是早就告诉你们了吗? 26关于你们,我有许多要说、要审判的,但差我来的那位是真实的,我把从祂那里听到的告诉世人。” 27他们不明白耶稣是指着父说的。

28于是耶稣说:“你们举起人子以后,必知道我就是那一位,并且知道我没有一件事是凭自己做的,我所说的都是父教导我的。 29差我来的那位跟我在一起,祂没有撇下我,让我孤单一人,因为我做的都是祂所喜悦的。” 30许多人因为这番话而信了耶稣。

真正的自由

31耶稣对信祂的犹太人说:“你们若持守我的道,就真是我的门徒了。 32你们必认识真理,真理必叫你们得到自由。”

33他们说:“我们是亚伯拉罕的子孙,从来没有做过奴隶,你为什么说我们可以得到自由呢?”

34耶稣说:“我实实在在地告诉你们,所有犯罪的人都是罪的奴隶。 35奴隶不能永远留在主人的家里,只有儿子才可以。 36所以,如果上帝的儿子释放了你们,你们就真正自由了!

耶稣和亚伯拉罕

37“我知道你们是亚伯拉罕的子孙,但你们却想杀我,因为你们心里容不下我的道。 38我所说的,是我从父那里看到的,你们却照着你们父8:38 犹太文化中,“父”可指生身的父,亦可泛指祖先。的话去做。”

39他们说:“我们的父就是亚伯拉罕!”

耶稣说:“你们如果真是亚伯拉罕的子孙,一定会做他所做的事。 40我把从上帝那里听到的真理告诉你们,你们反要杀我,亚伯拉罕绝不做这样的事。 41你们是在做你们父所做的事。”

他们说:“我们不是从淫乱生的!我们只有一位父,就是上帝。”

42耶稣说:“如果上帝是你们的父,你们一定会爱我,因为我来自上帝。如今我在这里,我不是凭自己来的,而是上帝差我来的, 43你们为什么不明白我的话呢?因为你们听不进去我的道。 44你们是出于你们的父魔鬼,你们乐意顺着它的私欲行。魔鬼从起初就是个杀人凶手,从不站在真理这一边,因为它心里根本没有真理。撒谎是它的本性,因为它是撒谎者,又是撒谎者的始祖。 45所以,我讲真理的时候,你们不信我。 46你们谁能指证我有罪呢?我既然把真理告诉了你们,你们为什么还不信我呢? 47出于上帝的人听上帝的话,你们不听上帝的话,因为你们不是出于上帝。”

48犹太人对祂说:“我们说你是撒玛利亚8:48 撒玛利亚人血统不纯,常被犹太人藐视,并当作骂人的话。,被鬼附身了,难道不对吗?”

49耶稣说:“我没有被鬼附身。我尊敬我的父,你们却侮辱我。 50我不为自己寻求荣耀,但有一位会为我寻求,祂也会断定谁是谁非。 51我实实在在地告诉你们,人如果遵行我的道,必永远不死。”

52那些犹太人说:“现在我们的确知道你是被鬼附身了!亚伯拉罕和众先知都死了,你还说人如果遵行你的道,必永远不死。 53难道你比我们的祖先亚伯拉罕还大吗?他死了,先知们也死了,你以为你是谁?”

54耶稣说:“如果我为自己争取荣耀,那荣耀算不了什么。但使我得荣耀的是我的父,你们也称祂为你们的上帝。 55你们不认识祂,我却认识祂。如果我说我不认识祂,那我就像你们一样是说谎的。然而,我认识祂,并且遵行祂的道。 56你们的祖先亚伯拉罕曾经欢欢喜喜地盼望看见我来的日子。他看见了,就欢喜快乐。”

57犹太人说:“你还不到五十岁,怎么会见过亚伯拉罕呢?”

58耶稣说:“我实实在在地告诉你们,亚伯拉罕还没有出生,我就已经存在了8:58 我就已经存在了”希腊文是“我是”,参见8:24注。。” 59于是,他们就拿起石头要打祂,耶稣却避开他们,离开了圣殿。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 8:1-59

1Jesu sì lọ sí orí òkè olifi.

2Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. 3Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. 4Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà, 5Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?” 6Èyí ni wọ́n wí, láti dán án wò, kí wọn ba à lè rí ẹ̀sùn kan kà sí i lọ́rùn.

Ṣùgbọ́n Jesu bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ń fi ìka rẹ̀ kọ̀wé ní ilẹ̀. 7Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè lemọ́lemọ́, ó gbe orí rẹ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Jẹ́ kí ẹni tí ó wà láìní ẹ̀ṣẹ̀ nínú yín kọ́kọ́ sọ òkúta lù ú.” 8Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sílẹ̀, ó ń kọ̀wé ní ilẹ̀.

9Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, (tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì dá wọn lẹ́bi) wọ́n sì jáde lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títí dé àwọn tí ó kẹ́yìn; a sì fi Jesu nìkan sílẹ̀, àti obìnrin náà láàrín, níbi tí ó wà. 10Jesu sì dìde, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”

Jesu wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: máa lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”

Ẹ̀rí Jesu dájú

128.12: Jh 9.5; 12.35; 1.4.Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

138.13-18: Jh 5.31-39.Nítorí náà àwọn Farisi wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rìí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rìí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ. 158.15: Jh 7.24; 3.17.Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni. 168.16: Jh 5.30.Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi. 178.17: De 19.15; Mt 18.16.A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì. 18Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rìí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí mi.”

198.19: Jh 14.7.Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”

Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.” 208.20: Mk 12.41; Jh 7.30.Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jesu sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹmpili: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tí ì dé.

218.21-22: Jh 7.33-36.Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

22Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?”

238.23: Jh 3.31; 17.14; 1Jh 4.5.Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. 248.24: Jh 8.28; 4.26; 13.19; Mk 13.6.Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

25Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?”

Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. 26Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.”

27Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. 288.28: Jh 3.14; 12.32.Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. 29Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” 308.30: Jh 7.31; 10.42; 11.45.Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.

Àwọn ọmọ Abrahamu

318.31: Jh 15.7; 2Jh 9.Nítorí náà Jesu wí fún àwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi nítòótọ́. 328.32: 2Kọ 3.17; Ga 5.1.Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”

338.33: Mt 3.9; Ga 3.7.Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-ọmọ Abrahamu ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”

348.34: Ro 6.16; 2Pt 2.19.Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. 358.35: Gẹ 21.10; Ga 4.30.Ẹrú kì í sì í gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé 36Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́. 37Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Abrahamu ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí ààyè nínú yín. Jesu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀. 38Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”

39Wọ́n dáhùn, wọ́n sì wí fún un pé, “Abrahamu ni baba wa!”

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìbá ṣe iṣẹ́ Abrahamu 40Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ̀yin ń wá ọ̀nà láti pa mí, ẹni tí ó sọ òtítọ́ fún yín, èyí tí mo ti gbọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run: Abrahamu kò ṣe èyí. 418.41: De 32.6; Isa 63.16; 64.8.Ẹ̀yin ń ṣe iṣẹ́ baba yín.”

Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “a kò bí wa nípa panṣágà: a ní Baba kan, èyí sì ni Ọlọ́run.”

Àwọn ọmọ èṣù

428.42: Jh 13.3; 16.28.Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá ṣe pé Ọlọ́run ni Baba yín, ẹ̀yin ìbá fẹ́ràn mi: nítorí tí èmi ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jáde, mo sì wá; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì wá fún ara mi, ṣùgbọ́n òun ni ó rán mi. 43Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. 448.44: 1Jh 3.8,15; Gẹ 3.4; 1Jh 2.4; Mt 12.34.Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké. 45Ṣùgbọ́n nítorí tí èmi ń sọ òtítọ́ fún yín, ẹ̀yin kò sì gbà mí gbọ́. 46Ta ni nínú yín tí ó ti dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀? Bí mo bá ń ṣọ òtítọ́, èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà mí gbọ́? 47Ẹni tí ń ṣe ti Ọlọ́run, a máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí èyí ni ẹ̀yin kò ṣe gbọ́, nítorí ẹ̀yin kì í ṣe ti Ọlọ́run.”

Jesu béèrè nípa ohun tí n ṣe ti ara rẹ̀

488.48: Jh 7.20; 10.20; 4.9.Àwọn Júù dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò wí nítòótọ́ pé, ará Samaria ni ìwọ jẹ́, àti pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù?”

49Jesu sì dáhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù, ṣùgbọ́n èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ẹ̀yin kò sì bu ọlá fún mi. 50Èmi kò wá ògo ara mi: Ẹnìkan ń bẹ tí ó ń wá a tí yóò sì ṣe ìdájọ́. 51Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò rí ikú láéláé.”

52Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’ 538.53: Jh 4.12.Ìwọ ha pọ̀ ju Abrahamu Baba wa lọ, ẹni tí ó kú? Àwọn wòlíì sì kú: ta ni ìwọ ń fi ara rẹ pè?”

54Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe: 55Ẹ kò sì mọ̀ ọ́n: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n: bí mo bá sì wí pé, èmi kò mọ̀ ọ́n, èmi yóò di èké gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: ṣùgbọ́n èmi mọ̀ ọ́n, mo sì pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. 568.56: Mt 13.17; Hb 11.13.Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”

578.57: Jh 2.20.Nítorí náà, àwọn Júù wí fún un pé, “Ọdún rẹ kò ì tó àádọ́ta, ìwọ sì ti rí Abrahamu?”

588.58: Jh 1.1; 17.5,24.Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kí Abrahamu tó wà, èmi ti wa.” 598.59: Jh 10.31; 11.8.Nítorí náà wọ́n gbé òkúta láti sọ lù ú: ṣùgbọ́n Jesu fi ara rẹ̀ pamọ́, ó sì jáde kúrò ní tẹmpili.