申命记 4 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

申命记 4:1-49

当守律法

1以色列人啊,要聆听我传授给你们的律法,要切实遵行,以便你们可以存活,并进入你们祖先的上帝耶和华赐给你们的那片土地。 2我吩咐你们的,你们不可做任何增减,这是你们的上帝耶和华的命令,你们要遵守。 3你们亲眼看见耶和华在巴力·毗珥事件中的作为,你们的上帝耶和华毁灭了你们中间所有拜巴力·毗珥的人, 4但你们这些信靠你们的上帝耶和华的人至今还活着。 5看啊,遵照我的上帝耶和华的吩咐,我把律例和典章传授给你们,好让你们在将要占领的土地上遵守。 6你们要谨遵这些律例和典章,因为这样就会让外族人看见你们的智慧和聪明。他们听见这些律法后,必说,‘这伟大的民族真有智慧和聪明!’ 7我们的上帝耶和华与我们如此亲近,随时垂听我们的呼求,有哪个伟大民族的神明能与之相比? 8有哪个伟大的民族拥有我今天所传授给你们的如此公义的律例和典章?

9“要谨慎、小心,不可忘记亲眼所见的事,要一生铭记在心,并且告诉子子孙孙。 10那天,你们在何烈山站在你们的上帝耶和华面前,耶和华对我说,‘把民众招聚起来,让他们听我的教诲,学习一生敬畏我,并传授给自己的儿女。’ 11你们来到山脚下,站在那里,山上烈焰冲天、乌云密布、极其幽暗。 12耶和华在火焰中对你们说话,你们只听见祂的声音,却看不见祂的形象。 13祂向你们宣告祂的约,就是祂吩咐你们遵守的十诫,并写在两块石版上。 14那时,耶和华吩咐我把律例和典章传授给你们,好让你们在将要占领的土地上遵守。

不可拜偶像

15“你们要格外小心,耶和华在何烈山的火焰中对你们说话时,你们没有看见任何形象, 16所以不可堕落,去为自己制造任何形状的神像——男人、女人、 17飞禽走兽、 18爬虫或鱼类。 19当你们举目观看你们的上帝耶和华赐给天下万民的日、月、星辰等天上万象时,不要受诱惑去跪拜、供奉它们。 20耶和华拯救你们脱离埃及那座熔铁炉,让你们做祂自己的子民,正如今日的情形。 21因你们的缘故,耶和华向我发怒,起誓不让我过约旦河、进入祂赐给你们作产业的那片佳美之地。 22我将死在约旦河这边,过不了约旦河。但你们必过去得到那片佳美之地。 23你们要谨慎,不可忘记你们的上帝耶和华与你们所立的约,不可违背你们上帝耶和华的禁令,去制造任何形状的神像。 24因为你们的上帝耶和华是烈火,是痛恨不贞的上帝。

25“将来,即使你们在那里安顿已久、子孙满堂,也不可堕落、制造任何形状的神像,不可做你们的上帝耶和华视为邪恶的事,惹祂发怒。 26否则,今天我叫天地作证,你们必很快从约旦河对面将要占领的土地上灭亡,你们必被彻底消灭,不得在那里长久居住。 27耶和华必把你们驱散到列邦,使你们在列邦中的人数所剩无几。 28你们必在那里供奉人用木石造的不会看、不会听、不会吃、不会闻的神像。 29但你们若在那里寻求你们的上帝耶和华,全心全意地寻求祂,就必寻见。 30日后,当你们遭遇这些事,受尽苦难的时候,必归向你们的上帝耶和华,听从祂。 31因为你们的上帝耶和华充满怜悯,祂不会抛弃你们,灭绝你们,也不会忘记祂与你们祖先所立的誓约。

独一的上帝

32“你们可以查考历史,自上帝创造世人以来,这样的奇事,天地之间何曾有过?谁曾听闻? 33有哪个民族像你们一样,听见了上帝在火中说话,还活了下来? 34有哪个神明像你们的上帝耶和华那样在埃及当着你们的面降灾祸、行神迹奇事、兴起战争、伸出臂膀、施展大能的手、以伟大而可畏的作为拯救一族脱离异邦? 35耶和华行这样的事,是要叫你们知道祂是上帝,除祂以外,别无他神。 36祂让你们听见祂从天上来的声音,好教导你们,又在地上让你们看见祂的烈火,并听见祂在烈火中说的话。 37因为祂爱你们的祖先,所以拣选你们,亲自用大能把你们从埃及领出来, 38赶走比你们强大的民族,领你们进入他们的土地,把他们的土地赐给你们作产业,正如今日的情形。 39所以,今天你们要知道并谨记,耶和华是天上地下的上帝,此外别无他神。 40我今天将祂的律例和诫命传授给你们,你们要遵守,以便你们及子孙都蒙福,在你们上帝耶和华所赐的土地上得享长寿。”

设立避难城

41那时,摩西约旦河东划出三座城作避难城, 42供素无冤仇却误杀他人者逃往避难。 43三座城分别是旷野高原的比悉——供吕便人避难,基列拉末——供迦得人避难,巴珊哥兰——供玛拿西人避难。

重申律法

44以下是摩西颁布给以色列人的律法, 45即在离开埃及后传授给他们的法度、律例和典章。 46当时他们在约旦河以东伯·毗珥对面的山谷,那里原属于希实本亚摩利西宏摩西以色列人离开埃及后消灭了西宏47占领了他的土地,还占领了巴珊的土地。西宏约旦河东亚摩利人的两个王, 48其国土从亚嫩谷边的亚罗珥一直到西云山,即黑门山, 49包括约旦河东的整个亚拉巴,远至毗斯迦山脚的亚拉巴海。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 4:1-49

Mose pàṣẹ ìgbọ́ràn

1Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín. 24.2: If 22.18,19.Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

3Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Olúwa ṣe ní Baali-Peori. Olúwa Ọlọ́run yín run gbogbo àwọn tí ó tẹ̀lé òrìṣà Baali-Peori kúrò ní àárín yín. 4Ṣùgbọ́n gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni ẹ wà láààyè lónìí.

5Ẹ kíyèsi i, mo ti kọ́ ọ yín ní àwọn òfin àti àṣẹ bí Olúwa Ọlọ́run mi ti pàṣẹ fún mi, kí ẹ ba à le tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń lọ láti ní ní ìní. 6Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.” 7Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkúgbà tí a bá ń ké pè é? 8Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

94.9-14: El 19.1–20.21.Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn. 10Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú Olúwa Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.” 11Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí, ẹ sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè náà, òkè náà sì ń jóná dé agbede-méjì ọrun, pẹ̀lú òkùnkùn, àti àwọsánmọ̀, àti òkùnkùn biribiri. 12Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárín iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́. 134.13: El 31.18; 34.28; De 9.10.Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí wàláà òkúta méjì. 144.14: El 21.1.Olúwa sì pàṣẹ fún mi nígbà náà láti kọ yín ní ìlànà àti ìdájọ, kí ẹ̀yin kí ó lè máa ṣe wọ́n ní ilẹ̀ náà, ní ibi tí ẹ̀yin ń lọ láti gbà á.

Èèwọ̀ ni ìbọ̀rìṣà jẹ́

15Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi, 16kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, 17tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú, 18tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi. 19Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run. 20Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ejibiti, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

21Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jordani kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín. 22Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jordani kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdìkejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà. 23Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá: Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí. 24Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

25Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti ní àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ ọmọ, tí ẹ sì ti gbé ní ilẹ̀ yìí pẹ́: Bí ẹ bá wá ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe irú ère yówù tó jẹ́, tí ẹ sì ṣe búburú lójú Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì mú un bínú. 26Mo pe ọ̀run àti ayé láti jẹ́rìí takò yín lónìí, pé kíákíá ni ẹ ó parun ní ilẹ̀ náà tí ẹ ń la Jordani kọjá lọ láti gbà. Ẹ kò ní pẹ́ ní ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò run pátápátá. 27Olúwa yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn ènìyàn náà, àwọn díẹ̀ nínú yín ni yóò yè láàrín orílẹ̀-èdè tí Olúwa yóò fọ́n yín sí. 28Ẹ ó sì máa sin ọlọ́run tí á fi ọwọ́ ènìyàn ṣe: tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe, èyí tí kò le ríran, gbọ́rọ̀, jẹun tàbí gbọ́ òórùn. 29Bí ẹ̀yin bá wá Olúwa Ọlọ́run yín láti bẹ̀ ẹ́, ẹ ó ri i, bí ẹ bá wá a, pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà a yín. 30Bí ẹ bá wà nínú wàhálà, bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ sí yín, láìpẹ́ ẹ ó tún padà tọ Olúwa Ọlọ́run yín wá, ẹ ó sì gbọ́ tirẹ̀. 31Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.

Olúwa ni Ọlọ́run

32Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí? 33Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè? 34Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnrarẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ ààmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?

35A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. 36Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá, 37torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti. 38Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.

39Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́. 40Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.

Àwọn ìlú Ààbò

414.41-43: Nu 35.6,9-34; De 19.2-13; Jo 20.7-9.Mose sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀-oòrùn Jordani. 42Kí apànìyàn kí ó lè máa sá síbẹ̀, tí ó bá ṣi ẹnìkejì rẹ̀ pa, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, àti pé bí ó bá sá sí ọ̀kan nínú ìlú wọ̀nyí kí ó lè là. 43Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Beseri ní ijù, ní ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, tí àwọn ọmọ Reubeni; Ramoti ní Gileadi, ti àwọn ọmọ Gadi àti Golani ní Baṣani, ti àwọn ará Manase.

Ìfáàrà sí òfin

44Èyí ni òfin tí Mose gbé kalẹ̀ fún àwọn ará Israẹli. 45Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀rí, àti ìlànà àti ìdájọ́ tí Mose fi lélẹ̀ fún ún àwọn ọmọ Israẹli, lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Ejibiti. 46Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá Àfonífojì Beti-Peori ní ìlà-oòrùn Jordani; ní ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn Amori tí ó jẹ ọba Heṣboni tí Mose àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Ejibiti bọ̀. 47Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani àwọn ọba Amori méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà-oòrùn Jordani. 48Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri ní etí odò Arnoni dé orí òkè Sirioni (èyí ni Hermoni). 49Àti gbogbo aginjù ní ìlà-oòrùn Jordani títí dé Òkun aginjù (Òkun iyọ̀) ní ìsàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga.