帖撒罗尼迦后书 1 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

帖撒罗尼迦后书 1:1-12

1保罗西拉提摩太写信给帖撒罗尼迦属于我们父上帝和主耶稣基督的教会。

2愿我们的父上帝和主耶稣基督赐给你们恩典和平安!

感恩与劝勉

3弟兄姊妹,我们应当为你们常常感谢上帝,这是合宜的,因为你们的信心不断增长,彼此相爱的心也不断增加。 4因此,我们在上帝的众教会中夸奖你们在各种迫害和患难中的坚忍和信心。 5你们这种表现正是上帝公义审判的明证,使你们配进上帝的国,你们正在为这国受苦。

6上帝是公义的,祂必以患难来报应那些迫害你们的人。 7当主耶稣和祂大能的天使在烈焰中从天上显现时,祂必使你们这些受苦的人和我们同得安慰, 8惩罚那些不认识上帝、不听从有关我们主耶稣之福音的人。 9那些人要受的刑罚就是离开主的面和祂荣耀的权能,永远灭亡。 10主降临的那日,祂要在祂的众圣徒中得到荣耀,使所有的信徒惊叹不已。你们也会在当中,因为你们相信了我们做的见证。

11因此,我们常常为你们祷告,愿我们的上帝看你们配得祂的呼召,用大能成全你们一切美好的心愿和凭信心所做的工作。 12这样,按照我们的上帝和主耶稣基督所赐的恩典,主耶稣基督的名便在你们身上得到荣耀,你们也在祂身上得到荣耀。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Tẹsalonika 1:1-12

11.1: 1Tẹ 1.1; 2Kọ 1.19; Ap 16.1.Paulu, Sila àti Timotiu,

Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

21.2: Ro 1.7.Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa.

Àdúrà àti ìdúpẹ́

31.3: 1Tẹ 1.2.Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. 4Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

5Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. 6Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, 7Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. 81.8: Ga 4.8.Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. 9A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ 10Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.

111.11: 1Tẹ 1.3.Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.