列王纪下 11 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

列王纪下 11:1-21

耶何耶大立约阿施为王

1亚哈谢的母亲亚她利雅见儿子死了,便决定除掉王室后裔。 2约兰王的女儿、亚哈谢的妹妹约示芭把亚哈谢的儿子约阿施从被杀的王子中偷出来,将他和乳母藏在一间卧室里,才躲过亚她利雅,使约阿施没有被杀。 3约阿施和他的乳母在耶和华的殿里藏了六年,那时亚她利雅篡位当政。

4第七年,耶何耶大派人召迦利11:4 迦利人”指雇来保护王的外族卫兵。和卫兵的百夫长们到耶和华的殿里,与他们立约,让他们在耶和华的殿里起誓,然后把约阿施王子带到他们面前。 5耶何耶大吩咐他们说:“你们在安息日值班的,三分之一要守卫王宫, 6三分之一要守卫苏珥门,三分之一要守住卫兵院后门。你们要轮流守卫。 7安息日没有值班的两队要在耶和华的殿里保护王, 8各人要手持兵器护卫在王周围。凡擅自闯入者,都要处死。无论王去哪里,你们都要紧随左右。” 9众百夫长依令而行,各自率领安息日值班和休班的随从来见耶何耶大10耶何耶大把耶和华殿中大卫王的矛枪和盾牌交给百夫长。 11从殿右到殿左,在祭坛和殿周围,卫兵都手持兵器护卫王。 12耶何耶大祭司领王子出来,给他戴上王冠,把律法书交给他,膏立他为王。众人都鼓掌高呼:“愿王万岁!”

13亚她利雅听见卫兵和众人的欢呼声,便走进耶和华的殿,众人都聚集在那里。 14她看见王照例站在柱旁,百夫长和吹号的人侍立在王左右,众人都欢呼吹号,便撕裂衣服喊叫:“反了!反了!” 15耶何耶大祭司认为不可在耶和华的殿里处死亚她利雅,便命令领兵的百夫长:“把她带出去。凡跟随她的,都要杀掉。” 16他们抓住她,把她带到马匹进出王宫的入口,在那里杀了她。

17耶何耶大让王及民众与耶和华立约,做耶和华的子民,也让王与民众立约。 18于是,民众出去拆毁了巴力庙,砸碎祭坛和偶像,在坛前杀了巴力的祭司玛坦耶何耶大派守卫保护耶和华的殿, 19然后率领百夫长、迦利人、卫兵和民众,护送王从耶和华的殿下来,经过卫兵院的门进入王宫。这样,约阿施坐上了王位。 20民众都欢喜快乐,城里安定,因为亚她利雅已在王宫那里被处死。 21约阿施七岁登基。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 11:1-21

Ataliah àti Joaṣi

111.1-20: 2Ki 22.10–23.21.Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run. 2Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti arábìnrin Ahasiah, mú Joaṣi ọmọ Ahasiah, ó sì jí i lọ kúrò láàrín àwọn ọmọ-aládébìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataliah; bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á. 3Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ náà.

4Ní ọdún keje, Jehoiada ránṣẹ́ ó sí mú àwọn olórí lórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, pẹ̀lú àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n. 5Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún ṣíṣọ́ ààfin ọba. 6Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn huri, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní ṣíṣọ́ ilé tí a kọ́, 7Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba. 8Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbọdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

9Olórí àwọn ọ̀rọ̀ọ̀rún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti pa á láṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jehoiada àlùfáà. 10Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dafidi tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 11Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́bàá pẹpẹ àti ilé ìhà gúúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà.

12Jehoiada mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi ààmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”

13Nígbà tí Ataliah gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 14Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn balógun àti àwọn afùnpè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀, wọ́n sì ń fun ìpè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataliah fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”

15Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.” 16Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á.

17Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú. 18Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.

Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 19Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú ààyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba. 20Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, pẹ̀lú ìlú ńlá náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà náà ní ààfin ọba.

21Jehoaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.