出埃及记 19 – CCB & YCB

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

出埃及记 19:1-25

以色列人在西奈山

1以色列人离开埃及满三个月的那一天,他们来到西奈半岛的旷野。 2他们离开利非订,来到西奈旷野,在那里的山下安营。

3摩西上山到上帝那里,耶和华从山上呼唤他说:“你告诉雅各家,告诉以色列人, 4‘我怎样对付埃及人,你们都看见了,我好像鹰一样把你们背在翅膀上带到我这里。 5现在,倘若你们认真听从我的话,遵守我的约,就必在万民中做我的子民,因为普天下都是我的。 6你们要归于我,作祭司之国、圣洁之邦。这些话你要告诉以色列人。’”

7摩西召集以色列的长老,把耶和华对他的一切吩咐都转告他们。 8百姓都齐声回答说:“凡耶和华所吩咐的,我们都愿意遵从。”

摩西便把他们的话回报耶和华。 9耶和华对摩西说:“我会在密云中临到你那里,使百姓也可以亲耳听见我与你说话的声音,这样他们就会永远信赖你。”摩西以色列人的话回报耶和华。 10耶和华对摩西说:“你现在回到他们那里,吩咐他们今天和明天要洁净自己,洗净衣服, 11到后天都要预备好,因为这一天耶和华要在百姓眼前降临在西奈山上。 12此外,你要在山的四围划定界线,吩咐百姓不得上山或碰到界线,违例者死。 13你们不可用手触摸违例者,要用石头打死他或用箭射死他,牲畜也不例外。百姓要一直等到听见角声长鸣才可上山。” 14于是,摩西下山回到百姓那里,吩咐他们各人洁净自己,洗净衣服。 15又吩咐他们说:“到后天一切都要准备好,这期间你们不可亲近女人。”

16到了第三天早晨,山上雷电大作,乌云密布,又有嘹亮的号角声,营中的百姓都胆战心惊。 17摩西率领百姓出营迎接上帝,他们都站在山脚下。 18因为耶和华在火中降临到西奈山,整座山都冒着浓烟,滚滚上腾,好像一个大火窑,整座山都震动起来。 19号角声越来越嘹亮。摩西说话,上帝就回应他,声音好像雷鸣。 20耶和华降临在西奈山顶,召摩西到山顶,摩西就上去了。 21耶和华对摩西说:“你下去嘱咐百姓不可闯过界线到我这里观看,以免很多人死亡。 22吩咐到我面前来的祭司要洁净自己,免得我忽然出来击杀他们。”

23摩西对耶和华说:“百姓不能上西奈山,因为你已经吩咐我们要在山的四围划定界限,使这山成为圣山。” 24耶和华对他说:“你下去把亚伦一起带来,祭司和百姓仍要留在原来的地方,不得乱闯到我面前,免得我忽然出来击杀他们。” 25摩西就下去,把耶和华的话转告给百姓。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 19:1-25

Ní orí òkè Sinai

1Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai. 2Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá.

3Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: 4‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. 519.5,6: De 7.6; 14.2,21; 26.19; Tt 2.14; 1Pt 2.9; If 1.6; 5.10.Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú ààmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. 6Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”

7Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. 8Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.

9Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.

10Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. 11Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. 1219.12-19: Hb 12.18-20.Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á: 13A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”

14Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 15Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”

1619.16: If 4.5.19.16-18: De 4.11,12.Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì. 17Mose sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè. 18Èéfín sì bo òkè Sinai nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. 19Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.

20Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o sì pe Mose wá sí orí òkè náà. Mose sì gun orí òkè. 21Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé. 22Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọlù wọ́n.”

23Mose wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”

24Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”

25Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn.